TA ni Thomas Emlyn? Kí ló mú kó gbèjà òtítọ́? Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣe tó lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí?

Ká tó lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ìparí ọdún 1650 sí ọdún 1750 ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Orílẹ̀-èdè Ireland. Ní àkókò yẹn, Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ń pàṣẹ nínú ìlú, àṣẹ tí wọ́n bá sì pa ni abẹ́ gé. Àmọ́ onírúurú àwùjọ ẹ̀sìn àti ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn ní Ṣọ́ọ̀ṣì.

TA NI THOMAS EMLYN?

Àsìkò tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yìí gan-an ni wọ́n bí Thomas Emlyn, ní àgbègbè Stamford, ní ìpínlẹ̀ Lincolnshire lórílẹ̀-èdè England ní May 27, 1663. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ló wà nígbà tó ṣe ìwàásù rẹ̀ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà ló ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún obìnrin olóyè kan tó ń gbé ní ìlú London, nígbà tó sì yá, ó kó lọ sí ìlú Belfast ní orílẹ̀-èdè Ireland.

Iṣẹ́ pásítọ̀ ni Emlyn ń ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan ní ìlú Belfast, lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ṣiṣẹ́ àlùfáà ní àwọn ibòmíì títí kan ìlú Dublin.

KÍ LÓ MÚ KÍ WỌ́N FI Ẹ̀SÙN KÀN ÁN PÉ Ó SỌ̀RỌ̀ ÒDÌ?

Ní gbogbo àsìkò yìí, Emlyn ti ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ohun tó kẹ́kọ̀ọ́ mú kó máa ṣiyèméjì lórí ọ̀ràn Mẹ́talọ́kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bó ṣe ń ṣèwádìí nínú ìwé Ìhìn Rere, ó túbọ̀ ń dá a lójú pé àwọn òye rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sunwọ̀n sí i bá Bíbélì mu.

Kò kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tó ṣàwárí yìí. Àmọ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní Dublin bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé kì í mẹ́nu kan ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan nínú ìwàásù rẹ̀ mọ́. Emlyn mọ̀ pé àwọn èèyàn kan kò ní gbà pé òtítọ́ ni ìwádìí òun, ló bá kọ̀wé pé: “Kò rọrùn rárá fún mi láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa ohun tí mo gbà gbọ́ ní báyìí, nítorí èrò mi ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.” Nígbà tó di June 1702, àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ méjì ta kò ó pé kì í mẹ́nu kan Mẹ́talọ́kan nínú ìwàásù rẹ̀. Ló bá kúkú jẹ́wọ́ pé òun kò gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ mọ́, bó ṣe kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn.

Ìwé tí Emlyn tẹ̀ jáde tó ní àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tó jẹ́rìí sí i pé Jésù kì í ṣè Ọlọ́run Olódùmarè

Kò ju ọjọ́ díẹ̀ tó fi kúrò ní ìlú Dublin lórílẹ̀-èdè Ireland, tó sì gba ilẹ̀ England lọ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá, ó pa dà sí ìlú Dublin láti wá yanjú àwọn ọ̀ràn kan. Ó ti ní i lọ́kàn pé tí òun bá ti yanjú àwọn ọ̀ràn yìí tán, òun a kó lọ sí ìlú London láti máa gbé níbẹ̀ títí láé. Àmọ́ nígbà tó wà ní ìlú Dublin, ó pinnu láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé èrò òun tọ̀nà, ló bá tẹ ìwé kan jáde tó fi ṣàlàyé àwọn ìwádìí tó ṣe látinú Ìwé Mimọ nípa ìgbésí ayé Jésù, ìyẹn An Humble Inquiry Into the Scripture-Account of Jesus Christ. Inú ìwé yìí ló ti sọ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tó jẹ́rìí sí i pé Jésù kì í ṣè Ọlọ́run Olódùmarè. Èyí ló jẹ́ kí inú bí àwọn ọmọ ìjọ tí Emlyn wà tẹ́lẹ̀ ní ìlú Dublin, ni wọ́n bá pè é lẹ́jọ́.

Ní June 14, 1703, àwọn agbófinró mú Emlyn, wọ́n sí gbe lọ sí ilé ẹjọ́ gíga, ìyẹn Queen’s Bench Court tó wà ní ìlú Dublin. Nínú ìwé tó kọ nípa bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe lọ, ìyẹn True Narrative of the Proceedings, Emlyn sọ pé: “Wọ́n ní mo ta ko Kristi nínú ìwé tí mo kọ, àti pé mo sọ̀rọ̀ òdì pé Jésù Kristi kò bá Ọlọ́run dọ́gba, wọ́n sì ní mo jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí.” Ìgbẹ́jọ́ náà rí rúdurùdu,  nítorí kí ẹjọ́ náà tó bẹ̀rẹ̀ ní wọ́n ti mọ ìdáj tí wọ́n máa dá fún Emlyn. Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀ṣì Ireland méje ló wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà pẹ̀lú àwọn adájọ́. Wọn ò tiẹ̀ jẹ́ kó sọ̀rọ̀ rárá. Gbajúmọ̀ amòfin kan tó ń jẹ́ Richard Levins sọ fún Emlyn pé ṣe ni “wọ́n á ya bò ó bí ìgbà tí ọdẹ fẹ́ pa ìkookò, láìsí òfin kan tó ń dá wọn dúró.” Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń parí lọ, Richard Pyne tó jẹ́ adájọ́ àgbà pátápátá ní orílẹ̀-èdè Ireland sọ fún ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ pé tí wọ́n bá kùnà láti dá ẹjọ́ náà bí àwọn ṣe fẹ́, kí wọ́n rántí pé “àwọn Bíṣọ́ọ̀bù tó jẹ́ olúwa òun wà lórí ìjókòó,” ìyẹn ní pe, palaba ìyà máa jẹ wọ́n.

Thomas Emlyn sọ pé: “Mo jìyà nítorí ohun tí mo gbà gbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ògo rẹ̀.”

Wọ́n sọ pé Emlyn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, agbẹjọ́rò àgbà wá dábàá pé kó gbà pé ọ̀kan náà ni Jésù àti Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, Emlyn kọ̀ jálẹ̀. Ní wọ́n bá ní kó sanwó ìtanràn, kó sì tún lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko. Nítorí pé kò lówó tó lè fi sanwó ìtanràn, ọdún méjì ní ó lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ọpẹ́lọpẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀ pé kí wọn dín owó ìtanràn yẹn kù, kí wọ́n tó dá a sílẹ̀ ní July 21, 1705. Ìyà tó jẹ lẹ́wọ̀n ló mú kó sọ ohun tó wà lókè yẹn pé: “Mo jìyà nítorí ohun tí mo gbà gbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ògo rẹ̀.”

Lẹ́yìn èyí, Emlyn kó lọ sí ìlú London, ibẹ̀ ló sì tí pàdé ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ William Whiston tí òun náà ti jìyà nítorí ìwé tó kọ nípa ohun tó mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ tí Bíbélì sọ. Whiston kan sáárá sí Emlyn, ó sì pè é ní “Ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni gan-an bí wọ́n ṣe ń ṣe é láti ìbẹ̀rẹ̀.”

KÍ NÌDÍ TÍ KÒ FI GBA Ẹ̀KỌ́ MẸ́TALỌ́KAN GBỌ́?

Gẹ́gẹ́ bíi ti William Whiston àti Isaac Newton tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míì tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, Emlyn rí i pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tó wà nínú ìwé Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Athanasia tó ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni kò bá Bíbélì mu. Ó ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, tí mo sì ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí mo kọ́ . . . mo wá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu kí n yí èrò mi pa dà lórí ohun tí mo gbà gbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.” Ó parí èrò sí pé “Ọlọ́run ni Baba Jésù Kristi, òun nìkan sì ni Ẹni Gíga Jù Lọ.”

Kí ló mú kí Emlyn parí èrò sí ibẹ̀? Ó rí ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́rìí sí i pé Jésù àti Baba Rẹ̀ kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo. Díẹ̀ lára wọn nìyí (àwọn ohun ti Emlyn kọ́ silẹ̀ nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni a fi lẹ́tà wínníwínní kọ):

  •  Jòhánù 17:3: “Kristi kò fìgbà kankan sọ pé òun ni Ọlọ́run, tàbí kó sọ pé òun ni Ọlọ́run kan ṣoṣo náà.” Baba rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni Bíbélì pè ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.””

  •  Jòhánù 5:30: “Ọmọ kò ṣe ìfẹ́ ara rẹ̀, bí kò ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀.”

  •  Jòhánù 5:26: “Baba ló fún un ní ìwàláàyè.”

  •  Éfésù 1:3: “Nígbà tó jẹ́ pé Jésù Kristi ni a mọ̀ sí ọmọ Ọlọ́run, kò sí ibì kankan tí a ti rí i kà pé ẹnì kan ni Baba Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń gbọ́ pé òun ni Baba Olúwa wa Jésù Kristi.”

Lẹ́yìn tí Emlyn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ẹnikẹ́ni lè tọ́ka sí tàbí dọ́gbọ́n hùmọ̀ pé Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo àti pé nǹkan kan náà ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.”

KÍ LA RÍ KỌ́ LÁRA EMLYN?

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò láyà láti gbèjà ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ṣùgbọ́n, Emlyn gbèjà òtítọ́ Bíbélì. Ó béèrè ìbéèrè kan pé, “Tí ẹnì kan kò bá lè ṣàlàyé òtítọ́ tó ṣeyebíye jùlọ tó kọ́ nínú Ìwé Mímọ́, tó sì gbà gbọ́ pé òótọ́ ni, kí wá ni àǹfààní pé ó ń ka Ìwé Mímọ́, tó sì ń wá òtítọ́?” Emlyn ò juwọ́ sílẹ̀ nínú ìsapá rẹ̀ láti gbèjà òtítọ́.

Àpẹẹrẹ gidi ni Emlyn àti àwọn èèyàn míì fi lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kó sún wa láti ronú bóyá àwa náà ṣe tán láti gbèjà òtítọ́, kódà tí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń bẹnu àtẹ́ lù wá nítorí ohun tí a gbà gbọ́. Ẹ jẹ́ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ọlá àti ipò tí àwọn èèyàn lé fúnni ló ṣe pàtàkì jù ni àbí kí èèyàn dúró gbọn-in láti gbèjà òtítọ́ tó wà nínu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?’