Sìgá mímu ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ èèyàn.

  • Ó pa ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù [100,000,000] èèyàn ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá.

  • Mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] èèyàn ló ń pa lọ́dọọdún.

  • Ó kéré tán, sìgá mímu ń pa èèyàn kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá mẹ́fà.

Síbẹ̀, ọṣẹ́ tí sìgá ń ṣe kò dínkù.

Àwọn aláṣẹ sọ pé tí wọn kò bá yanjú ìṣòro yìí, àwọn tí sìgá á máa pa lọ́dọọdún á lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] tó bá máa fi di ìparí ọdún 2030. Wọ́n wá fojú bù ú pé tó bá fi máa di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún tá a wà yìí, àwọn tí á ti kú nítorí sìgá mímu máa tó bílíọ̀nù kan [1,000,000,000].

Àwọn tó ń mu sìgá nìkan kọ́ ni ìṣòro yìí kàn. Ẹ̀dùn ọkàn tó ń bá ìdílé wọn kì í ṣe kèrémí, àtigbọ́ bùkátà pàápàá máa ń di ìṣòro fáwọn mọ̀lẹ́bí. Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún látara èéfín sìgá tó ń tú sínú afẹ́fẹ́. Gbogbo èèyàn ni ọ̀rọ̀ náà kàn báyìí nítorí pé owó tí èèyàn ń ná lórí ìlera ti ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Sìgá mímu ò dà bí àjàkálẹ̀ àrùn tí àwọn dókítà ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń wá oògùn fún, àrọ́wọ́tó ni ojútùú sí ìṣòro yìí wà. Abájọ tí Dókítà Margaret Chan tó jẹ́ ọ̀gá àgbà fún Àjọ Ìlera Àgbáyé fi sọ pé: “Àfọwọ́fà àwa èèyàn ni ìṣòro sìgá mímu tó ń jà ràn-ìn kárí ayé yìí, ó sì ṣeé yanjú tí gbogbo wa bá fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti gbógun ti ìṣòro yìí.”

Àwọn èèyàn kárí ayé ti sapá gan-an kí wọ́n lè wá ojútùú sí ìṣòro sìgá mímu yìí. Ní oṣù August ọdún 2012, nǹkan bí orílẹ̀-èdè márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] ló para pọ̀ láti wá ojútùú sí ìṣòro tí sìgá mímu ń fà tàbí kí wọ́n dín báwọn èèyàn ṣe ń mu ún kù. * Bí wọ́n ṣe sapá tó, àwọn nǹkan kan wà tí kò jẹ́ kí ìṣòro yìí kásẹ̀ nílẹ̀. Lọ́dọọdún, àwọn iléeṣẹ́ tó ń ta sìgá máa ń ná ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là láti polówó sìgá kí wọ́n lè rí àwọn oníbàárà tuntun ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà àti pàápàá láàárín àwọn obìnrin. Torí pé sìgá tètè máa ń di bárakú, bílíọ̀nù kan èèyàn ló ti jingíri sínú àṣà yìí, èyí sì fi hàn pé lọ́jọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì máa jìyà àkóbá tí sìgá ń fà. Tí àwọn tó ń mu sìgá ò bá jáwọ́, iye àwọn tí sìgá máa pa ní ogójì ọdún sígbà tí a wà yìí máa pọ̀ gan-an.

Lóòótọ́, ó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti jáwọ́ nínú sìgá, àmọ́ kò rọrùn fún wọn torí pé ó ti di bárakú àti pé àwọn ìpolówó tó ń gbé sìgá lárugẹ ò tún jẹ́ kí wọ́n lè mójú kúrò níbẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Naoko nìyẹn. Àti kékeré ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Bó ṣe ń wo àwọn tó ń fa sìgá lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù àti àwọn ìwé ìròyìn máa ń jẹ́ kó wù ú, bí òun náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mu ún nìyẹn. Ó mọ̀ pé àrùn jẹjẹrẹ tó mú àwọn òbí rẹ̀ ní ẹ̀dọ̀fóró ló pa wọ́n, síbẹ̀ kò jáwọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ń tọ́ ọmọbìnrin méjì lọ́wọ́ nígbà náà. Naoko sọ pé: “Ká sòótọ́, ẹ̀rù máa ń bà mí pé àrùn jẹjẹrẹ lè mú èmi náà ní ẹ̀dọ̀fóró tàbí kó tún ṣàkóbá fún ìlera àwọn ọmọ mi, síbẹ̀ ó ṣòro gan-an fún mi láti jáwọ́, ó máa ń ṣe mi bíi pé mi ò lè fi sìgá sílẹ̀.”

Nígbẹ̀yìn, Naoko jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti jáwọ́ ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míì náà lọ́wọ́ láti yàgò pátápátá fún sìgá. Kí ni ohun náà? Jọ̀wọ́ máa kàwé yìí nìṣó.

^ ìpínrọ̀ 11 Lára àwọn nǹkan tí wọ́n ti ṣe ni pé wọ́n ṣe ìkéde nípa ewu tó wà nínú sìgá, wọ́n fòfin de ìpolówó sìgá, wọ́n fi owó kún owó orí tí wọ́n ń san, wọ́n sì tún ṣe àwọn ètò kan láti ran àwọn tó ń mu sìgá lọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́.