Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníwàásù 3:13) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ wa, ó sì ti pèsè ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ nínú Bíbélì. (Aísáyà 48:17) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìlànà Bíbélì tó sọ bá a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ wa.

MÁA FI OJÚ TÓ TỌ́ WO IṢẸ́ RẸ

Ì báà jẹ́ iṣẹ́ ọpọlọ lò ń ṣe tàbí iṣẹ́ agbára tàbí iṣẹ́ míì, mọ̀ dájú pé àǹfààní wà nínú gbogbo rẹ̀. (Òwe 14:23) Irú àǹfààní wo? Ohun kan ni pé, iṣẹ́ àṣekára máa ń jẹ́ ká lè bójú tó ara wa. Lóòótọ́, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa pèsè fún wa, pàápàá àwọn tó ń fòótọ́ inú sin òun. (Mátíù 6:31, 32) Síbẹ̀, ó fẹ́ kí àwa náà ṣiṣẹ́ ká lè bójú tó àwọn ohun tá a nílò.—2 Tẹsalóníkà 3:10.

Rántí pé, iṣẹ́ lóògùn ìṣẹ́, ọmọlúàbí èèyàn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kó lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Joshua tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sọ pé: “Bó o bá ti ń gbọ́ bùkátà ara rẹ, ìwọ náà ti ń gbé nǹkan ńlá ṣe nìyẹn. Bó o bá sì ń rówó ra ohun tó o nílò, á jẹ́ pé ò ń jẹ èrè iṣẹ́ rẹ̀ nìyẹn.”

Bákan náà, bá a bá ń ṣiṣẹ́ kára, a máa níyì lójú àwọn èèyàn. Má gbàgbé pé kò sí iṣẹ́ tó rọrùn. Àmọ́, tá a bá tẹpá mọ́ṣẹ́, tí a ò sì ṣe ìmẹ́lẹ́ láìka bí iṣẹ́ ọ̀hún ṣe lágbára tó, ọkàn wa á balẹ̀ pé à ń ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa múnú wa dùn, pé a kì í ṣe ọ̀lẹ. (Òwe 26:14) Torí náà, ẹni tó bá ń ṣiṣẹ́ máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Aaron tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínu àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Ara máa ń tù mí lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ó lè rẹ̀ mí o, kí ẹnì kankan má sì yìn mí fún iṣẹ́ tí mo ṣe, síbẹ̀, inú mi máa ń dùn pé mo ti mú nǹkan gidi kan ṣe lọ́jọ́ yẹn.”

 TẸPÁ MỌ́ṢẸ́

Bíbélì gbóríyìn fún ọkùnrin “tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀” àti obìnrin tó ń “ṣe ohun yòówù tí ọwọ́ ara rẹ̀ ní inú dídùn sí.” (Òwe 22:29; 31:13) Òótọ́ kan ni pé èèyàn kì í di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sàn kan òru kan. Àti pé, iṣẹ́ tí a kò bá mọ̀ ọ́ ṣe dáadáa, a kì í gbádùn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ lónìí ni kò gbádùn iṣẹ́ wọn torí pé wọn ò sapá láti di ọ̀jáfáfá lẹ́nu rẹ̀.

Àmọ́ ṣá, kò sí iṣẹ́ téèyàn ò lè mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, kó sì gbádùn rẹ̀. Ohun tó gbà ni pé kéèyàn fọkàn sí iṣẹ́ náà dáadáa. Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún [24] kan tó ń jẹ́ William sọ pé: “Tó o bá fara ṣiṣẹ́ dáadáa, tó o sì rí èrè iṣẹ́ náà, inú rẹ á dùn. O ò lè ní irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ tó bá ń pẹ́ iṣẹ́ sílẹ̀ tàbí tó ń fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́.”

RONÚ LÓRÍ BÍ IṢẸ́ RẸ ṢE Ń ṢE ÀWỌN ÈÈYÀN LÁǸFÀÀNÍ

Bó bá kan ọ̀rọ̀ iṣẹ́, ohun tó wà lọ́kàn àwọn kan ò ju bí wọ́n ṣe máa rówó rẹpẹtẹ lọ, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó yẹ kéèyàn ronú lé, bíi: ‘Kí nìdí tí iṣẹ́ yìí fi ṣe pàtàkì? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí mi ò bá ṣe é tàbí tí mi ò bá ṣe é dáadáa? Báwo ni iṣẹ́ mi ṣe ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní?’

Bá a bá rí àǹfààní tí iṣẹ́ wa ń ṣe fún àwọn èèyàn, ó máa mú kí iṣẹ́ túbọ̀ yá wa lára, kí inú wa sì dùn. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Kì í ṣe àwọn oníbàárà wa àti àwọn tó gbà wá sí iṣẹ́ nìkan ni iṣẹ́ wa ń ṣe láǹfààní, ó tún ń ṣe ìdílé wa àtàwọn aláìní láǹfààní.

Ìdílé wa. Ọ̀nà méjì ni baálé ilé kan tó bá ń ṣiṣẹ́ kára ń gbà ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní. Àkọ́kọ́ ni pé, á lè pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run gbé fún un, ìyẹn láti “pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (1 Tímótì 5:8) Ọ̀nà kejì ni pé, baálé ilé tó bá ń ṣiṣẹ́ kára ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Shane tá a mẹ́nu bà ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Iṣẹ́ káfíńtà ni bàbá mi ń ṣe, ó sì máa ń fòótọ́ inú ṣiṣẹ́. Kò kẹ̀rẹ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ pé ká jára mọ́ṣẹ́, òun ló jẹ́ kí n mọ̀ pé ó dáa kéèyàn máa ṣiṣẹ́ ọwọ́, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan tó máa wúlò fún àwọn èèyàn.”

Àwọn aláìní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé “kí [a] máa ṣe iṣẹ́ àṣekára . . . kí [a] lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Tí a bá ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè fún ìdílé wa, ó ṣeé ṣe ká ní àjẹṣẹ́kù tá a lè fi ran àwọn tí kò rí jájẹ lọ́wọ́. (Òwe 3:27) Torí náà, bá a bá ṣiṣẹ́ kára, àwa náà máa rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni.

 FI KÚN ÌSAPÁ RẸ LẸ́NU IṢẸ́

Jésù sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè pé: ‘Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.’ (Mátíù 5:41) Báwo ni ìlànà yẹn ṣe kan iṣẹ́ tá à ń ṣe? Kàkà tí wàá fi máa ṣe ìwọ̀nba lẹ́nu iṣẹ́, o ò ṣe wá bí wàá ṣe ṣiṣẹ́ rẹ dójú àmì. Ní àfojúsùn kan, bóyá kó o pinnu láti túbọ̀ yára lẹ́nu iṣẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ tàbí kó o sapá láti mú kí iṣẹ́ rẹ dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Rí i pé gbogbo iṣẹ́ rẹ lo ṣe láì yọ nǹkan sílẹ̀ títí kan àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá.

Bó o ba fi kún ìsapá rẹ lẹ́nu iṣẹ́, wàá túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ náà dáadáa. Ṣùgbọ́n á jẹ́ látọkàn rẹ wá lo pinnu láti ṣe kún un kì í ṣe pé ẹnì kan ló ń tì ẹ́ láti fi kún iṣẹ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti lo àkókò rẹ bó o ṣe fẹ́. (Fílémónì 14) Èyí mú wa rántí ìlànà tó wà nínú ìwé Òwe 12:24 tó sọ pé: “Ọwọ́ àwọn ẹni aláápọn ni yóò ṣàkóso, ṣùgbọ́n ọwọ́ dẹngbẹrẹ yóò wá wà fún òpò àfipámúniṣe.” Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó lè gbà kẹ́nì kan mú òun sìnrú. Àmọ́, ẹni tí wọ́n bá ń tì kó tó ṣiṣẹ́ dà bí ẹni tí wọ́n ń mú sìnrú. Bí ẹnì kan bá ń fínnúfíndọ̀ ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un, kódà tó tún ṣe kọjá ohun tí wọ́n retí láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni fipá mú un ṣe é, ó ṣe dáadáa torí pé lójú ẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé òun fúnra rẹ̀ ló ń darí iṣẹ́ ara rẹ̀ torí òun ló pinnu láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe náà.

FIṢẸ́ SÍ ÀYÈ RẸ̀

Ó dára kéèyàn ṣiṣẹ́ kára lóòótọ́, síbẹ̀ àwọn nǹkan míì wà nígbèésí ayé ẹ̀dá tó tún ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ lọ. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ wa. (Òwe 13:4) Àmọ́ kò so pé ká sọ ara wa di ẹrú iṣẹ́. Ìwé Oníwàásù 4:6 tiẹ̀ sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” Kókó ibẹ̀ ni pé béèyàn bá sọ ara rẹ̀ di ẹrú iṣẹ́, òun gan-an lè má ráyè gbádùn gbogbo ohun tó fojoojúmọ́ ṣe. Ńṣe lọ̀rọ̀ rẹ̀ máa dà bí ẹni tó ń “lépa ẹ̀fúùfù.”

Àwọn ìmọ̀ràn Bábélì yìí lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. O dára ká fara ṣíṣẹ́ lóòótọ́, ṣùgbọ́n má gbàgbé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Àwọn nǹkan wo la lè kà sí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù? Ara rẹ̀ ni pé ká máa wáyè fún ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa. Ṣùgbọ́n èyí tó ṣe pàtàkì jù ni àwọn nǹkan tó bá níṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run bíi kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa ronú lé e lórí.

Béèyàn bá fi iṣẹ́ sí àyè rẹ̀, tó sì ń wáyè fún àwọn nǹkan míì, ó dájú pé á túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni William tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àpẹẹrẹ ọ̀kan nínú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń wú mi lórí, bó bá di ká ṣiṣẹ́, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó ń wáyè fún àwọn nǹkan míì, àwọn oníbàárà wa sì fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé ó máa ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ dáadáa. Bẹ́ẹ̀ kì í ta kú ti iṣẹ́, bí iṣẹ́ bá ti parí, ó ń lọ sílé nìyẹn láti bá ìdílé rẹ̀ ṣeré kí wọ́n sì jọ lọ jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́ ohun tó wú mi lórí jù ni pé ó máa ń láyọ̀ ṣáá ní gbogbo ìgbà!”