Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  May 2014

 ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Jésù Gbọ́?

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Jésù Gbọ́?

Ìjíròrò kan tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Akin lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Káyọ̀dé.

Ó ṢE PÀTÀKÌ KÁ GBA JÉSÙ GBỌ́

Akin: Ẹ ǹlẹ́ o. Inú mi dùn pé a tún ríra lónìí.

Káyọ̀dé: Ẹ káàbọ̀, inú tèmi náà dùn láti rí yín.

Akin: Mo mú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wá fún yín ni. Mo mọ̀ pé ẹ máa gbádùn àwọn ìwé ìròyìn yìí gan-an.

Káyọ̀dé: Ẹ ṣeun. Inú mi dùn pé ẹ wá lónìí nítorí pé mo ní nǹkan kan lọ́kàn tí mo fẹ́ bi yín.

Akin: Ẹ̀n-ẹ́n-ẹ̀n, kí ni nǹkan náà?

Káyọ̀dé: Ṣé ẹ rí i, mo sọ fún ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ nípa bí mo ṣe gbádùn ìwé tí ẹ fún mi lọ́jọ́ sí. Ló bá sọ pé mi ò gbọ́dọ̀ ka àwọn ìwé yín mọ́ nítorí pé ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù gbọ́. Mo wá sọ fún un pé màá béèrè lọ́wọ́ yín tẹ́ ẹ bá ti wá. Ṣé lóòótọ́ ni ẹ ò gba Jésù gbọ́?

Akin: Inú mi dùn pé ọ̀dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ ti béèrè ìbéèrè yẹn.

Káyọ̀dé: Ohun témi náà rò nìyẹn.

Akin: Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Jésù gbọ́. Kódà, a gbà pé kéèyàn tó lè rí ìgbàlà, ó gbọ́dọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù.

Káyọ̀dé: Èmi náà sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ pé ẹ ò gba Jésù gbọ́. Mo rántí pé a ò tíì jọ sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rí.

Akin: Òótọ́ ni, bóyá kí n ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí nígbà tá a bá ń wàásù.

Káyọ̀dé: Ó dáa.

Akin: Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 14:6. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló ń bá sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Ó kà pé: “Jésù wí fún un pé: ‘Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.’” Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, nípasẹ̀ ta ni a fi lè sún mọ́ Ọlọ́run?

Káyọ̀dé: Nípasẹ̀ Jésù ni.

Akin: Bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ohun táwa náà sì gbà gbọ́ nìyẹn. Bó ṣe wà nínú Bíbélì tá a kà yìí, lórúkọ ta ni a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run?

Káyọ̀dé: Lórúkọ Jésù ni.

Akin: Mo gbà pẹ̀lú yín. Ìdí nìyẹn tí mo fi máa ń gba gbogbo àdúrà mi lórúkọ Jésù. Bí gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe máa ń gbàdúrà nìyẹn.

Káyọ̀dé: Inú mi dùn láti mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Akin: Ẹsẹ Bíbélì míì tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni Jòhánù 3:16. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan fi pè é ní àkópọ̀ Ìhìn Rere. Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé tá a bá ní ká sọ gbogbo ohun tí Bíbélì ròyìn nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lápapọ̀, ó wà nínú Jòhánù 3:16. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kà á.

Káyọ̀dé: Kò burú. Ó kà pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́  nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Akin: Ẹ ṣeun. Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí rí?

Káyọ̀dé: Bẹ́ẹ̀ ni mo ti gbọ́ ọ láìmọye ìgbà ní Ṣọ́ọ̀ṣì.

Akin: Ṣàṣà lẹni tí ò mọ ẹsẹ Bíbélì yìí. Tẹ́ ẹ bá wò ó dáadáa, Jésù sọ kókó kan tó gba àfiyèsí, ó ní ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí àwa èèyàn ló mú kó ṣèlérí ìyè ayérayé fún wa. Ǹjẹ́ ẹ kíyèsí ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe?

Káyọ̀dé: A gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́.

Akin: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó pọndandan pé ká lo ìgbàgbọ́ nínú ọmọ bíbí kan ṣoṣo náà, ìyẹn Jésù Kristi. Tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nìkan la tó máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Kókó yìí wà ní ojú ìwé kejì ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí mo mú wá fún yín, nígbà tó ń sọ nípa ìdí tá a fi tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, lára ohun tó sọ ni pé “Ìwé ìròyìn yìí ń gbani níyànjú láti nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ẹni tó kú ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù sì ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.”

Káyọ̀dé: Ẹ̀n-ẹ́n, ìyẹn ni pé, ó wà nínú ìwé ìròyìn yín pé ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Jésù gbọ́ lóòótọ́.

Akin: Bẹ́ẹ̀ ni.

Káyọ̀dé: Kí wá nìdí táwọn èèyàn fi sọ pé ẹ ò gba Jésù gbọ́?

Akin: Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń mú káwọn èèyàn sọ bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń sọ ọ́ torí wọ́n gbọ́ ọ lẹ́nu àwọn míì. Tàbí kó jẹ́ àwọn pásítọ̀ wọn ló gbin irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ sí wọn lọ́kàn.

Káyọ̀dé: Àbí nítorí pé ẹ̀ ń pe ara yín ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà dípò kó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jésù, làwọn kan ṣe sọ pé ẹ ò gba Jésù gbọ́?

Akin: Ó ṣeé ṣe káwọn kan rò bẹ́ẹ̀.

Káyọ̀dé: Àmọ́ kí ló dé tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa Jèhófà lẹ máa ń sọ ní gbogbo ìgbà?

‘MO TI SỌ ORÚKỌ RẸ DI MÍMỌ̀’

Akin: Ohun kan nìyí, a gbà gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì láti lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Jésù ọmọ rẹ̀ ti ṣe. Ẹ wo ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Bàbá rẹ̀ nínú Jòhánù 17:26. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kà á.

Káyọ̀dé: Ó kà pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”

Akin: Ẹ ṣeun. Nínú ẹsẹ Bíbélì tí ẹ kà yẹn, Jésù sọ pé òun ti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀. Ǹjẹ́ ẹ mọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Káyọ̀dé: Rárá.

Lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ṣe pàtàkì kéèyàn lè rí ìgbàlà

Akin: Ó dáa, bóyá ká wo ẹsẹ Bíbélì míì tó ṣàlàyé kókó yìí dáadáa. Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí ìwé Ìṣe 2:21 sọ. Ó kà pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Tó bá jẹ́ pé kéèyàn máa pé orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì ká tó lè rí ìgbàlà, kò sí àní-àní pé Jésù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Káyọ̀dé: Bẹ́ẹ̀ ni.

Akin: Jésù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa lò ó kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ìdí nìyẹn tí àwa náà fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà ní gbogbo ìgbà. A mọ̀ pé, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa pè é.

Káyọ̀dé: Àmọ́ táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run tàbí tí wọn ò lò ó, wọ́n ṣì mọ̀ pé Ọlọ́run ni àwọn ń bá sọ̀rọ̀ nínú àdúrà.

Akin: Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Ṣùgbọ́n bó ṣe sọ orúkọ rẹ̀ fún wa ti mú kó ṣeé ṣe láti sún mọ́ ọn dáadáa.

Káyọ̀dé: Kí lẹ ní lọ́kàn?

Akin: Ó dáa, rò ó wò náà: Ká ní a ò mọ orúkọ Mósè, ohun tá a kàn mọ̀ ni pé òun ni ọkùnrin tó pín òkun pupa níyà tó sì tún gba Òfin  Mẹ́wàá. Tún wo Nóà, ká ní ohun tá a mọ̀ kò ju pé òun ló kan áàkì tó fi gba ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko là, tí a ò sì mọ orúkọ rẹ̀, tàbí ká sọ pé a ò mọ orúkọ Jésù Kristi, a kàn mọ̀ pé ọkùnrin kan wá láti ọ̀run láti wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ohun tó dájú ni pé a ṣì máa mọ̀ wọ́n, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Káyọ̀dé: Ó ṣeé ṣe.

Akin: Àmọ́ Ọlọ́run rí i dájú pé a mọ orúkọ àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn. Torí kò sí ohun tó dà bí ká fi orúkọ wọn mọ̀ wọ́n. Kódà bá ò tiẹ̀ rí Mósè, Nóà àti Jésù rí, orúkọ wọn tá a mọ̀ ló jẹ́ kí ìtàn àwọn èèyàn yìí wọ̀ wá lọ́kàn gan-an.

Káyọ̀dé: Mi ò tiẹ̀ rò ó bẹ́ẹ̀ rí, àmọ́ àlàyé tẹ́ ẹ ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu lóòótọ́.

Akin: Ìdí míì nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń lo orúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. A fẹ́ jẹ́ kí àwọn èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà kí wọ́n sì rí i gẹgẹ bí Ẹni gidi kan tó yẹ kí wọ́n sún mọ́. Bákan náà, a máa ń pe àfiyèsí sí ohun tí Jésù ti ṣe ká lè rí ìgbàlà. Ẹ jẹ́ kí á ka ẹsẹ Bíbélì kan tó ti ohun tá a sọ yìí lẹ́yìn.

Káyọ̀dé: Ó dáa.

Akin: Lẹ́ẹ̀kan, a ka ìwé Jòhánù 14:6, níbi tí Jésù ti sọ pé òun ni “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó sọ nínú Jòhánù 14:1. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ka ohun tí Jésù sọ ní ọwọ́ ìparí ẹsẹ Bíbélì yẹn.

Káyọ̀dé: Kò burú. Ó sọ pé: “Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.”

Akin: Ẹ ṣeun. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a ní ojúlówó ìgbàgbọ́, ó ju pé kéèyàn kàn yan ọ̀kan nínú Jèhófà tàbí Jésù.

Káyọ̀dé: Òótọ́ ni. Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn méjèèjì.

Akin: Mo gbà fún yín. Ó dá mi lójú pé ẹ̀yin náà gbà pé kéèyàn kàn sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Jésù kò tó. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé à ń lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn méjèèjì.

Káyọ̀dé: Òótọ́ lẹ sọ.

Akin: Àmọ́, báwo lẹ́nì kan ṣe lè fi hàn pé òun ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Jésù? Ó máa wù mí ká jọ jíròrò ìbéèrè yìí nígbà míì. *

Káyọ̀dé: Ó dáa bẹ́ẹ̀.

Ìbéèrè wo lo ní nípa Bíbélì tó ń jà gùdù lọ́kàn rẹ? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ á dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

^ ìpínrọ̀ 60 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 12 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì jw.org/yo.