Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  March 2015

 Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Se O Ye Ki Awon Kristeni Maa Se Ayeye Odun Ajinde?

Se O Ye Ki Awon Kristeni Maa Se Ayeye Odun Ajinde?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopædia Britannica sọ pé Ọdún Àjíǹde jẹ́ “àjọ̀dún pàtàkì tí àwọn Kristẹni fi ń ṣe ayẹyẹ Àjíǹde Jésù Kristi.” Àmọ́, ṣé ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe ayẹyẹ yìí?

Ká tó lè mọ̀ bóyá ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan jẹ́ ògidì, ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ibi tó ti ṣẹ̀ wá. Bákan náà, ká tó lè mọ̀ bóyá ó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe Ọdún Àjíǹde, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Ọdún Àjíǹde.

Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ìrántí ikú òun, kò ní kí wọ́n máa ṣe ayẹyẹ àjíǹde òun. Pọ́ọ̀lù pe ìrántí ikú Jésù yìí ní “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 11:20; Lúùkù 22:19, 20.

Láfikún sí i, ìwé Britannica sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ń ṣe nígbà Ọdún Àjíǹde “kò ní nǹkan kan ṣe” pẹ̀lú àjíǹde Jésù, “àmọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn wá látinú àwọn àṣà àti ìtàn ayé àtijọ́.” Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopedia of Religion sọ nípa ẹyin àti ehoro tó jẹ́ àmì Ọdún Àjíǹde pé: “Ẹyin náà ṣàpẹẹrẹ bí ẹ̀mí tuntun ṣe ń jáde wá bí i pé látinú ikú, ìyẹn ohun kan tó le bí èèpo ẹyin.” Ó fi kún un pé: “Ehoro jẹ́ ẹ̀dá kan tó máa ń bímọ gan-an, torí náà ó ṣàpẹẹrẹ pé ìgbà ìrúwé ti ń bọ̀.”

Philippe Walter, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àwọn ìwé ìṣẹ̀ǹbáyé, ṣàlàyé bí àwọn àṣà yẹn ṣe wá di ara ayẹyẹ Ọdún Àjíǹde. Ó ní “nígbà tí àwọn kèfèrí bẹ̀rẹ̀ sí í di Kristẹni,” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì so àjọyọ̀ “ìparí ìgbà òtútù bọ́ sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé” táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe mọ́ àjíǹde Jésù. Walter fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé èyí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti so “àjọyọ̀ àwọn Kristẹni” pọ̀ mọ́ àjọ̀dún àwọn abọ̀rìṣà, kí wọ́n lè fa ọ̀pọ̀ èèyàn wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.

Àwọn àpọ́sítélì kò fàyè gba irú àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà ayé wọn, torí pé wọ́n jẹ́ “aṣèdíwọ́” fún àṣà àwọn abọ̀rìṣà. (2 Tẹsalóníkà 2:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé “lẹ́yìn lílọ” òun, àwọn èèyàn kan ‘yóò dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.’ (Ìṣe 20:29, 30) Nígbà tó sì fi máa di ọwọ́ ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé àwọn ọkùnrin kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣi àwọn Kristẹni lọ́nà. (1 Jòhánù 2:18, 26) Èyí wá mú kó rọrùn láti mú àṣà àwọn abọ̀rìṣà wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.

“Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14

Àwọn kan lè máa rò pé, kò burú láti lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà Ọdún Àjíǹde. Ó ṣe tán, ó mú kó ṣeé ṣe fún “àwọn kèfèrí” láti túbọ̀ lóye ohun tí àjíǹde Jésù túmọ̀ sí. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ fàyè gba irú àṣà bẹ́ẹ̀ láé. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àṣà àwọn abọ̀rìṣà ni Pọ́ọ̀lù rí bó ṣe ń rìnrìn àjò la Ilẹ̀ Ọba Róòmù kọjá. Síbẹ̀ kò tìtorí kí àwọn abọ̀rìṣà yẹn lè di Kristẹni, kó wá tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’”—2 Kọ́ríńtì 6:14, 17.

Kí ni àyẹ̀wò ráńpẹ́ tá a ṣe yìí jẹ́ ká mọ̀? Ó ti jẹ́ ká rí i pé Ọdún Àjíǹde kì í ṣe àjọyọ̀ tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe.

Mọ Púpọ̀ Sí I

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Àjíǹde?

Kà nípa ibi tí àṣà Ọdún Àjíǹde márùn-ún ti wá.

ILÉ ÌṢỌ́

Àjíǹde Jésù Máa Jẹ́ Ká Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun!

Ìwọ rò ó wò ná, kéèyàn wà láàyè títí láé láìsí ìrora, ìyà àti ọ̀fọ̀ kankan.