Nígbà tí ọ̀gá àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọba ilẹ̀ Nicaragua ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi ṣòro láti mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò, ó ní: “Nígbà tí gbogbo aráàlú bá jẹ́ oníwà ìbàjẹ́, ọ̀nà dà tí ìjọba ò ní kún fún àwọn oníwà ìbàjẹ́.”

Òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni ọ̀gbẹ́ni yìí sọ nítorí pé tí ìwà ìbàjẹ́ bá gbilẹ̀ láàárín àwọn aráàlú, kò sọ́gbọ́n tí ìjọba ìlú fi máa dára. Bọ́rọ̀ bá rí báyìí, a jẹ́ pé ìjọba tí kò ní hùwà ìbàjẹ́ kò lè tọwọ́ èèyàn wá. Bíbélì sọ nípa irú ìjọba bẹ́ẹ̀, ó pè é ní Ìjọba Ọlọ́run, ìjọba yẹn ni Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún.—Mátíù 6:9, 10.

Àtọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso. Òun ló sì máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn. (Sáàmù 2:8, 9; Ìṣípayá 16:14; 19:19-21) Ara àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn nínú Ìjọba yẹn ni pé kò ní sí ìwà ìbàjẹ́ mọ́. Jẹ́ ká wo ohun mẹ́fà tó mú kó dá wa lójú pé Ìjọba náà máa mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò.

1. AGBÁRA ÌJỌBA

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Owó orí àtàwọn owó míì tí àwọn aráàlú ń san ni ìjọba èèyàn fi ń ṣiṣẹ́. Bí owó yìí ṣe ń rọ́ wọlé máa ń wọ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì lójú débi pé wọ́n ń jí nínú owó náà. Àwọn kan sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè bá àwọn èèyàn dín owó orí wọn kù. Èyí sábà máa ń dá kún ìṣòro yìí nítorí pé, gbàrà tí ìjọba bá ti rí i pé owó orí to ń wọlé ti ń dín kù, wọ́n á tún fi kún owó orí táwọn èèyàn ń san. Bí owó tó pọ̀ bá sì tún wọlé sápò ìjọba, àwọn òṣìṣẹ́ yìí á tún jí i kó, àwọn míì á sì máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ dín owó orí wọn kù. Níkẹyìn, àwọn aráàlú tí kò lè ṣe màdàrú ló máa ń forí fá gbogbo ìyà náà.

 OJÚTÙÚ: Àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni Ìjọba Ọlọ́run ti gba agbára rẹ̀. * (Ìṣípayá 11:15) Kò nílò owó orí látọ̀dọ̀ ẹnì kankan láti lè ṣiṣẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára Ọlọ́run tí kò láàlà àti ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Ìjọba náà á pèsè gbogbo ohun tí àwọn èèyàn bá nílò.—Aísáyà 40:26; Sáàmù 145:16.

2. ALÁKÒÓSO

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Ọ̀jọ̀gbọ́n Susan Rose-Ackerman tá a dárúkọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé bá a bá fẹ́ mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò, ọ̀dọ̀ àwọn tó wà lókè la gbọ́dọ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba ò lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bí wọ́n bá ń sapá láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì, àmọ́ tí wọ́n ń ṣe bíi pé àwọn ò rí ìwà ìbàjẹ́ tó kún ọwọ́ àwọn lọ́gàálọ́gàá. Bó bá tiẹ̀ wù alákòóso kan láti ṣe ohun tó dára, agbára rẹ̀ kò lè gbé e nítorí pé kò sí adára-má-kù-síbì-kan. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ fi bá a mu pé, “kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere” ní gbogbo ìgbà.—Oníwàásù 7:20.

Ìfà tí Sátánì fi lọ Jésù dà bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ńlá kan, àmọ́ Jésù kò gbà

OJÚTÙÚ: Jésù Kristi tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí Alákòóso nínú Ìjọba rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí àwa èèyàn. Jésù dára délẹ̀délẹ̀, a kò sì lè mú un ṣe ohun tí kò tọ́. Nígbà kan, Sátánì fi ìfà ńlá kan bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ Jésù. Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé ṣèlérí fún Jésù pé òun á fún un ní “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” bó bá jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan péré, àmọ́ Jésù kò gbà. (Mátíù 4:8-10; Jòhánù 14:30) Nígbà tí Jésù ń joró ikú, àwọn kan gbé ohun mímu kan tó lè pa oró náà wá fún un, àmọ́ Jésù kọ̀ ọ́ torí pé tó bá mu ún, ìrònú rẹ̀ ò ní já geere mọ́, ó sì lè kọsẹ̀. Ẹ ò rí i pé láìka ìrora ńlá yìí sí, Jésù ò yẹsẹ̀. (Mátíù 27:34) Ní báyìí, Jésù ti wà lọ́run lọ́dọ̀ Baba rẹ̀, ó sì ti fi hàn pé òun tóótun láti ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.—Fílípì 2:8-11.

3. ÀÌFÌDÍMÚLẸ̀ ÌJỌBA

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn aráàlú máa ń dìbò torí kí wọ́n lè yọ àwọn jẹgúdújẹrá kúrò nípò. Síbẹ̀, ìwà ìbàjẹ́ tó máa ń wáyé níbi ìbò kì í jẹ́ kí wọ́n kẹ́sẹ járí, ibi gbogbo ló sì ti ń ṣẹlẹ̀. Àwọn bàbá ìsàlẹ̀ máa ń gbówó ńlá sílẹ̀ kí àwọn tí wọ́n ń dìbò fún lè rọ́wọ́ mú nínú ìbò, nígbà tí àwọn tó rọ́wọ́ mú bá gorí àlééfà, àwọn bàbá ìsàlẹ̀ yìí ni á máa darí wọn.

John Paul Stevens tó jẹ́ adájọ́ àgbà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kì í jẹ́ kí ìjọba lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ torí kì í ṣe ẹni táwọn aráàlú ń fẹ́ ni yóò máa darí ìjọba bí kò ṣe àwọn tó gbówó kalẹ̀.” Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé inú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ni àwọn jẹgúdújẹrá pọ̀ sí jù.

OJÚTÙÚ: Ìjọba Ọlọ́run kì í pààrọ̀ ààrẹ torí náà kò ní sí wàhálà ìbò rárá. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ìdí sì ni  pé Ọlọ́run ló yan ẹni tó máa ṣàkóso, kò nílò ìbò ẹnikẹ́ni láti fi mọ ẹni tó yẹ kó yàn, wọn ò sì lè yọ ẹni náà kúrò lórí àlééfà láé! Gbogbo nǹkan yìí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run fìdí múlẹ̀ dáadáa, kó sì jẹ́ ìjọba táráyé ń fẹ́.

4. ÒFIN

Àtọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Àwọn kan rò pé bí àwọn bá ṣe àwọn òfin tuntun, ìwà ìbàjẹ́ á dópin. Àmọ́, ìwádìí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fi hàn pé àwọn òfin tuntun tí wọ́n bá ṣe ló tún ń fún àwọn jẹgúdújẹrá yẹn láyè láti máa hùwà ìbàjẹ́ wọn nìṣó. Owó tí ìjọba ń ná láti ṣe àwọn òfin tuntun yìí pọ̀, síbẹ̀, àṣeyọrí tí òfin náà ń ṣe kò tó nǹkan rárá.

OJÚTÙÚ: Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ò lẹ́gbẹ́, kò tiẹ̀ fi ibi kankan jọ ti ìjọba èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Kàkà kí Jésù máa gbé òfin má-ṣu-má-tọ̀ kalẹ̀, ńṣe ni Jésù fún wa ní Ìlànà Pàtàkì kan to sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Lákòótán, àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run sábà máa ń dá lórí ohun pàtàkì méjì, àkọ́kọ́ ni èrò ọkàn wa, èkejì ni ìwà wa. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tí Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ń rínú wa, tó sì lágbára lórí èrò wa, síbẹ̀ kì í fipá mú wa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 16:7.

5. ÈRÒ ỌKÀN

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Bá a bá wádìí ẹ̀ lọ wádìí ẹ̀ bọ̀, ojú kòkòrò àti ìmọtara ẹni nìkan ló wà nídìí ìwà ìbàjẹ́. Irú ìwà yẹn ló sì kún ọwọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ṣé ẹ rántí ilé ìtajà tó wà nílùú Seoul tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, kí àwọn kọngílá tó gba iṣẹ́ ìkọ́lé náà lè rí èrè rẹpẹtẹ, wọ́n kọ́kọ́ fowó díẹ̀ dí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan lẹ́nu, wọ́n sì ṣiṣẹ́ àjàǹbàkù tó pa dà wá lẹ́yìn.

Torí náà, bí ìjọba bá fẹ́ mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò, ńṣe ló yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ àwọn èèyàn nípa bí wọ́n á ṣe ṣẹ́pá ẹ̀mí ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan tó ti jingíri sọ́kàn wọn. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé  ìjọba èèyàn ò lẹ́mìí àtiṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kò tiẹ̀ sí bí wọ́n ṣe lè ṣeé.

OJÚTÙÚ: Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ìbàjẹ́ nípa kíkọ́ àwọn èèyàn láti borí àwọn èrò tí kò dáa. * Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú [wọn] ṣiṣẹ́.” (Éfésù 4:23) Kàkà kí wọ́n máa ṣojú kòkòrò tàbí kí wọ́n ní ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan, wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn míì dénú.—Fílípì 2:4; 1 Tímótì 6:6.

6. ÀWỌN ARÁÀLÚ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Bí àyíká bá tiẹ̀ dára, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì kẹ́kọ̀ọ́ láti máa hùwà ọmọlúàbí, àwọn olóríkunkun kan á ṣì máa hùwà ìbàjẹ́. Ìyẹn sì wà lára ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rí tí wọ́n fi sọ pé ó máa ṣòro fún ìjọba èèyàn láti mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò, ohun tí wọ́n lè ṣè ò ju pé kí wọ́n dín in kù.

OJÚTÙÚ: Ìwé àdéhùn tí Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ sọ pé, bí ìjọba bá fẹ́ rẹ́yìn ìwà ìbàjẹ́, kí wọ́n sapá láti mú kí àwọn èèyàn jẹ́ “olóòótọ́ àti ọmọlúwàbí, kí kálukú sì bójú tó àwọn ojúṣe rẹ̀.” Ìmọ̀ràn yẹn dáa lóòótọ́, àmọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí bó ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àwọn ìwà gidi yìí, ó tún retí kí àwọn èèyàn tó fẹ́ wà nínú ìjọba rẹ̀ máa hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé “àwọn oníwọra” àti “àwọn òpùrọ́” kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Ìṣípayá 21:8.

Àwọn èèyàn lè kọ́ bí wọ́n á sẹ máa hùwà ọmọlúwàbí gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ìgbàanì ti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì fẹ́ fowó ra ẹ̀mí mímọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ wọn kò gbà fún un, wọ́n sọ fún un pé: “Ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ yìí.” Lẹ́sẹ̀ kan náà ni Símónì ní kí àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà fún òun kí òun lè borí ìfẹ́ ọkàn búburú náà.—Ìṣe 8:18-24.

BÍ O ṢE LÈ WÀ LÁRA ÀWỌN TÓ MÁA JOGÚN ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

Ibi yòówù kó o máa gbé láyé, àǹfààní wà fún ẹ láti wà lára àwọn tó máa jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 10:34, 35) Kárí ayé ni àwọn ẹ̀kọ́ tó jíire wà fún gbogbo àwọn tó bá ń fẹ́ àǹfààní yìí, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà fò ẹ́ ru. Bó o bá fẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, ẹ̀kọ́ náà lè má ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ara ohun tí wàá kọ́ ni “ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run” àti bí ìjọba náà á ṣe mú ìwà ìbàjẹ́ kúrò. (Lúùkù 4:43) A rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá mọ̀ ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹnjw.org/yo.

Ṣé wàá fẹ́ kí ẹnì kan máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé, lọ́fẹ̀ẹ́?

^ ìpínrọ̀ 8 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 22 Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Oníwà Ìbàjẹ́ Yìí?” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2012.