• ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1960

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: LẸ́BÁNÓNÌ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO MÁA Ń JA KỌNFÚ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Wọ́n bí mi ní ìlú Rmaysh tó wà nítòsí bodè ìlú Ísírẹ́lì, àsìkò yẹn ni ogun abẹ́lé gbóná gan-an lórílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì. Mo ṣì rántí bí àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ ṣe ń bú gbàù tó sì sọ ọ̀pọ̀ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ di aláàbọ̀ ara. Nǹkan ò fara rọ rárá torí pé ìwà ìkà àti ìwà ipá gbòde kan lákòókò yẹn.

Ìdílé Onígbàgbọ́ ni wọ́n bí mi sí, gbogbo àwa méjìlá tá a sì wà nínú ìdílé náà ló ń dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti ìlà oòrùn, èyí tí wọ́n máa ń pè ní Ṣọ́ọ̀ṣì Maronite. Ọwọ́ bàbá mi máa ń dí gan-an nítorí iṣẹ́ tó ń ṣe láti fi gbọ́ bùkátà wa. Àmọ́, ìyá mi máa ń rí i dájú pé gbogbo wa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo rí i pé ìsìn àti ìjọba kò ṣe tán láti ran àwọn mẹ̀kúnnù lọ́wọ́.

Bí mo ṣe ń dàgbà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìjà kọnfú. Mo gba àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó le gan-an, kò sì pẹ́ tí mo fi di ọ̀jáfáfá nínú rẹ̀. Mo lè gbá èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́, kí n sì fi ìpá ṣéèyàn léṣe. Mo tún kọ́ béèyàn ṣe ń lo onírúurú ohun ìjà. Èrò mi ni pé, ‘tí mi ò bá tiẹ̀ lè dá ogun dúró, ó yẹ kí n lè ṣẹ́pá àwọn ọ̀daràn tó ń hùwà ipá.’ Bí mo bá rí àwọn méjì tó ń jà, kíá ni màá ti dá sí i. Onínúfùfù ni mí, nǹkan kékeré sì máa ń tètè bí mi nínú. Ìdí nìyẹn tí òkìkí mi fi kàn dé apá gúúsù Lẹ́bánónì, àwọn èèyàn sì bẹ̀rù mi gan-an bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé nítorí kí n báa lè gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá ni mo ṣe ń jà kiri.

Nígbà tó di ọdún 1980, mo wọ ẹgbẹ́ àwọn oníjà kọnfú ní ìlú Beirut kí n lè kọ́ ìjà náà sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni bọ́ǹbù máa ń bú gbàù nílùú yẹn, ọjọ́ kan ò lọ kí n má lọ ja kọnfú. Gbogbo ohun tí mo mọ̀ kò jú kí n jẹun, kí n sùn, kí n sì máa ṣe bí Bruce Lee, ìyẹn òṣèré ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà kan tó gbóná gan-an nínú ìjà kọnfú. Èmi náà máa ń gẹ irun bíi ti Bruce Lee, mo sì máa ń rìn bíi tiẹ̀, mo tún káṣà bó ṣe máa ń pariwo tó bá ń jà. Gbogbo ìgbà ni ojú mi máa ń le koko bí ojú ẹkùn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ohun tí mò ń lé ni kí n di ògbóǹtagí oníjà kọnfú ní ilẹ̀ Ṣáínà, káwọn èèyàn lè máa kan sárá sí mi. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí mò ń ṣe ìdánrawò kíkankíkan tí mo fi ń gbara dì láti lọ sí ilẹ̀ Ṣáínà, mo gbọ́ tí ẹnì kan kan  ilẹ̀kùn mi. Ọ̀rẹ́ mi àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ló wá mi wá. Nígbà tí mo jáde sí wọn, mò ń làágùn yọ̀bọ̀ pẹ̀lú aṣọ kọnfú tí mo wọ̀, mo sì sọ fún wọn pé, “Mi ò mọ nǹkankan nípa Bíbélì o.” Àṣé ọjọ́ yẹn gan-an ni ìgbésí ayé mi máa bẹ̀rẹ̀ sí i yí pa dà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn lo Bíbélì láti ṣàlàyé ìdí tí àwa ẹ̀dá èèyàn kò fi lágbára láti fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá. Wọ́n jẹ́ kí n rí i pé Sátánì Èṣù gan-an lẹ́ni tó ń fa gbogbo wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀. (Ìṣípayá 12:12) Ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà gbà sọ̀rọ̀ wú mi lórí gan-an torí ohun tí wọ́n ń sọ dá wọn lójú, ọkàn wọn sì balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀. Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́ mi pé Ọlọ́run ní orúkọ. (Sáàmù 83:18) Wọ́n tún fi ohun tó wà nínú 1 Tímótì 4:8 hàn mí, tó kà pé: “Eniyan a máa rí anfani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfani ti ẹ̀sìn kò lópin; nitori ó ní anfani ní ayé yĭ, ó tún fún eniyan ní anfani ti ayé tí ḿ bọ̀.”—ÌRÒHÌN AYỌ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì mú kí n ṣe àwọn àtúnṣe kan.

Àmọ́, ó dùn mí pé mo dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn dúró nítorí pé àwọn ìdílé mi ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà má wá sí ilé wa mọ́. Síbẹ̀, mo pinnu pé mi ò ní ja kọnfú mọ́ àti pé màá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ Bíbélì. Èyí kò dùn mọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi nínú, àmọ́ mo dúró lórí ìpinnu mi pé màá wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn kí wọ́n lè kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo wá wọn títí, àmọ́ mi ò rí wọn. Láwọn àkókò kan, nǹkan ò rọgbọ rárá fún ìdílé mi, pàápàá nígbà tí bàbá mi ṣàdédé kú. Èyí kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi. Nígbà yẹn, iléeṣẹ́ kan tó máa ń kọ́lé ni mò ń bá ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adel béèrè ìdí tí ojú mi fi kọ́rẹ́ lọ́wọ́, nígbà tí mo sọ ohun tó ń ṣe mí, ó ṣàlàyé ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde. Adel jẹ́ onínúure, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó mú sùúrù fún mi, ó sì fi oṣù mẹ́sàn-án gbáko kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí mo ṣe ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi, mo rí i pé ó yẹ kí n yí ìwà mi pa dà. Ká sòótọ́ kò rọrùn, torí ara tètè máa ń kan mí, mo sì máa ń tètè bínú lórí ohun tí ò tó nǹkan. Àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè ṣàkóso ìbínú mi àti bí mo ṣe lè máa ní sùúrù tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ mí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nínú ìwé Mátíù 5:44 pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” Bákan náà, ìwé Róòmù 12:19 kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, . . . nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘“Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san,” ni Jèhófà wí.’” Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti ṣàtúnṣe, ọkàn tèmi náà sì balẹ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀, àwọn ẹbí mi ò fẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní báyìí àwọn gan-an tiwá gba táwọn Ẹlẹ́rìí. Kódà, ọ̀kan nínú wọn ti kẹ́kọ̀ọ́, òun náà sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú mi dùn pé màmá mi náà máa ń sọ nípa ìgbàgbọ́ àwa Ẹlẹ́rìí fáwọn ẹlòmíì títí tí wọ́n fi kú.

Jèhófà ti fi aya rere jíǹkí mi, aya tó dúró tì mí gbágbáágbá, Anita lorúkọ rẹ̀. Èmi àti ẹ̀ la jọ ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù fáwọn èèyàn. Láti ọdún 2000 ni èmi àti Anita ti kó lọ si ìlú Eskilstuna, lórílẹ̀-èdè Sweden ká lè kọ́ àwọn tó ń sọ èdè Lárúbáwá lágbègbè yẹn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Ọkàn mi ṣì máa ń gbọgbẹ́ tí mo bá rí àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ tàbí tí wọ́n ń hùwà ìkà sí. Àmọ́ mo ti mọ ìdí táwọn nǹkan wọ̀nyẹn fi ń ṣẹlẹ̀, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run máa fòpin sí i láìpẹ́. Èyí máa ń fún mi láyọ̀ gan-an.—Sáàmù 37:29.

Inú èmi àti ìyàwó mi máa ń dún tá a bá ń wàásù. A sì nífẹ̀ẹ́ láti máa sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn