Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  March 2015

Nje O Mo?

Nje O Mo?

Àǹfààní wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nínú jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù?

Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!”

Ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù máa ń ní àwọn ẹ̀tọ́ àtàwọn àǹfààní kan ní ibikíbi tó bá wà ní ilẹ̀ ọba Róòmù. Abẹ́ òfin Róòmù ni ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù wà kì í ṣe abẹ́ òfin àgbègbè ibi tó bá ń gbé. Tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn án, ó lè gbà kí wọ́n ṣe ẹjọ́ òun lábẹ́ òfin àgbègbè tọ́rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ ó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ Róòmù. Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ ẹjọ́ ikú ló tọ́ sí i, ó ṣì lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ́dọ̀ olú ọba Róòmù.

Ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ yìí ni Cicero tó jẹ́ aṣáájú ilẹ̀ Róòmù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní lọ́kàn tó fi sọ pé: “Ẹni bá fi okùn de ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ti rú òfin ìjọba, ìwà ìkà sì ni tí wọ́n bá fi ẹgba nà án, tí wọ́n bá wá pa á, ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹnì kan pa òbí rẹ̀ tàbí ìbátan tímọ́tímọ́ kan.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ó lo àǹfààní ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ó kéré tán lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: (1) Ó sọ fún aṣojú ìjọba ìlú Fílípì pé wọ́n ti tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú bí wọ́n ṣe na òun lẹ́gba. (2) Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù kí wọ́n má bàa nà án lẹ́gba ní Jerúsálẹ́mù. (3) Ó ké gbàjarè sí Késárì, kó lè jẹ́ pé olú ọba Róòmù ló máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.—Ìṣe 16:37-39; 22:25-28; 25:10-12.

Báwo ni wọ́n ṣe ń sanwó iṣẹ́ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Wàláà tí wọ́n kọ àdéhùn láti ra àgùntàn àti ewúrẹ́ sí, ní nǹkan bí ọdún 2050 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Ogún [20] ọdún ni baba ńlá náà Jékọ́bù fi bójú tó àgùntàn Lábánì tó jẹ́ arákùnrin ìyá rẹ̀. Ọdún mẹ́rìnlá ló fi kọ́kọ́ bá Lábánì ṣiṣẹ́ torí kó lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì, àmọ́ wọ́n fún un ní àwọn ohun ọ̀sìn gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà fún ọdún mẹ́fà tó kù. (Jẹ́nẹ́sísì 30:25-33) Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé “irú àdéhùn tó wà láàárín Lábánì àti Jékọ́bù, ìyẹn fífi ohun ọ̀sìn sanwó fáwọn olùṣọ́ àgùntàn kò ṣàjèjì sí àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn tó ń kà á nígbà yẹn.”

Àwọn wàláà àdéhùn ayé ọjọ́un tí wọ́n hú jáde látinú ilẹ̀ ní ìlú Nuzi, Larsa àtàwọn ibòmíì ní orílẹ̀-èdè Iraq tòde òní jẹ́ àpẹẹrẹ irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń gba owó iṣẹ́ wọn. Ẹni tó ni ẹran ọ̀sìn náà máa fa iye ẹran pàtó kan lé olùṣọ́ àgùntàn náà lọ́wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn àti bóyá ó jẹ́ akọ tàbí abo. Lẹ́yìn ọdún kan, ó ní iye òwú, wàrà, ọmọ ẹran àtàwọn nǹkan míì tí ẹni tó ni àwọn ẹran ọ̀sìn náà máa gbà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn. Ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù ló máa jẹ́ ti olùṣọ́ àgùntàn.

Bí àgùntàn tí wọ́n kó fún olùṣọ́ àgùntàn bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu bí agbo ẹran náà ṣe máa pọ̀ tó láàárín ọdún kan. Wọ́n retí pé kí àgùntàn ọgọ́rùn-ún [100] bí ọmọ tó pọ̀ tó ọgọ́rin [80]. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àdánù èyíkéyìí ṣẹlẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn yẹn ló máa san-án pa dà. Fún ìdí yìí, ó máa ní láti bójú tó àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó sọ́dọ̀ rẹ̀ dáadáa.