Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Nje O Mo?

Nje O Mo?

Àwọn wo ni “ìwẹ̀fà” tí Bíbélì mẹ́nu kàn?

Àwòrán ìwẹ̀fà ará Asíríà kan lára ògiri

Nígbà míì, wọ́n máa ń fi orúkọ yìí pe àwọn ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá fẹ́ fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ tàbí tí wọ́n mú lẹ́rú ni wọ́n sábà máa ń tẹ̀ lọ́dàá. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti tẹ̀ lọ́dàá tí wọ́n sì fọkàn tán ló máa ń bójú tó ilé àwọn obìnrin nínú ààfin ọba. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwẹ̀fà náà Hégáì àti Ṣááṣígásì ló ń ṣọ́ àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọge Ọba Ahasuwérúsì tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Sásítà Kìíní ti ilẹ̀ Páṣíà.—Ẹ́sítérì 2:3, 14.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tí Bíbélì pè ní ìwẹ̀fà ni wọ́n tẹ̀ lọ́dàá. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba. Irú àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwẹ̀fà tí wọn kò tẹ̀ lọ́dàá ni Ebedi-mélékì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jeremáyà àti ọkùnrin ará Etiópíà tí ajíhìnrere náà Fílípì wàásù fún. Ó dájú pé onípò àṣẹ nínú ààfin ni Ebedi-mélékì torí pé ó láǹfààní láti máa bá Ọba Sedekáyà sọ̀rọ̀. (Jeremáyà 38:7, 8) Bákan náà, Bíbélì sọ pé ọkùnrin ará Etiópíà náà jẹ́ akápò ọba tó “lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.”—Ìṣe 8:27.

Kí nìdí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn fi máa ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ lára àwọn ewúrẹ́ láyé àtijọ́?

Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tó ń bọ̀, ó ní: ‘Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, yóò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.’ (Mátíù 25:31, 32) Kí nìdí táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi máa ń ya àwọn ẹran wọ̀nyí sọ́tọ̀ọ̀tọ̀?

Wọ́n sábà máa ń da àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ pọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jẹko láàárọ̀. Bó bá sì di alẹ́, wọ́n á kó wọn sínú gàá kí wọ́n lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ òtútù tàbí àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn olè. (Jẹ́nẹ́sísì 30:32, 33; 31:38-40) Àmọ́, torí pé àwọn àgùntàn kò lágbaja, pàápàá àwọn abo àti ọ̀dọ́ àgùntàn, yàrá ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń kó wọn sí kí àwọn ewúrẹ́ tó máa ń ṣe gàràgàrà má bàa ṣe wọ́n léṣe. Ìwé náà, All Things in the Bible sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún máa ń ya àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ́tọ̀ nígbà “tí wọ́n bá ń bímọ, tí wọ́n bá ń fún wàrà wọn tàbí tí wọ́n bá ń rẹ́ irun wọn.” Jésù lo àpèjúwe tó máa tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ torí pé àwọn darandaran pọ̀ ní gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì nígbà yẹn lọ́hùn-ún.