Kò sí ẹ̀dá tí kì í ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Gbogbo wa la máa ń ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí fún wa àti àwọn èèyàn wa. A sábà máa ń béèrè àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ ayé yìí á ṣì dáa, tí a sì ro èmi àti àwọn ọmọ mi lọ́rùn? Ṣé àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ kò ní pa ayé yìí run báyìí? Kí ni mo lè ṣe tí nǹkan á fi dẹrùn fún mi lọ́jọ́ iwájú?’ Àwa èèyàn ò lè ṣe ká má ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la nítorí pé ìwà ẹ̀dá ni. Ó máa ń wù wá ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ká sì ní ìdánilójú nípa ohun tá a ń retí lọ́jọ́ iwájú àti pé a máa ń wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú tó tura, tí nǹkan á sì máa lọ déédéé. Ó dájú pé ká ní ọgbọ́n kan wà téèyàn lè dá sí i tí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ á fi dáa, gbogbo ohun tó bá gbà lèèyàn ò bá fún-un.

Ṣùgbọ́n ta ló mọ bí nǹkan á ṣe rí fún òun lọ́jọ́ iwájú? Ta ló lè sọ? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ nípa ọjọ́ ọ̀la ló ti ṣẹ, síbẹ̀, àìmọye àsọtẹ́lẹ̀ wọn ni kò ṣẹ. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run sọ pé bí òun bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, kò sí ohun tó lè yẹ̀ ẹ́. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run ni “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.” (Aísáyà 46:10) Ǹjẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ máa ń ṣẹ?

ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ỌLỌ́RUN TÓ TI ṢẸ

Kí nìdí tó fi yẹ kí o gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ ní ayé àtijọ́ yẹ̀ wò, kí o sì wo bí wọ́n ṣe ṣẹ? Tó o bá mọ ẹnì kan tó ti máa ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń ṣẹ, ó dájú pé wàá túbọ̀ fọkàn tán an, wàá sì tún gba ohun tó bá sọ lọ́jọ́ míì gbọ́. Lọ́nà kan náà, tó o bá mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí sẹ́yìn tó sì ṣẹ, kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ láti mọ àwọn ìlérí tó ti ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.

Odi tí wọ́n tún kọ́ níbi àwókù ìlú Nínéfè àtijọ́

ÌLÚ OLÓKÌKÍ TÓ PA RUN:

Bí àpẹẹrẹ, ohun àgbàyanu ni àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìlú ńlá kan tó ti jẹ́ alágbára fún àìmọye ọdún máa pa run. Ọlọ́run tipasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn wòlíì rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Nínéfè yóò di  ahoro. (Sefanáyà 2:13-15) Kí ni àwọn òpìtàn sọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún kí Jésù tó wá sáyé, àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Mídíà para pọ̀ gbéjà ko ìlú Nínéfè, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Láfikún sí i, Ọlọ́run ti sọ ṣáájú ní pàtó pé Nínéfè ‘yóò di ahoro bí aginjù.’ Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó ṣeé ṣe kí ìlú Nínéfè àti àwọn ìgbèríko tó yí i ká fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba [200] ibùsọ̀. Síbẹ̀, àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Mídíà tó ṣẹ́gun wọn kò dá àwọn ìlú wọ̀nyẹn sí rárá, kódà wọn kò fi ilẹ̀ náà ṣe nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n pa á run pátápátá. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó máa ń rí sí ọ̀ràn òṣèlú lè fi ìdánilójú sọ pé ibi tọ́rọ̀ náà á pa dà já sí nìyí?

YÓÒ FI INÁ SUN EGUNGUN ÀWỌN ÈÈYÀN:

Ta ló lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ẹnì kan máa sun egungun àwọn èèyàn lórí pẹpẹ ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún sígbà yẹn? Tí á sì tún sọ orúkọ àti ìlà ìran ẹni náà títí kan ìlú tí wọ́n máa gbé pẹpẹ náà sí? Tí irú àsọtẹ́lẹ̀ tó pabanbarì bẹ́ẹ̀ bá lè ṣẹ, ó dájú pé òkìkí ẹni tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà á kàn délé dóko. Wòlíì Ọlọ́run kan sọ pé ‘ọmọkùnrin kan ní ilé Dáfídì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsáyà yóò fi iná sun egungun àwọn èèyàn’ lórí pẹpẹ tó wà ní ìlú Bẹ́tẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 13:1, 2) Bí Ọlọ́run ṣe sọ gẹ́lẹ́ náà ló ṣe ṣẹlẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún lẹ́yìn náà, ọba kan tó ń jẹ́ Jòsáyà tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì “ránṣẹ́, ó sì kó egungun láti inú àwọn ibi ìsìnkú, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ” tó wà ní ìlú Bẹ́tẹ́lì. (2 Àwọn Ọba 23:14-16) Ọlọ́run tó lágbára ju ẹ̀dá lọ fíìfíì ló lè sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kó sì tún fún wa ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bó ṣe máa ṣẹ.

Àwọn wòlíì tó wà nínú Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Bábílónì lọ́nà tó ṣe rẹ́gí

ÌPARUN ILẸ̀ ỌBA KAN:

Ohun àgbàyanu gbáà ló máa jẹ́ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ọkùnrin kan ṣe máa pa ilẹ̀ ọba alágbára ńlá kan tó ń ṣàkóso ayé run. Kódà, ó dárúkọ ọkùnrin náà ṣáájú kí wọ́n tó lóyún rẹ̀ àti ọ̀nà àrà tó máa gbà ṣẹ́gun. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Kírúsì ni ẹni tí yóò gbógun ja ìlú náà. Kírúsì yìí náà ló máa dá àwọn Júù tí wọ́n wà nígbèkùn sílẹ̀. Ó sì tún máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tún tẹ́ńpìlì wọn kọ́. Ọlọ́run tún sọ pé lára ọgbọ́n tí Kírúsì máa dá ni pé, á mú kí odò tó ń ṣàn nínú ìlú náà gbẹ àti pé ẹnubodè ìlú náà  máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu kí wọ́n lè jagun náà ní àjàṣẹ́gun. (Aísáyà 44:27–45:2) Ǹjẹ́ ohun tí Ọlọ́run sọ yìí rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́? Àwọn òpìtàn gbà pé lóòótọ́ ni Kírúsì ṣẹ́gun ìlú yìí. Àwọn ọmọ ogun Kírúsì dá ọgbọ́n tó pabanbarì nígbà tí wọ́n darí ọ̀kan lára odò àwọn ará Bábílónì gba ibòmíràn, èyí sì mú kí odò náà fà. Làwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá ya wọnú ìlú ńlá náà nítorí pé ẹnubodè wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu. Lẹ́yìn náà, Kírúsì dá àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, ó sì ní kí wọ́n lọ tún tẹ́ńpìlì wọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Ọ̀rọ̀ yẹn yani lẹ́nu, torí kì í ṣe Ọlọ́run àwọn Júù ni Kírúsì ń jọ́sìn. (Ẹ́sírà 1:1-3) Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan yàtọ̀ sí Ọlọ́run tó lè s àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé bíi ti ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí?

A ti gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò báyìí tó fi bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ ṣe ṣẹ. Àwọn ìtàn yìí kì í ṣe ìtàn àròsọ nítorí pé àwọn èèyàn jẹ́rìí sí i. Aṣáájú àwọn Júù ìgbàanì, ìyẹn Jóṣúà sọ ohun kan lójú ògìdìgbó àwọn èèyàn náà tí àwọn náà sì lè jẹ́rìí sí dáadáa, ó ní: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣúà 23:1, 2, 14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jóṣúà gbà lóòótọ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá ló máa ń ṣẹ. Àmọ́, kí ló mú kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run péye? Ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣe nǹkan yàtọ̀ pátápátá sí ti àwa èèyàn. Ó ṣe pàtàkì pé kí o mọ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí nítorí Ọlọ́run ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ọjọ́ iwájú tó máa kan ìwọ alára.

ÌYÀTỌ̀ LÁÀÁRÍN ÀSỌTẸ́LẸ̀ ỌLỌ́RUN ÀTI TI ÈÈYÀN

Àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ sábà máa ń dá lórí àwọn ìwádìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tó fi mọ́ ti àwọn abẹ́mìílò pàápàá. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kéde àwọn ohun tí wọ́n sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń káwọ́ gbera tí wọ́n á sì máa retí ohun tí á ṣẹlẹ̀.—Òwe 27:1.

Ká sòótọ́, ohun táwa èèyàn bá rí nìkan la mọ̀, àmọ́ ní ti Ọlọ́run kò sí ohun tó pa mọ́ lójú rẹ̀. Ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ láìkù síbì kan. Nítorí náà, tí Ọlọ́run bá fẹ́, ó lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la sí ẹnì kan tàbí sí ìlú kan. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà, ó lè yí àwọn nǹkan kan pa dà tó fi mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kó lè bá ohun tó ní lọ́kàn mu. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, . . . yóò sì ní àṣeyọrí sí rere.” (Aísáyà 55:11) Lọ́rọ̀ kan, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ọlọ́run máa rí i dájú pé gbogbo ohun tí òun bá sọ yóò ṣẹ pátápátá.

ỌJỌ́ Ọ̀LA RẸ

Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tiẹ̀ wà tó ṣe é fọkàn tán nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ àti ti àwọn èèyàn rẹ? Tó o bá mọ̀ pé ìjì líle kan ń bọ̀ wá jà láìpẹ́, ǹjẹ́ o kò ní wá ọ̀nà bí wàá ṣe sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ? Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó yẹ kó o ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì náà nìyẹn. Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìyípadà ńláǹlà máa dé bá ayé yìí láìpẹ́. (Wo àpótí náà: “ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la.”) Èyí sì yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ.

Rò ó wò ná: Bí ọ̀rọ̀ ayé yìí ṣe rí kò yàtọ̀ sí ohun tá a gbé yẹ̀ wò lókè yìí. Ńṣe ló dà bí ìtàn tá a ti kọ sínú ìwé kan téèyàn sì láǹfààní láti lọ wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ìparí rẹ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, . . . Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.’” (Aísáyà 46:10) Ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ń dúró de ìwọ àti ẹbí rẹ. O ò ṣe kúkú béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa ọjọ́ ọ̀la. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bá ẹ̀mí lò, wọn kì í sí gbọ́ ohùn ẹ̀dá ẹ̀mí èyíkéyìí; bákan náà wọn ò ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan téèyàn lè fi mọ ọ̀la. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n, wọ́n á sì kọ́ ẹ nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ti ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.