“Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí.”—SÁÀMÙ 139:1.

“Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi.”—SÁÀMÙ 139:16

ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run ò rí nǹkan míì lára wa ju ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ, a ò sì yẹ lẹ́ni tó ń bójú tó. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Kendra sọ pé bí òun ṣe ń sapá tó láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run, òun máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Èyí mú kí òun ka ara òun sí ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku, ìbànújẹ́ sì máa ń dorí òun kodò. Nítorí ẹ̀dùn ọkàn yìí, Kendra sọ pé: “Òun kì í gbàdúrà mọ́.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ wa ni Jèhófà ń wò, ńṣe ló máa ń wo irú ẹni tí a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún. Bíbélì sọ pé: ‘Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wa.’ Síwájú sí i, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣe sí wa “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,” àmọ́ nínú àánú rẹ̀, ó máa ń dárí jì wá nígbà tá a bá ronú pìwà dà.—Sáàmù 103:10, 14.

Nígbà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àkòrí àkọ́kọ́ ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ . . . Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi.” (Sáàmù 139:16, 23) Dáfídì mọ̀ pé òun máa ń ṣẹ̀, àmọ́ tí òun bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá, Jèhófà máa ń rí inú òun lọ́hùn-ún, ó sì máa ń mọ̀ pé òun kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Jèhófà mọ̀ ẹ́ ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ ẹ́ lọ. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ṣe àṣìṣe, Ọlọ́run mọ ohun tó fà á. Ó mọ̀ pé àyíká tí à ń gbé, àwọn tó tọ́ wa dàgbà àti ìwà tá a jogún láti ara àwọn òbí wa máa ń nípa lórí wa. Síbẹ̀, ó mọyì bá a ṣe ń sapá láti ṣèfẹ́ rẹ̀, kódà tá a bá tiẹ̀ ń ṣàṣìṣe léraléra.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń lo òye tó ní nípa rẹ láti tù ẹ́ nínú?