Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  January 2015

Ohun Ti Bibeli So

Ohun Ti Bibeli So

Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?

Àgbàyanu ni ọ̀nà tí ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá wa?

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, akéwì kan sọ pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 139:14) Ó máa ń yani lẹ́nu téèyàn bá ń ronú nípa bí ọlẹ̀ ṣe máa ń di odindi ọmọ. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ gbà pé lóòótọ́ ni Ẹlẹ́dàá kan wà.—Ka Sáàmù 139:13-17; Hébérù 3:4.

Ẹni tó dá àgbáálá ayé yìí tó fi ṣeé gbé náà ló dá gbogbo ẹ̀dá inú rẹ̀. (Sáàmù 36:9) Ẹlẹ́dàá wa ṣàlàyé bí òun ṣe jẹ́ fún wa.—Ka Aísáyà 45:18.

Ṣé ara ẹranko la ti wá?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀yà ara wa jọra pẹ̀lú tàwọn ẹranko. Ìdí sì ni pé Ẹlẹ́dàá tó dá àwa èèyàn náà ló dá àwọn ẹranko láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ekuru ni Ọlọ́run fi dá èèyàn àkọ́kọ́, kì í ṣe ara ẹranko ló ti wá.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:24; 2:7.

Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la gbà yàtọ̀ sí àwọn ẹranko. Lákọ̀ọ́kọ́, àwa èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa, ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì máa bọlá fún un. Èkejì, Ọlọ́run kò dá àwọn ẹranko láti wà láàyè títí láé, ṣùgbọ́n ó dá àwa èèyàn láti wà títí lọ kánrin. Àmọ́ ní báyìí, àwa èèyàn ń kú torí pé ẹni àkọ́kọ́ tí Ẹlẹ́dàá dá ṣàìgbọràn sí àwọn àṣẹ Rẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:15-17.