Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé?

Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé kó lè jẹ́ ibùgbé aláyọ̀ fún ìran èèyàn

Ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé inú rẹ̀. Ó pèsè omi tó pọ̀ láti gbé ẹ̀mí ró. Ìwọ̀n tí ayé fi dẹ̀gbẹ́, bó ṣe ń yí po àti bó ṣe jìnnà sí oòrùn ni kò jẹ́ kí ó gbóná tàbí tutù ju bó ṣe yẹ lọ. Òfuurufú àti agbára òòfà ilẹ̀ ayé máa ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ìtànṣán oòrùn tó lè jóni gbẹ. Bákan-náà, ó tún yani lẹ́nu láti rí bí àwọn ewéko, ẹranko, èèyàn àti àwọn ẹ̀dá míì ṣe ń ran ara wọn lọ́wọ́ láti gbé ìwàláàyè ara wọn ró. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí.—Ka Aísáyà 45:18.

Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ṣé ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ tó kún inú ayé wà lára ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ayé yìí?—Ka Diutarónómì 32:4, 5.

Ǹjẹ́ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé yìí ṣì máa ṣẹlẹ̀?

Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé kó lè jẹ́ ibùgbé aláyọ̀ fún wa, ó fẹ́ kí àwa èèyàn inú rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ òun tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ká sì tún nífẹ̀ẹ́ ara wa. Torí náà, Ọlọ́run kà wá sí pàtàkì ju ewéko àti ẹranko lọ. A láǹfààní láti mọ Ẹlẹ́dàá wa ká sì sún mọ́ ọn. Èyí ń jẹ́ ká mọrírì ìfẹ́ tó ní sí wa àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀, àwa náà sì lè fara wé e.—Ka Oníwàásù 12:13; Míkà 6:8.

Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti ṣe gbogbo ohun tó ní lọ́kàn. Nígbà náà, ó dá wa lójú pé ó máa tó fòpin sí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ, á sì sọ ayé yìí di ibi tó dùn ún gbé fún ìran èèyàn.—Ka Sáàmù 37:11, 29; Aísáyà 55:11.