Ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí ikú ìrúbọ tí òun máa tó kú. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.

Ní ọdún yìí, Ìrántí Ikú Jésù bọ́ sí ọjọ́ Friday, April 3, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe ìwọ àti ìdílé rẹ láti wá gbọ́ àsọyé kan tó máa ṣàlàyé ìdí tí ikú Jésù fi ṣe pàtàkì àti bó o ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀.