Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  April 2015

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Báwo ni ọjọ́ ọlá àwa èèyàn ṣe máa rí?

BÁwo ni ikú Jésù ṣe máa mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn?

Ó dájú pé àwọn èèyàn á ṣì máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Àmọ́, ṣé àwọn fúnra wọn lè ṣe ohun tó máa mú kí gbogbo èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú? Rárá o. Lóde òní, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra ló kún inú ayé. Àmọ́, ohun tó dára gan-an ni Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn.—Ka 2 Pétérù 3:13.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, lọ́jọ́ iwájú gbogbo èèyàn kárí ayé máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. A ó máa gbé nínú ààbò, ẹnì kankan ò sì ní kó ìpayà bá wa.—Ka Míkà 4:3, 4.

Báwo ni ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe máa dópin?

Ọlọ́run ò dá ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́ àwa èèyàn. Àmọ́, nítorí pé ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí mú kó di aláìpé. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ la sì ti jogún ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Jésù sọ aráyé di pípé pa dà.—Ka Róòmù 7:21, 24, 25.

Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, Jésù kú ikú ìrúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwa èèyàn bọ́ lọ́wọ́ ohun tí àìgbọràn ọkùnrin àkọ́kọ́ fà. (Róòmù 5:19) Torí náà, Jésù mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti ní ọjọ́ ọlá àgbàyanu, nígbà tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan kò ní mú káwọn èèyàn máa hùwà burúkú mọ́.—Ka Sáàmù 37:9-11.