Iléeṣẹ́ akẹ́rù kan ni Alex ti ń ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan tó ti ṣiṣẹ́ tó ti rẹ̀ ẹ́, ìrònú bá a, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú iṣẹ́ rádaràda wo tiẹ̀ ni mò ń ṣe yìí ná? Ìgbà wo lèmi náà máa rí towó ṣe? Kí n má tiẹ̀ ṣiṣẹ́ rárá gan-an sàn ju èyí lọ!’

Bíi ti Alex, ọ̀pọ̀ lónìí ni kò gbádùn kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ àṣekára. Mẹkáníìkì kan tó ń jẹ́ Aaron sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ò fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ mọ́, wọ́n á ní ‘kọ́wọ́ máà dilẹ̀ ni mò ń fi eléyìí ṣe títí dìgbà tí màá fi rí iṣẹ́ gidi.’”

Kí nìdí táwọn èèyàn ò fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ àṣekára mọ́? Ó lè jẹ́ nítorí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí pé ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ìrọ̀rùn tó sì rọra ń jayé lẹni tó ti “rí ṣe.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Matthew, tó máa ń ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé sọ pé: “Àwọn èèyàn gbà pé kò dìgbà téèyàn bá forí ṣe fọrùn ṣe kó tó lówó láyé táa wà yìí, òṣìṣẹ́ ńbẹ lóòrùn, náwó náwó ńbẹ ní ibòji.” Ẹlòmíì tó ń jẹ́ Shane, tó ń ṣiṣẹ́ aṣọ́gbà sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Iṣẹ́ kékeré owó ńlá ni àwọn èèyàn tún ń lé kiri lónìí.”

Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ tó rọ́wọ́ mú lónìí ló gbádùn àtimáa ṣe iṣẹ́ àṣekára. Daniel tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó sì ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé sọ pé: “Èrè wà nínú iṣẹ́ àṣekára téèyàn bá ń ṣe nǹkan tó ní láárí.” Andre ẹni ọdún mẹ́tàlélógún [23] náà gbà pẹ̀lú òun tí Daniel sọ, ó ní: “Ohun tí mo mọ̀ ni pé ayọ̀ àti ìgbádùn wà nínú iṣẹ́ àṣekára, bó bá jẹ́ pé iṣẹ́ kékeré lèèyàn ń ṣe, kò ní pẹ́ tá a fi sú u, ó sì lè má láyọ̀.”

Kí ló mú kí Daniel àti Andre ní èrò tó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn nípa iṣẹ́ àṣekára? Ìlànà Bíbélì ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ó dáa kéèyàn ṣiṣẹ́ kára kó sì lẹ́mìí ìfaradà. Àmọ́ ó tún jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ wa.

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbádùn iṣẹ́ rẹ? Jẹ́ ká gbé mélòó kan yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.