Báwo ni àwọn atukọ̀ òkun ṣe ń ṣe ọkọ̀ òkun wọn kí omi bàa wọnú rẹ̀?

Ọ̀mọ̀wé Lionel Casson tó máa ń ṣè ìwádìí nípa àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń lò láyé àtijọ́ sọ ohun tí àwọn ará Róòmù máa ń ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dí àwọn àlàfo tó máa ń wà nínú pákó tí wọ́n fi kan ọkọ̀ ojú omi náà. Ohun tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn ni pé “wọ́n á fi ọ̀dà bítúmẹ́nì tàbí ìda kun ọkọ̀ náà tinú-tòde.” Ṣáájú kí àwọn ará Róòmù tó já ọgbọ́n yìí ni àwọn ará Ákádíánì àti àwọn ará Bábílónì ti ń lo ọ̀dà bítúmẹ́nì kí omi má baà wọnú ọkọ̀ òkun wọn.

Ọ̀dà bítúmẹ́nì olómi bí irú èyí pọ̀ gan-an láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan

Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa irú ọgbọ́n yìí nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:14. Ọ̀dà bítúmẹ́nì tí Bíbélì lò níbí ń tọ́ka sí ohun èèlò kan tí wọ́n máa ń rí lára epo rọ̀bì tí wọ́n wà jáde.

Ọnà méjì ni a lè gbà rí ọ̀dà bítúmẹ́nì, yálà kó jẹ́ èròjà olómi tàbí kó jẹ́ èròjà líle. Ọ̀dà bítúmẹ́nì olómi ni àwọn tó máa ń kan ọkọ̀ òkun láyé àtijọ́ máa ń fi kun ọkọ̀ wọn. Tó bá gbẹ tán, á gan mọ́ ọ lára, èyí kò sì ní jẹ́ kí omi lè wọlé sí inú rẹ̀.

Ọ̀dà bítúmẹ́nì pọ̀ gan-an láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan. Àpẹẹrẹ kan ni ti àfonífojì Sídímù tó wà ní agbègbè Òkun Òkú tó “kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòtò ọ̀dà bítúmẹ́nì.”—Jẹ́nẹ́sísì 14:10.

Báwo ni wọ́n ṣe máa ń tọ́jú ẹja láyé àtijọ́ kó má bàa bàjẹ́?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ka ẹja sí oúnjẹ pàtàkì. Iṣẹ́ apẹja ni díẹ̀ lára àwọn àpọ́sítélì Jésù ń ṣe ní Òkun Gálílì ṣáájú kí wọ́n tó di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 4:18-22) Wọ́n máa ń kó àwọn ẹja tí wọ́n bá pa lọ sí “àwọn iléeṣẹ́” kan tó wà nítòsí Gálílì, kí wọ́n lè ṣètò bí kò ṣe ní bàjẹ́.

Àwòrán àwọn apẹja ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì tí wọ́n gbẹ́ sára igi

Ìwé kan tó ń jẹ́ Studies in Ancient Technology sọ ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà tọ́jú ẹja ní iléeṣẹ́ náà, kódà àwọn kan ṣì ń lo ọ̀nà yìí títí dòní. Wọ́n á kọ́kọ́ yọ ihá rẹ̀, wọ́n á sì fomi fọ̀ ọ́. Ìwé náà sọ pé “wọ́n á fi iyọ̀ pa ìjàgbọ̀n, ẹnu àti ìpẹ́ rẹ̀. Wọ́n á wá po ẹja náà mọ́ iyọ̀ míì, wọ́n á sì fi ẹní bò ó. Wọ́n á wá fi í lẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-un nínú oòrùn kó lè gbẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí ẹja náà pa dà sí òdì kejì kí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì lè gbẹ dáadáa. Ní àsìkò yìí gbogbo omi ara rẹ̀ máa gbẹ, iyọ̀ náà á sì wọ inú rẹ̀ dáadáa. Tí ẹja náà bá gbẹ tán, á le gbagidi.”

A ò lè sọ bí ẹja tí wọ́n yan lọ́nà yìí ṣe máa pẹ́ tó kó tó di pé ó bàjẹ́. Àmọ́ bí àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì ṣe ń ta àwọn ẹja yìí sí ilẹ̀ Síríà fi hàn pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́jú ẹja nígbà náà lọ́hùn-ún gbéṣẹ́ gan-an.