Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Bí O Ṣe Lè Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Wí

Bí O Ṣe Lè Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Wí

“Ilẹ̀ ti ṣú, ìdààmú sì bá mi pé Jordan ọmọkùnrin mi kò tíì wọlé, mi ò mọ̀ bóyá wàhálà kan lo ṣẹlẹ̀ àbí òun gan-an ò tiẹ̀ mọ̀ pé a ti ń dààmú nípa ẹ̀ látàárọ̀. Tí mo bá gbọ́ ìró mọ́tò tó kọjá, ńṣe ni màá tara kìjí. Ẹ̀kẹta nìyí tó máa pẹ́ níta ju àkókò tí a fún un pé kí ó máa wọlé. Nígbà tó dé, orí mi ti gbóná, kódà mo fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣi ọ̀rọ̀ sọ sí i.”—GEORGE.

“Ṣàdédé ni mo gbọ́ tí ọmọdébìnrin mi ké tò-ò, àyà mí já débi pé orí mi fò lọ. Kò pẹ́ ni mo rí i tó gbá orí mú tó sì ń sunkún. Àṣé àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tí kò ju ọmọ ọdún mẹ́rin lọ ló gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́.”—NICOLE.

“A rí òrùka lọ́wọ́ Natalie, ọmọdébìnrin wa tí kò ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ. La bá bi í pé ibo ló ti rí i, ó ní: ‘Mi o jí òrùka o, mo rí i he ni! A mọ̀ pé irọ́ ló pa fún wa, ó kàn ń ṣe bíi pé kò mọ nǹkan kan. Ọ̀rọ̀ náà dùn wá débi pé omi bọ́ lójú wa.”—STEPHEN.

Ẹ̀YIN ÒBÍ, ǹjẹ́ irú àwọn ohun tá a sọ lókè yìí ti ṣẹlẹ̀ sí yín rí? Tí ẹ bá wà nírú ipò tí àwọn òbí tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí wà, ǹjẹ́ ẹ ò ní máa ṣe kàyéfì pé ṣe ó yẹ kí ẹ bá àwọn ọmọ náà wí? Ṣé ó burú kéèyàn bá ọmọ rẹ̀ wí?

KÍ NI ÌBÁWÍ?

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí,” kò túmọ̀ sí fífi ìyà jẹni. Ohun tí ìbáwí túmọ̀ sí ni fífúnni ní ìtọ́ni, kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti títọ́ni sọ́nà. Kò ní í nǹkan kan ṣe pẹ̀lú kéèyàn lu ọmọ ní ìlùkulù tàbí kéèyàn rorò mọ́ ọn.—Òwe 4:1, 2.

A lè fi bíbá ọmọ wí wé ẹni tó ń dáko. Àgbẹ̀ tó fẹ́ dáko á kọ́kọ́ roko, lẹ́yìn náà, á bomi rin àwọn irúgbìn kó lè hù, á sì tún máa dáàbò bo irúgbìn náà lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àti èpò tó lè pa á lára. Bí irúgbìn náà ṣe ń hù, á máa pẹ̀ka rẹ̀ kó lè máa dàgbà lọ́nà tó yẹ. Ó mọ̀ pé tí òun bá lo oríṣiríṣi ọ̀nà yìí nìkan ni irúgbìn náà fi lè dàgbà dáadáa. Bákan náà, oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn òbí ń gbà tọ́ àwọn ọmọ wọn. Nígbà míì, wọ́n lè fún àwọn ọmọ wọn ní ìbáwí, èyí tá a lè fi wé bí àgbẹ̀ kan ṣe ń pẹ̀ka irúgbìn rẹ̀ kó lè hù dáadáa. Irú ìbáwí yìí ló máa jẹ́ kí wọn lè tètè ṣàtúnṣe sí àwọn èrò tí kò tọ́, á sì jẹ́ kí wọ́n lè dàgbà lọ́nà tó dáa. Síbẹ̀, bí ó ṣe yẹ kí àgbẹ̀ kan fara balẹ̀ pẹ̀ka irúgbìn kan kí igi náà má bàa kú pátápátá, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kí àwọn òbí fi ìfẹ́ bá ọmọ wọn wí.

Tó bá di ká báni wí, Jèhófà Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn òbí. Ó máa ń fìfẹ́ bá àwọn olùjọsìn rẹ̀ onígbọràn tó wà lórí ilẹ̀ ayé wí lọ́nà tó tuni lára débi pé wọ́n wá ‘nífẹ̀ẹ́ ìbáwí.’ (Òwe 12:1) Wọ́n “di ìbáwí mú,” wọn ò sì “jẹ́ kí ó lọ.” (Òwe 4:13) O lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọyì ìbáwí tó o bá ń fara wé ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta tí Ọlọ́run ń gbà fún wa ní ìbáwí, o máa ń ṣeé: (1) tìfẹ́tìfẹ́, (2) lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu tàbí níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti (3) lọ́nà tó ṣe déédéé.

 Ẹ MÁA FÌFẸ́ BÁ ÀWỌN ỌMỌ YÍN WÍ

Ìfẹ́ ló máa ń sún Ọlọ́run láti bá wa wí. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” (Òwe 3:12) Síwájú sí i, Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú.” (Ẹ́kísódù 34:6) Torí náà, Jèhófà kì í ṣe òǹrorò, kì í búni, kì í bẹnu àtẹ́ lù wá tàbí kó máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa. Ìdí sì ni pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣeni léṣe, àfi bíi “pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.”—Òwe 12:18.

FETÍ SÍLẸ̀

Lóòótọ́, kò lè ṣeé ṣe fún àwọn òbí láti fara wé Jèhófà pátápátá tó bá dọ̀ràn ká lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Torí pé ìgbà míì wà tí wọ́n lè hùwà tí ń tánni ní sùúrù, àmọ́, ẹ máa rántí pé téèyàn bá fìbínú bá ọmọ wí, ó lè sọ ni di òǹrorò àti aláṣejù, ìbáwí náà sì lè máà mú èso kankan jáde. Síwájú sí i, fífi ìbínú jẹ ọmọ níyà kì í ṣe ìbáwí rárá, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu ni.

Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tí ẹ bá fìfẹ́ bá àwọn ọmọ yín wí, tí ẹ sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu, ìyẹn ló máa méso jáde. Gbé àpẹẹrẹ bí George àti Nicole, àwọn òbí méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe yanjú ọ̀ràn náà.

GBÀDÚRÀ

“Nígbà tí Jordan pa dà dé, inú ti bí èmi àti ìyà rẹ̀ gan-an, àmọ́ a mú sùúrù, a sì fetí sílẹ̀ sí àlàyé rẹ̀. Nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú, a pinnu láti yanjú ọ̀rọ̀ naa láàárọ̀ ọjọ́ kejì. A jọ gbàdúrà pa pọ̀ ká tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ náà. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, ara wa ti balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, a sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó wọ ọmọ wa lọ́kàn. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló fi gba ìbáwí náà, tó sì gbà pé lóòótọ́, òun ṣe ohun tí kò dáa. Ọjọ́ yẹn la mọ̀ pé àkókó tí inú bá ń bíni lọ́wọ́ kọ́ ló yẹ kéèyàn máa bá ọmọ wí, torí pé irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kì í sèso tó dáa. Bí a ṣe kọ́kọ́ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tó ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀ràn náà tètè yanjú.”—George.

Ẹ JỌ SỌ̀RỌ̀ PAPỌ̀

“Inú bí mi gan-an nígbà tí mo rí ìwà ìkà tí ọmọkùnrin mi hù sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Dípò tí máà fi bá a wí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ńṣe ni mo ní kó gba yàrá rẹ̀ lọ ní kíá, torí pé inú ti bí mi gan-an nígbà yẹn, tí n bá sì ní kí n bá a wí lákòókò yẹn, mo lè ṣì í lù. Nígbà tí ara mi wálẹ̀, mo ṣàlàyé fún pé ìwà ipá kó dára, mo sì ṣàlàyé bí ìwà rẹ̀ ṣe dun ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó. Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ ọ́ lára gan an, èmi náà rí i pé ọgbọ́n tí mo lò gbéṣẹ́ torí pé ó bẹ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé òun kò ní ṣe irú rẹ̀ mọ́, ó sì gbá a mọ́ra.”Nicole.

Tó bá tiẹ̀ yẹ ká fìyà jẹ ọmọ kan nítorí ohun tó ṣe, ìfẹ́ léèyàn á fi bá a wí.

ÌBÁWÍ TÓ WÀ NÍWỌ̀NTÚNWỌ̀NSÌ

Jèhófà sábà máa ń báni wí “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 30:11; 46:28) Ó sì máa ń gbé àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, títí kan àwọn  nǹkan tí ẹni náà fúnra rẹ̀ lè máà fọkàn sí. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà lọ́nà yìí? Ọ̀gbẹ́ni Stephen tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tó ṣe, ó ní: “Lóòótọ́, ohun tí Natalie ṣe dùn wá dọ́kàn nítorí bó ṣe kọ̀ jálẹ̀ tó sì pa irọ́ pé òun kò jí òrùka yẹn, àmọ́, nígbà tá a ronú lórí ọjọ́ orí ẹ̀, a rí i pé ọmọdé ló ń ṣe é.”

Robert tó jẹ́ ọkọ Nicole náà gbé gbogbo ohun tó wé mọ́ ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ bá ṣìwà hù, ó sábà máa ń bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ó ti máa ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ àbí ó ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ ni? Ṣé ara ọmọ náà kò yá ni, àbí ó kàn ń fi ìwà tó hù yìí bo ohun tó ń ṣeé gan-an mọ́lẹ̀?’

Òbí tó ń fòye báni lò á máa rántí pé kò sígbà tí ọmọdé kò ní ṣe ìṣe ọmọdé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Robert sọ pé: “Nǹkan tó jẹ́ kí n máa fi ojú tó tọ́ wo ọ̀ràn náà tí kò sì jẹ́ kí n gbé ọ̀rọ̀ náà gbòdì ni pé mo máa ń rán ara mi létí àwọn ohun témi náà dán wò nígbà tí mo wà ní ọmọdé.”

O ṣe pàtàkì pé kí o mọ ibi tí ọgbọ́n ọmọ rẹ dé àti ohun tó o lè ṣe, síbẹ̀ o kò gbọ́dọ̀ gbàgbàkugbà láàyè. Tó o bá ń ronú lórí nǹkan tí ọmọ rẹ lè ṣe, ibi tágbára rẹ̀ mọ àti ohun tó yí ipò náà ká, wà á lè mọ ọ̀nà tó dáa jù láti bá a wí, ìyẹn kò sì ní jẹ́ kí ó lù ú nílùkulù, àmọ́ wà á lè fi òye bá àwọn ọmọ rẹ lò.

ÌBÁWÍ TÓ ṢE DÉÉDÉÉ

Ìwé Málákì 3:6 sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” Ọkàn àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run balẹ̀ nítorí òtítọ́ tá a mọ̀ yìí. Àwọn ọmọdé náà nílò ìbáwí tó ṣe déédéé kí ọkàn wọn lè balẹ̀. Tí ìbáwí rẹ bá ń ṣe ségesège nítorí bí nǹkan ṣe rí lára rẹ lásìkò náà, ọmọ rẹ kò ní lóye ìdí tó o fi ń bá òun wí, èyí á bà á lọ́kàn jẹ́, á sì múnú bí i.

Rántí ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Ọ̀rọ̀ yìí bá àwọn òbí wí gan an. (Mátíù 5:37) Kó o tó fòté lé ohun tó o fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ ṣe, ronú jinlẹ̀ kó o ba lè mọ̀ bóyá wà á lè ṣe ohun tó o sọ. Tó o bá ti sọ fún ọmọ rẹ pé tó bá ṣẹ̀, ohun báyìí lo máa ṣe fún un, rí i dájú pé ohun tó o sọ pé wà á ṣe gẹ́lẹ́ lo ṣe.

Kí ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ní ìbáwí tó yẹ, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀yin òbí máa sọ̀rọ̀ pọ̀ déédéé. Robert sọ pé: “Tí àwọn ọmọ wa bá gbìyànjú láti jẹ́ kí n gbà pẹ̀lú wọn lórí àwọn ọ̀ràn kan tí ìyàwó mi kò fara mọ́, tí èmi ò sì mọ̀ tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mo máa ń yí ìpinnu mi pa dà, tí máa sí jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí ìyá wọn ṣe sọ gẹ́lẹ́ náà ni mo fara mọ́.” Ẹyin òbí, tí ẹ kò bá tíì fohun ṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀ràn kan, ó máa dára tí ẹ bá jọ jíròrò ọ̀ràn náà láàárín ẹ̀yin méjèèjì, kẹ́ ẹ sì dórí ìpinnu kan náà.

ÌBÁWÍ ṢE PÀTÀKÌ

Tí ẹ̀yin òbí bá fara wé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fìfẹ́ báni wí, tí ẹ sì ń ṣeé lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu àti lọ́nà tó ṣe déédéé, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe lórí àwọn ọmọ yín kò ní já sí asán. Ìbáwí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yàn kí wọ́n sì yanjú, wọ́n á sì tún mọnúúrò nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Bí Bíbélì ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló ṣe máa rí, ó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.