“Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—JÒHÁNÙ 6:44.

ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gba Ọlọ́run gbọ́, síbẹ̀ ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò sún mọ́ ọn rárá. Irú èrò yìí ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Christina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ireland ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, ó sọ pé: “Mo kàn mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo àmọ́ èmi fúnra mi kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n. Kò tiẹ̀ ṣe mí rí bíi pé mo sún mọ́ Ọlọ́run.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o jìnnà sí Ọlọ́run, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ò ní fi ẹ sílẹ̀. Jésù ṣe àkàwé kan tó jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa, ó ní: “Bí ọkùnrin kan bá wá ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì ṣáko lọ, kì yóò ha fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún náà sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá ọ̀kan tí ó ṣáko lọ?” Kí ni Jésù fẹ́ fàyọ? Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.”—Mátíù 18:12-14.

Gbogbo ọ̀kọ̀ọ̀kan “àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí” ló ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe ń ‘wá ọ̀kan tí ó bá ṣáko lọ’? Ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀rẹ̀ àkòrí yìí sọ pé, Jèhófà ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀.

Lónìí, àwọn wo ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn nílé wọn àti níbikíbi tí wọ́n bá ti rí wọn kí wọ́n lè sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn?

Wo díẹ̀ lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fa àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run ní kí ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Fílípì lọ pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, kí ó sì ṣàlàyé ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ìwẹ̀fà náà ń kà fún un. (Ìṣe 8:26-39) Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run rán àpọ́sítélì Pétérù lọ sí ilé ọ̀gágun ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù tó ti ń gbàdúrà, tó sì ń sapá láti jọ́sìn Ọlọ́run. (Ìṣe 10:1-48) Ọlọ́run tún darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ sí odò kan nítòsí ìlú Fílípì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà “ẹni tí ó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run,” Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí” àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.—Ìṣe 16:9-15.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé, Jèhófà máa ń fún gbogbo àwọn tó bá ń wá a ní àǹfààní láti mọ òun. Lónìí, àwọn wo ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn nílé wọn àti níbikíbi tí wọ́n bá ti rí wọn kí wọ́n lè sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn? Ọ̀pọ̀ ló gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ló ń lò wọ́n láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sún mọ́ ọn?’ Jọ̀wọ́ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè gba ìrànlọ́wọ́ tó ń pèsè yìí, kó bàa lè fà ẹ́ mọ́ra. *

^ ìpínrọ̀ 8 Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí ìkànnì wa ìyẹn, www.jw.org/yo.