Ronú nípa bó ṣe máa rí ká ní o kò lè darí àwọn ẹ̀yà ará rẹ, àyàfi ẹyinjú rẹ nìkan. Ìṣòro tí Jairo ẹ̀gbọ́n mi ń bá yí nìyẹn. Síbẹ̀, ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀. Kí n tó sọ ohun tó mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ ìtàn rẹ̀ fún yín.

Nígbà tí wọ́n bí Jairo, ó ní àrùn cerebral palsy tí wọ́n ń pè ní spastic quadriplegia, ìyẹn irú àrùn inú ọpọlọ kan. * Àrùn yìí kì í jẹ́ kó lè gbé apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ bó ṣe fẹ́, kì í sì í jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ọpọlọ rẹ̀ kò lè gbé ìsọfúnni tó ṣe tààrà lọ sínú iṣan rẹ̀, torí náà ńṣe ni ọwọ́ àti ẹsẹ rẹ̀ máa ń jù fìrì-fìrì tí kò sì ní lè ṣe nǹkan kan sí. Láwọn ìgbà míì ọwọ́ rẹ̀ tó ń jù fìrì-fìrì máa ń jẹ́ kó ṣe ara rẹ̀ léṣe. Ó sì lè ṣe àwọn tó bá wà nítòsí rẹ̀ náà léṣe tí wọ́n ò bá wà lójúfò. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń de apá àti ẹsẹ rẹ̀ mọ́ àga àwọn arọ kó má bàa ṣe ara rẹ̀ léṣe.

INÚ ÌNIRA LÓ WÀ TÍTÍ TO FI DÀGBÀ

Inú ìnira ni Jairo wà bó ṣe ń dàgbà. Nígbà tó wà lọ́mọ oṣù mẹ́ta, gìrì máa ń mú kó dákú lọ gbári. Lọ́pọ̀ ìgbà, Màmá mi á gbá a mọ́ra wọ́n á sì gbé e dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn, wọ́n á rò pé ó ti kú.

Bí wọ́n ṣe ń gbá a mọ́ra yìí mú kí eegun Jairo di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], ó ṣèṣe, ìbàdí rẹ̀ sì yẹ̀, torí náà wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Mo ṣì rántí bí Jairo ṣe máa ń kérora lálaalẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà.

Torí àìlera yìí, Jairo kò lè dá ohunkóhun ṣe àyàfi tí ẹlòmíì bá ràn án lọ́wọ́ fún àwọn nǹkan bíi jíjẹun, mímúra àti lílọ sórí bẹ́ẹ̀dì. Mọ́mì àti Dádì ló sì máa ń ràn án lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni Jairo máa ń nílò ìrànlọ́wọ́, àwọn òbí wa máa ń sọ fún un pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.

Ọ̀NÀ ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ ṢÍ SÍLẸ̀

Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí wa, àtìgbà tí Jairo sì ti wà ní ìkókó ni wọ́n ti máa ń ka àwọn ìtàn Bíbélì fún un. Wọ́n mọ̀ pé ìgbésí ayé èèyàn máa túbọ̀ nítumọ̀ téèyàn bá sún mọ́ Ọlọ́run. Lóòótọ́, apá àti ẹsẹ̀ Jairo máa ń ṣàdédé jù fìrì léraléra, àmọ́ ó lè ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Síbẹ̀ àwọn òbí wa máa ń rò ó pé báwo ni Jairo ṣe máa lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Jairo ṣì wà lọ́mọdé, Dádì mi sọ fún un pé, “Jairo, ṣé o lè bá mi sọ̀rọ̀?” Ó wá fi kún un pé, “Tó o bá nífẹ̀ẹ́ mi, wà á bá mi sọ̀rọ̀!” Bí dádì mi ṣe ń bẹ̀ ẹ́ pé kó tiẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan, ńṣe ni omi lé ròrò lójú rẹ̀. Ó gbìyànjú láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, àmọ́ kò lè sọ̀rọ̀ jáde. Ó dun bàbá mi pé àwọn mú kí Jairo sunkún. Àmọ́ èyí fi hàn pé Jairo  lóye ohun tí bàbá mi sọ. Ohun tó kàn jẹ́ ìṣòro ni pé kò lè sọ̀rọ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn òbí wa kíyè sí i pé Jairo máa ń yí ojú rẹ̀ léraléra láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Ó máa ń tojú sú Jairo pé àwọn èèyàn kì í lóye òun. Àmọ́ nígbà tí àwọn òbí wa bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìrísí ojú rẹ̀ láti mọ ohun tó fẹ́ tí wọ́n á sì ṣe nǹkan náà fún un, ayọ̀ á hàn lójú rẹ̀. Ayọ̀ tó hàn lójú rẹ̀ ni ọ̀nà tó fi ń dúpẹ́ ohun tí wọ́n ṣe fún un.

Dókítà kan tó ń tọ́jú àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa sọ fún wa pé, kí ọ̀rọ̀ wa lè máa yé ara wa, ká máa na ọwọ́ méjèèjì sókè tá a bá fẹ́ béèrè ohun tí ìdáhùn rẹ̀ jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọwọ́ ọ̀tún dúró fún bẹ́ẹ̀ ni, ọwọ́ òsì dúró fún bẹ́ẹ̀ kọ́. Torí náà, ibi tó bá tẹjú mọ́ ló máa jẹ́ ká mọ ohun tó fẹ́.

JAIRO GBÉ ÌGBÉSẸ̀ PÀTÀKÌ KAN

Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe àpéjọ níbi tí wọ́n ti máa ń sọ àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì fún àwùjọ ńlá. Inú Jairo máa ń dùn yàtọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ àsọyé tí wọ́n darí sí àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Lọ́jọ́ kan nígbà tí Jairo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], Dádì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Jairo, ṣé ó wù ẹ́ láti ṣe ìrìbọmi?” Lẹ́ẹ̀kan náà, bó ṣe wo ọwọ́ ọ̀tún Dádì fi hàn pé ó wù ú láti ṣe ìrìbọmi. Dádì wá béèrè pé, “Ṣé o ti ṣèlérí fún Ọlọ́run nínú àdúrà pé wàá sìn ín títí láé?” Jairo tún wo ọwọ́ ọ̀tún Dádì. Ó wá ṣe kedere pé Jairo ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ ní ìgbà mélòó kan, ó ṣe kedere pé Jairo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ìrìbọmi. Torí náà, lọ́dún 2004, ó dáhùn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n tíì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìyẹn ni pé, “Ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?” Jairo gbé ojú rẹ̀ sókè láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Èyí jẹ́ ọ̀nà tó ti múra sílẹ̀ láti fi sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Torí náà, nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ó ṣe ìrìbọmi, ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ó TẸJÚ MỌ́ ÀWỌN OHUN TI ỌLỌ́RUN

Lọ́dún 2011, ọ̀nà tuntun tá a lè gbà bá Jairo sọ̀rọ̀ wá ṣí sílẹ̀, ìyẹn ni kọ̀ǹpútà tó ń bá ojú ṣiṣẹ́. Ẹ̀rọ yìí máa ń ṣàkíyèsí ẹyinjú rẹ̀ tó fi jẹ́ pé ohun tó bá ṣẹ́jú sí lójú kọ̀ǹpútà máa dàbí ìgbà téèyàn fọwọ́ tẹ nǹkan ọ̀hún lójú kọ̀ǹpútà. Oríṣiríṣi àwòrán ló wà lójú kọ̀ǹpútà náà tó lè ṣẹ́jú sí, èyíkéyìí tó bá sì ṣẹ́jú sí máa gbé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti ṣètò sí inú rẹ̀ jáde.

 Bí òye Jairo nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń jinlẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń wù ú láti ran àwọn míì lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Ọlọ́run. Nígbà tí ìdílé wa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, Jairo sábà máa ń wò mí, á sì tún wo kọ̀ǹpútà rẹ̀. Èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà rán mi létí pé kí n bá òun kọ ìdáhùn tí ó máa sọ nígbà ìbéèrè àti ìdáhùn nínú ìpàdé Kristẹni.

Ní ìpàdé, ó máa ń fara balẹ̀ wo kọ̀ǹpútà rẹ̀ kó lè mú ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà kan tó máa gbé ìdáhùn rẹ̀ jáde. Ó máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbàkigbà tó bá láǹfààní láti fún àwọn ará ìjọ ní ìṣírí lọ́nà yìí. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alex tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jairo sọ pé, “Orí mi máa ń wú tí mo bá gbọ́ bí Jairo ṣe ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì.”

Jairo máa ń lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tó ń bá ojú ṣiṣẹ́ tó sì ń gbóhùn jáde láti dáhùn ní ìpàdé àti láti wàásù fáwọn míì

Jairo tún máa ń lo ojú rẹ̀ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́. Ọ̀nà tó ń gbà ṣe èyí ni pé ó máa tẹ àwòrán kan tó ṣàfihàn ọgbà táwọn ẹranko wà, tí àwọn èèyàn tó wá látinú onírúurú ẹ̀yà sì ń gbé pa pọ̀ níṣọ̀kan. Tó bá ti ṣí àwòrán yìí, ohùn orí kọ̀ǹpútà náà á sọ pé, “Ìrètí tí Bíbélì mú dá wa lójú ni pé ayé máa di Párádísè níbi tí kò ti ní sí àìsàn àti ikú mọ́, Ìṣípayá 21:4.” Tí ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ bá tẹ́tí sí i, á tún tẹ nǹkan míì lórí kọ̀ǹpútà náà tó máa sọ pé, “Ṣé wàá fẹ́ kí n kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Sí ìyàlẹ́nu, bàbá ìyá mi tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí. Nǹkan ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí bí Jairo àti Ẹlẹ́rìí míì ṣe ń kọ́ Bàbá àgbà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú gbogbo wa sì dùn nígbà tí Bàbá àgbà ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe nílùú Madrid lóṣù August ọdún 2014.

Àwọn olùkọ́ Jairo náà kíyè sí ẹ̀mí ìfọkànsìn tí Jairo ní. Rosario tó jẹ́ dókítà tó ń tọ́jú àwọn tó níṣòro ọ̀rọ̀ sísọ tiẹ̀ sọ nígbà kan pé: “Ká ní mo fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan, ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni màá dara pọ̀ mọ́. Mo ti rí bí ìgbàgbọ́ Jairo ṣe jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀, láìka ipò tó le koko tó wà sí.”

Ńṣe ni ojú Jairo máa ń tàn yanran tí mo bá ka ìlérí Bíbélì yìí fún un pé: “Ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:6) Lóòótọ́, ó máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà inú rẹ̀ máa ń dùn. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé ó sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì láwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ Kristẹni. Ayọ̀ tó máa ń hàn lójú rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ní jẹ́ ẹ̀rí pé téèyàn bá ń sin Jèhófà, ó máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ bó tilẹ̀ ní ìṣòro.

^ ìpínrọ̀ 5 Cerebral palsy ni orúkọ gbogbo gbòò tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àrùn inú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kéèyàn lè gbé apá àti ẹsẹ bó ṣe fẹ́. Ó tún lè fa gìrì, àìlè jẹun dáadáa àti àìlè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já geere. Spastic quadriplegia ló le jù lára àwọn àrùn cerebral palsy; ó lè mú kí gbogbo oríkèé ara kú tipiri, kì ọrùn sì máa gbọ̀n yèpéyèpé.