ÌBÀNÚJẸ́ dorí Màríà kodò débi pé níbi tó kúnlẹ̀ sí, ìrora tó bá a kọjá àfẹnu sọ. Bí omijé ṣe ń dà lójú rẹ̀, ló ń rántí igbe ìrora tí Jésù ọmọ rẹ̀ ké kẹ́yìn lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lóró fún ọ̀pọ̀ wákàtí lórí òpó igi. Lọ́jọ́ náà lọ́hùn-ún, òkùnkùn ṣú bolẹ̀ lọ́sàn-án gangan, ilẹ̀ ayé mì tìtì. (Mátíù 27:45, 51) Lójú Màríà, ṣe ló dà bíi pé Jèhófà lo àwọn ohun àrà ọjọ́ náà láti fi hàn pé òun ni ikú oró tí Jésù kú dùn jù lọ.

Kò pẹ́ tí ìmọ́lẹ̀ tàn, tí òkùnkùn tó bo Gọ́gọ́tà, ìyẹn ibi Agbárí, fi pòórá. Lọ́jọ́ yẹn, Màríà ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ gidigidi. (Jòhánù 19:17, 25) Oríṣiríṣi àròkàn lo ṣeé ṣe kó ti gba ọkàn rẹ̀, irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] sẹ́yìn. Nígbà yẹn, òun àti Jósẹ́fù ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ọmọ wọn jòjòló lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni, ibẹ̀ ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti lo ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò gbé àwọn nǹkan ńlá ṣe láyé. Àmọ́, bàbá àgbàlagbà yẹn tún sọ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa dà bíi pé wọ́n fi idà gígùn kan gún ọkàn Màríà. (Lúùkù 2:25-35) Wákàtí tí ìbànújẹ́ mu Màríà lómi yìí gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ bàbá yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ yé e ní kíkún.

Ìbànújẹ́ dá ọgbẹ́ sí Màríà lọ́kàn

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tó dunni tó ikú ọmọ ẹni, ó sì máa ń fa ọgbẹ́ ọkàn tó bùáyà fún àwọn òbí. Ẹ ò rí i pé ọ̀tá burúkú gbáà ni ikú jẹ́, gbogbo èèyàn ló sì máa ń dá lóró lọ́nà kan tàbí òmíràn. (Róòmù 5:12; 1 Kọ́ríńtì 15:26) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti fara da ọgbẹ́ ọkàn tí ikú máa ń dá ni? Bá a ṣe fẹ́ ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé Màríà látìgbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, àá túbọ̀ kọ́ nípa bí ìgbàgbọ́ ṣe ran Màríà lọ́wọ́ láti fara da ọgbẹ́ ọkàn.

“OHUN YÒÓWÙ TÍ Ó BÁ SỌ FÚN YÍN, Ẹ ṢE É”

Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún mẹ́ta àtààbọ̀ sẹ́yìn. Màríà kíyèsí pé ìyípadà kan máa tó ṣẹlẹ̀. Torí pé ní ìlú Násárétì, àwọn aráàlú ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù Oníbatisí àti bí ìwàásù rẹ̀ nípa ìrònúpìwàdà ṣe ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Màríà ti rí i pé Jésù gba àwọn ìròyìn yẹn gẹ́gẹ́ bí àmì pé àkókò ti tó láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán-an. (Mátíù 3:1, 13) Àmọ́ tí Jésù bá kúrò nílé, nǹkan á nira díẹ̀ fún Màríà àti àwọn àbúrò Jésù tó kù. Lọ́nà wo?

Nígbà yẹn, ó jọ pé Jósẹ́fù tó jẹ́ ọkọ Màríà ti kú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé kéèyàn pàdánù ẹni tó sún mọ́ni kò ṣàjèjì sí Màríà. * Abájọ tó fi jẹ́ pé lásìkò yìí wọn kì í pe Jésù ní “ọmọkùnrin káfíńtà náà” nìkan, àmọ́ wọ́n tún máa ń pè é ní “káfíńtà náà.” Ó hàn kedere pé Jésù ló ń bójú tó iṣẹ́ tí baba rẹ̀ fi sílẹ̀, òun ló sì ń gbọ́ bùkátà ìdílé títí kan ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ̀ bí tẹ̀lé e. (Mátíù 13:55, 56; Máàkù 6:3) Ká tiẹ̀ gbà pé Jákọ́bù tí wọ́n bí tẹ̀ lé Jésù ti ń kọ́ṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, kó lè máa bá iṣẹ́ ìdílé wọ́n nìṣó, ipa tó yẹ kí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí á yọ sílẹ̀ tí kò bá sí nítòsí mọ́. Bùkátà tó wà lọ́rùn Màríà pọ̀, àmọ́ ṣé bí nǹkan ṣe fẹ́ yí pa dà yìí kò ní máa bà á lẹ́rù? Àfàìmọ̀ kó máà rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbéèrè pàtàkì kan ni pé: Kí ni Màríà máa ṣe tí ọmọ rẹ̀ tí í ṣe Jésù ará Násárétì bá di Jésù Kristi ìyẹn Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí?  Bíbélì sọ nǹkan pàtàkì lórí kókó yìí.—Jòhánù 2:1-12.

Jésù ṣèrìbọmi lọ́dọ̀ Jòhánù, ó sì di Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run tàbí Mèsáyà. (Lúùkù 3:21, 22) Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ ti bọ́ sí kánjúkánjú, síbẹ̀, kò ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ nígbà tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá ń ṣe nǹkan ayọ̀. Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ ni wọ́n jọ lọ síbi àsè ìgbéyàwó kan ní Kánà. Ibẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàlá [13] sí Násárétì. Bí ayẹyẹ ṣe ń lọ lọ́wọ́, Màríà kíyèsí pé àwọn tó ń ṣe ìnáwó ń ṣàníyàn nípa nǹkan kan. Ó rí i pé ara àwọn èèyàn ò balẹ̀, àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ síra wọn. Àṣé ọtí ló tán tí wọ́n fi ń kùn lábẹ́lẹ̀! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nínú àṣà àwọn Júù, ohun ìtìjú ni fún ìdílé tó ń ṣe ìnáwó tí ọtí bá tán níbi àríyá, àìní ẹ̀mí aájò àlejò ni wọ́n ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí. Ìdí tí àánú fi ṣe Màríà nìyẹn, ló bá lọ bá Jésù.

Ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé “Wọn kò ní wáìnì kankan.” Kí ló ń retí pé kí Jésù ṣe? A ò lè sọ ní pàtó, ṣùgbọ́n, ó mọ̀ pé ẹni ńlá tó lè ṣe nǹkan ńlá ni ọmọ òun. Ó sì lè máa retí pé kí ọmọ náà kúkú bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ níbẹ̀. Lọ́rọ̀ kan, ohun tó ń sọ ni pé: “Ọmọ, tètè wá nǹkan kan ṣe sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí.” Àmọ́ èsì tí Jésù fún un á yà á lẹ́nu. Jésù sọ pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin?” Ọ̀pọ̀ máa ń ka ọ̀rọ̀ Jésù yìí sí àrífín, àmọ́ kì í ṣe àrífín o. Ó kàn dọ́gbọ́n tọ́ ìyá rẹ̀ sọ́nà ni. Ohun tó wulẹ̀ ń sọ fún ìyá rẹ̀ ni pé Jèhófà Baba rẹ̀ ló lẹ́tọ̀ọ́ láti darí bí òun ṣe gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun.

Màríà ò gba ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú, torí pé onírẹ̀lẹ̀ ni, ohun tí ọmọ rẹ̀ sọ ti yé e. Ó wá sọ fún àwọn tó ń gbé oúnjẹ níbi ayẹyẹ náà pé: “Ohun yòówù tí ó bá sọ fún yín, ẹ ṣe é.” Ohun tí Màríà ṣe yìí fi hàn pé ó mọ ipò rẹ̀, ó gbà pé kì í tún ṣe ojúṣe òun mọ́ láti máa darí Jésù, àfi kí òun àti àwọn tó kù máa gba ìdarí lọ́dọ̀ Jésù. Ohun tí Jésù ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé ó gba ti tọkọtaya yẹn rò lọ́jọ́ ẹ̀yẹ wọn bí ìyá rẹ̀ ti ṣe. Ọjọ́ yẹn ló ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, ó sọ omi di wáìnì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn? “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” Màríà náà lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Ohun tó ṣe kọjá pé ó ka Jésù sí ọmọ rẹ̀, ńṣe lò ń wò ó bí Olúwa àti Olùgbàlà rẹ̀.

Ẹ̀yin òbí, ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pọ̀ fún yín nínú bí Màríà ṣe lo ìgbàgbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí òbí tó ti bí ọmọ tó dà bíi Jésù lónìí, síbẹ̀, àkókò tí ọmọ bá di géńdé sábà máa ń jẹ́ ìṣòro fún àwọn òbí kan. Tí òbí kò bá ṣọ́ra, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa hùwà sí ọmọ wọn tó ti dàgbà bíi pé ọmọdé ṣì ni, kò sì yẹ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran ọmọ wọn tó ti dàgbà lọ́wọ́? Ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n fọkàn tán àwọn ọmọ náà pé wọ́n máa ṣe ìpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu èyí tá a mú inú Jèhófà dùn, tí á sì jẹ́ kí wọ́n rí ìbùkún rẹ̀. Òbí tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń fọkàn ọmọ balẹ̀. Ó dájú pé Jésù gan-an mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí Màríà ṣe láwọn àkókò yẹn.

‘ÀWỌN ARÁKÙNRIN RẸ̀ . . . KÒ LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ RẸ̀’

Ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ fún wa nípa Màríà ní gbogbo ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Màríà ti di opó lákòókò yẹn, àwọn ọmọ rẹ̀ ṣì kéré, òun nìkan ló sì ń dá tọ́ wọn. Torí náà, pẹ̀lú àwọn ojúṣe tó wà nílẹ̀ yìí, ó lè máà ṣeé ṣe fún un láti máa tẹ̀lé Jésù kiri lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. (1 Tímótì 5:8) Síbẹ̀, ó ṣì máa ń ṣe àṣàrò lórí àwọn nǹkan  tẹ̀mí tó ti kọ́ nípa Mèsáyà, ó sì tún máa ń lọ sí ìpàdé ní Sínágọ́gù tó sún mọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ àṣà ìdílé wọn láti ìbẹ̀rẹ̀.—Lúùkù 2:19, 51; 4:16.

Ó ṣeé ṣe kí Màríà wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nínú Sínágọ́gù nílùú Násárétì. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ tí ọmọ rẹ̀ sọ pé òun ni Mèsáyà tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn! Ṣùgbọ́n á bà á nínú jẹ́ gan-an nígbà tó rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Násárétì ìlú rẹ̀ ni kò gba Jésù gbọ́, tí wọ́n sì tún wá ọ̀nà láti pa Jésù ọmọ rẹ̀!—Lúùkù 4:17-30.

Èyí tó ṣeé ṣe kó dùn ún jù ni bí àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù ṣe ń ṣe sí Jésù. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù 7:5 jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àbúrò Jésù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kò gba Jésù gbọ́ bíi ti ìyá wọn. Ẹsẹ yẹn kà pé: ‘Àwọn arákùnrin rẹ̀ . . . kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.’ Ó kéré tán, Jésù ní àbúrò obìnrin méjì. Àmọ́ Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa wọn. * Torí náà, Màríà mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí nínú ìdílé tí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, ó gbọ́dọ̀ sapá láti ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ bíi tiẹ̀, kò sì gbọ́dọ̀ le koko mọ́ wọn jù kí ọ̀rọ̀ má bàa di wàhálà.

Ìgbà kan wà tí àwọn ẹbí Jésù pinnu láti lọ “gbá a mú,” nítorí wọ́n rò pé: “Orí rẹ̀ ti yí.” (Máàkù 3:21, 31) Màríà ní tiẹ̀ kò lérò bẹ́ẹ̀ o, àmọ́ ó tẹ̀ lé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ débẹ̀ pẹ̀lú èrò pé wọ́n á kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó lè jẹ́ kí àwọn náà di onígbàgbọ́. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ rí nǹkan kan kọ́ lọ́dọ̀ Jésù? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, tó sì kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tó kù kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ǹjẹ́ Màríà wá rò wọ́n pin pátápátá pé wọn ò tiẹ̀ lè yí pa dà mọ́?

Tó bá jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìwọ náà ti wá, má bọkàn jẹ́, àpẹẹrẹ Màríà á gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró. Kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí kì í ṣe onígbàgbọ́ sú u, ńṣe ló ń hùwà lọ́nà tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ń fún òun ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àlàáfíà. Ó tún ti ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ lẹ́yìn. Ǹjẹ́ Màríà ò ní máa ṣàárò Jésù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan báyìí? Tàbí kó tiẹ̀ máa rò ó pé tí Jésù bá ṣì wà lọ́dọ̀ òun nǹkan ò bá tún sàn fún òun. Tí irú èrò yìí bá tiẹ̀ wá sí Màríà lọ́kàn, ó dájú pé ńṣe ló máa pa á mọ́ra. Màríà ka àǹfààní tó ní láti ti Jésù lẹ́yìn sí nǹkan ńlá. Ǹjẹ́ ìwọ náà ń ti ọmọ rẹ lẹ́yìn kó lè fi Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀?

‘A Ò FI IDÀ GÍGÙN KAN GÚN ỌKÀN RẸ̀’

Ǹjẹ́ Ọlọ́run san Màríà lérè nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀? Jèhófà kì í ṣe abaraámóorejẹ, èrè ńlá wà fún gbogbo ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, bọ́rọ̀ sì ṣe rí fún Màríà gẹ́lẹ́ nìyẹn. (Hébérù 11:6) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára rẹ̀ nígbà tó bá gbọ́ tí ọmọ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ tàbí tí àwọn míì tó gbọ́ ìwàásù rẹ̀ ní tààràtà ń ròyìn àwọn ohun tó sọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn àkàwé tí Jésù lò fi hàn pé ó gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù àti Màríà dáádáá

Nínú àwọn àpèjúwe tí Jésù lò, ó ṣeé ṣe kí Màríà ti rántí ìgbà tí Jésù ń dàgbà ní ìlú Násárétì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ àkàwé nípa obìnrin tó gbá ilé rẹ̀ títí tó fi rí ẹyọ owó kan tó sọ nù àti obìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti obìnrin tó tan fìtílà tó sì gbé e sórí ọ̀pá fìtílà. Ó ṣeé ṣe kí Màríà rántí pé ìgbà tí ọmọ rẹ̀ yìí wà ní kékeré ló ti kíyèsí pé òun ṣe gbogbo nǹkan tó ń sọ nínú àkàwé rẹ̀. (Lúùkù 11:33; 15:8, 9; 17:35) Nígbà tí Jésù sọ pé àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́, ó ṣeé ṣe kí Màríà ronú kan àsìkò tí Jésù wà ní ọmọ kékeré tó ń wo bí Jósẹ́fù ṣe ń kọ́ ọ bí èèyàn ṣe ń ṣe àjàgà tó sì ń fi ìṣọ́ra gbé e sọ́rùn ẹranko arẹrù kan kó má bàa wúwo jù fún un. (Mátíù 11:30) Ẹ ò rí i pé ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ ló máa jẹ́ fún Màríà bó ṣe ń ronú lórí àǹfààní àrà  ọ̀tọ̀ tí Jèhófà fún un láti kọ́ Jésù lẹ́kọ̀ọ́ tó sì tún wò ó dàgbà títí tó fi di Mèsáyà! Ó dájú pé, ayọ̀ rẹ̀ kún nígbà tó ń gbọ́ bí ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ olùkọ́ni tó tóbi jùlọ ṣe ń lo àwọn nǹkan tó wà láyìíká láti fi ṣàpèjúwe tó sì ń fa ẹ̀kọ́ tó ń wọni lọ́kàn yọ nínú wọn!

Láìka gbogbo nǹkan yìí sí, Màríà ṣì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. A ò rí i kà rí pé ọmọ rẹ̀ ń gbé e gẹ̀gẹ̀ kiri kí àwọn èèyàn lè máa wárí fún un. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí obìnrin kan dìde láàárín èrò níbi tí Jésù ti ń wàásù lọ́wọ́ tó sì sọ pé aláyọ̀ ni ìyá tó bíi lọ́mọ, Jésù dáhùn pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:27, 28) Nígbà táwọn míì tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ sọ fún un pé ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń wá a, ó sọ fún wọn pé ẹnì tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá òun. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kò bí Màríà nínú torí pé ohun tó sọ yé e. Ohun tó sì ń sọ ni pé okùn ọmọ ìyá yi lóòótọ́, síbẹ̀, àwọn tó gba òun gbọ́ lòun kà sí pàtàkì jù.—Máàkù 3:32-35.

Síbẹ̀, ta ló mọ bó ṣe máa dun Màríà tó bó ṣe ń wo Jésù ọmọ rẹ̀ tó ń joró ikú lórí igi? Àpọ́sítélì Jòhánù tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ pé: Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń lọ lọ́wọ́, Màríà dúró “lẹ́bàá òpó igi oró Jésù.” Kò sí ohun tó lè mú kí ìyá onífẹ̀ẹ́ yìí ṣàì dúró ti ọmọ rẹ̀ gbágbáágbá nígbà ìṣòro. Ohun tó sì ṣe nìyẹn títí tí ọmọ rẹ̀ fi mí èémí ìkẹyìn. Bí Jésù tiẹ̀ ń kú lọ, ó rí i pé ìyá rẹ̀ ṣì wà níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrora gógó ló fi ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń sọ àti èémí tó ń mí, síbẹ̀ ó sọ pé kí Jòhánù, ìyẹn àpọ́sítélì rẹ̀ tó fẹ́ràn jù máa mójú tó ìyá òun. Nígbà yẹn àwọn àbúrò rẹ̀ ṣì jẹ́ aláìgbàgbọ́ ìdí nìyẹn tó fi fa ìyà rẹ̀ lé Jòhánù lọ́wọ́. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí olùjọsìn Jèhófà máa tọ́jú ìdílé rẹ̀, pàápàá tó bá di ọ̀rọ̀ nǹkan tẹ̀mí.—Jòhánù 19:25-27.

Àmọ́ nígbà tí ikú Jésù dé, ọgbẹ́ ọkàn tó bùáyà ni Màríà fara dà gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ. Lóòótọ́ kò sí ohun tá a lè fi wé ìbànújẹ́ tó bá a nígbà ikú ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni ayọ̀ rẹ̀ kò láfiwé nígbà tí ọmọ rẹ̀ jíǹde lọ́jọ́ kẹta! Iṣẹ́ ìyanu tó lágbára gan-an lèyí jẹ́ fún Màríà! Orí ẹ̀ á tún wú nígbà tó gbọ́ pé Jésù fara han Jákọ́bù àbúrò rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:7) Ìfarahàn Jésù yìí wọ Jákọ́bù àtàwọn àbúrò rẹ̀ tó kù lọ́kàn débi pé àwọn náà gba Jésù gbọ́. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ìyá wọn lọ sí ìpàdé Kristẹni, tí wọ́n sì ‘tẹra mọ́ àdúrà’ gbígbà (Ìṣe 1:14) Kódà, méjì nínú wọn, ìyẹn Jákọ́bù àti Júdà wà lára àwọn tí Ọlọ́rùn lò láti kọ Bíbélì.

Inú Màríà dùn láti rí i pé àwọn ọmọ rẹ̀ tó kù náà di Kristẹni tòótọ́

Ohun tí a gbọ́ gbẹ̀yìn nípa Màríà ni pé ó máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìpàdé, wọ́n sì jọ máa ń gbàdúrà pa pọ̀. Ẹ ò rí i pé àkọsílẹ̀ tó lárinrin ni ọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé Màríà, ó sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ! Ìgbàgbọ́ tó ní ló jẹ́ kó ye idà oró, tó sì gba èrè lẹ́yìn-ọ-rẹyìn. Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀, àwa náà á lè fara da ọgbẹ́ yòówù tí ayé burúkú yìí lè dá sí wa lára, àá sì gba èrè tó gadabú.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìgbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá [12] nìkan la gbọ́ orúkọ Jósẹ́fù kẹ́yìn nínú Ìwé Ìhìn Rere. Lẹ́yìn ìyẹn, ìyá Jésù àti àwọn àbúrò rẹ̀ la tún ń gbọ́ orúkọ wọn. Kódà, wọ́n máa ń pe Jésù ní “ọmọkùnrin Màríà” láì tiẹ̀ mẹ́nu kan Jósẹ́fù.—Máàkù 6:3.

^ ìpínrọ̀ 16 Jósẹ́fù kọ́ ni bàbá tó bí Jésù lọ́mọ, nítorí náà, ọmọ ìyá ni òun àti àwọn àbúrò rẹ̀, wọn kì í ṣe ọmọ bàbá kan náà.—Mátíù 1:20.