Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ìbọn Máa Ń Wà Lára Mi Níbikíbi Tí Mo Bá Lọ

Ìbọn Máa Ń Wà Lára Mi Níbikíbi Tí Mo Bá Lọ
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1958

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ITALY

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌỌ̀TA

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìgbèríko kan ní ìlú Róòmù ni wọ́n bí mi sí, ní àdúgbò kan tí àwọn tálákà pọ̀ sí. Nǹkan ò rọrùn fún mi torí mi ò gbọ́njú mọ ìyá mi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ èmi àti bàbá mí kò wọ̀ rárá. Bí mo ṣe ya ọmọ ìgboro láti kékeré nìyẹn.

Nígbà tí màá fi pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í jalè. Mi ò sì ju ọmọ ọdún méjìlá lọ nígbà tí mo kọ́kọ́ sá kúrò nílé. Àìmọye ìgbà ni bàbá mi ti wá gbà mí lẹ̀ ní àgọ́ àwọn ọlọ́pàá kí ó lè mú mi pa dà wálé. Èmi náà mọ̀ pé alára gbígbóná ni mí, ńṣe ni mo máa ń bínú lódìlódì, tí màá sì máa kanra mọ́ gbogbo èèyàn. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo fi ilé sílẹ̀ pátápátá. Mo wá di ọmọ asùnta, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró. Ibi tí ilẹ̀ bá ti ṣú bá mi náà ni mò ń sùn sí, nígbà míì, ó lè jẹ́ inú ọkọ̀ ọlọ́kọ̀ ni màá sùn mọ́jú. Tí ilẹ̀ bá m, màá fi omi bọ́jú, ìgboro tún yá.

Iṣẹ́ olè ni mo yàn láàyò, mò ń já báàgì gbà, mo sì ń máa fọ́lé onílé lóru. Nígbà tó yá, òkìkí mi bẹ̀rẹ̀ sí í kàn káàkiri, bí mo tún ṣe wọ ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta kan nìyẹn. Ìgbà yẹn ni mo wá di ìgárá ọlọ́ṣà tó ń fọ́ báǹkì. Mo tètè gbayì lójú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi tó kù nítorí pé ìwà jàgídíjàgan mi lékenkà. Ìbọn máa ń wà lára mi níbikíbi tí mo bá lọ. Kódà, tí mo bá fẹ́ sùn, màá rọra fi í sábẹ́ ìrọ̀rí mi. Kò sí irú ìwà ìpáǹle tí mi kì í hù, ṣé ti oògùn olóró lẹ fẹ́ sọ ni tàbí ti olè jíjà, ọ̀rọ̀ rírùn àti ìṣekúṣe, gbogbo rẹ̀ ló kún ọwọ́ mi. Mo wá di ọ̀daràn tí àwọn ọlọ́pàá ń wá lójú méjèèjì. Àìmọye ìgbà ni mo ti fi ẹ̀wọ̀n jura, tí wọ́n bá tú mi sílẹ̀, kì í pẹ́ tí wọ́n á tún fi mú mi, tì wọ́n á sì tì mí mọ́lé.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Nígbà kan tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, mo lọ sọ́dọ̀ àbúrò ìyá mi fúngbà díẹ̀. Èmi ò kúkú mọ̀ pé òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ti di Ajẹ́rìí. Wọ́n ṣáà rọ̀ mí pé kí èmi náà wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí ojúmìító tí mo fẹ́ ṣe, mo tẹ̀ lé wọn lọ. Nígbà tá a dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìpàdé, mo takú pé  ìtòsí ilẹ̀kùn ni màá jókòó sí kí n lè máa ṣọ́ àwọn tó ń wọlé tó sì ń jáde. Mi ò kúkú túra lẹ̀, digbí ni ìbọn wà lápò mi.

Tèmi n tiyín tòótọ́, ìpàdé yẹn ló tún ayé mi ṣe. Ńṣe ló dà bíi pé ilẹ̀ ayé míì ni mo wà! Ojú àwọn tó wà níbẹ̀ tutù, wọ́n túra ká sí mi, ẹ̀rín músẹ́ ni wọ́n fi ń bá mi sọ̀rọ̀. Mo ṣì rántí bí wọ́n ṣe yẹ́ mi sí lọ́jọ́ náà, wọn ò fura òdì sí mi bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ò fojú ọmọọ̀ta wò mí. Ohun tí wọ́n ṣe jọ mí lójú gan-an nítorí pé nǹkan ò rí bẹ́ẹ̀ nígboro rárá!

Èyí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bi ẹ̀kọ́ mi ṣe ń tẹ̀ síwájú ló túbọ̀ ń yé mi sí i pé ó yẹ kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ohun tó wà nínú ìwé Òwe 13:20 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Mo rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì yẹ kí n yẹra fún ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tí mò ń kó. Kò rọrùn fún mi, àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo sì fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.

Látìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́pá ìwàkiwà àti àṣàkaṣà tó kún ọwọ́ mi tẹ́lẹ̀

Mo tún sẹ àwọn ìyípadà kan. Mo sapá gan-an kí n lè jáwọ́ nínú sìgá mímu àti lílo oògùn olóró. Bákàn náà, mo gé irun mi, mo tún yọ yẹtí etí mi sọnù, mo sì jáwọ́ nínú sísọ ọ̀rọ̀ rírùn. Látìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́pá ìwàkiwà àti àṣàkaṣà tó kún ọwọ́ mi tẹ́lẹ̀.

Àmọ́ mo wá ní ìṣòro kan, mi ò gbádùn kí n máa kàwé, mi ò sì fẹ́ràn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́. Èyí jẹ́ kó ṣòro fún mi láti pọkàn pọ̀ kí n lè fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ sílò. Síbẹ̀, mo tiraka, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Mo máa ń rò pé Jèhófà ò lè dárí jì mí fún gbogbo ìwà burúkú tí mo ti hù sẹ́yìn. Àmọ́ tí ìrònú yìí bá ti wá sí mi lọ́kàn, mo máa ń ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe dárí ji Dáfídì Ọba nígbà tó ṣẹ̀, èyí sì máa ń mú kí ara tù mí.—2 Sámúẹ́lì 11:1–12:13.

Ìṣòro míì tó kà mí láyà ni bí màá ṣe máa wàásù láti ilé-dé-ilé. (Mátíù 28:19, 20) Ẹ̀rù máa ń bà mí kí n má lọ pàdé àwọn tí mo ti ṣe ní jàǹbá rí! Ṣùgbọ́n díẹ̀díẹ̀ ni ìbẹ̀rù yẹn kúrò lọ́kàn mi. Mo wá rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ nípa Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì máa ń dárí jì wà fàlàlà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí mo kọ́ ló gbà mí là! Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń hùwà jàǹdùkú kiri nígbà yẹn ló ti kú, àwọn míì sì wà lẹ́wọ̀n. Àmọ́ ìgbésí ayé tèmi nítumọ̀, mo sì ń retí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Mo ti di onírẹ̀lẹ̀, mo sì ń ṣègbọràn. Mi ò kì í bínú lódì mọ́, èyí sì ti jẹ́ kí ń máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Ọlọ́run tún fún mi ní arẹwà obìnrin kí n fi ṣaya, Carmen lorúkọ rẹ̀. Àwa méjèèjì ń gbádùn bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì ń fún wa láyọ̀.

Ní báyìí, iṣẹ́ ọmọlúwàbí ni mò ń ṣe ní báǹkì. Dípò kí n máa jà wọ́n lólè bíi tí tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mò ń bá wọn ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó.