Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  April 2014

O Borí Ìdẹwò!

O Borí Ìdẹwò!

“Ọ̀tọ̀ ni ohun tí mo wá lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣàdédé ni ìpolówó kan yọ lójú kọ̀ǹpútà, bí mo ṣe ṣí i báyìí ni àwòrán oníhòòhò bá yọ gan-n-boro sí mi!”—CODY. *

“Àìpẹ́ yìí ni ọmọbìnrin arẹwà kan níbi iṣẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi tage kó lè fa ojú mi mọ́ra. Ló bá sọ fún mi lọ́jọ́ kan pé ká jọ lọ ‘ṣeré ìfẹ́’ ní òtẹ́ẹ̀lì. Ohun tó ń fẹ́ ti yé mi.”—DYLAN.

T Ó bá di ọ̀ràn oríṣiríṣi ìgbádùn, àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé: “Kò ṣeé fi sára kú.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, àwọn èèyàn kan fẹ́ láti jẹ ìgbádùn láìka ewu tó wà níbẹ̀ sí. Ìdẹwò sì lèyí jẹ́. Ṣùgbọ́n ni ti àwọn èèyàn míì, wọn ka irú ìdẹwò bẹ́ẹ̀ sí ọ̀tá aléni-má-dẹ̀yìn tí àwọn gbọ́dọ̀ borí. Kí ni èrò tìẹ? Tí o bá kojú ìdẹwò, ṣé ó yẹ kó o juwọ́ sílẹ̀ ni àbí kó o wá bó o ṣe máa borí ìdẹwò náà?

Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìdẹwò ló máa ń yọrí sí ìṣòro ńlá. Bí àpẹẹrẹ, kò dájú pé bisikíìtì kan tí o lọ yọ́ jẹ lè ṣàkóbá fún ẹ. Àmọ́, tó o bá fàyè gba àwọn nǹkan míì, irú bí ìṣekúṣe, wọ́n lè kó ẹ sí yọ́yọ́. Ìdí nìyí tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá obìnrin ṣe panṣágà jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún; ẹni tí ó bá ṣe é ń run ọkàn ara rẹ̀.”—Òwe 6:32, 33.

Tí o bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ìṣekúṣe, kí ló yẹ kí o ṣe? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: ‘Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, pé kí ẹ wà ní mímọ́, kí ẹ ta kété sí àgbèrè; kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti kó ara rẹ̀ níjàánu nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.’ (1 Tẹsalóníkà 4:3, 4) Báwo lo ṣe lè kó ara rẹ níjàánu tó bá di ọ̀ràn ìṣekúṣe? Àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ rèé.

Àkọ́kọ́: Má Ṣe Wo Ìwòkuwò

Tí o bá ń wo ìwòkuwò, ńṣe ni á máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣe ìṣekúṣe. Jésù pàápàá fi hàn pé ohun téèyàn bá ń wò ló máa ń wà lọ́kàn èèyàn láti ṣe, abájọ tó fi kìlọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Kó lè fi bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó, ó lo àbùmọ́ tó fakíki nínú àrọwà rẹ̀ pé: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mátíù 5:28, 29) Kí ni Jésù ní lọ́kàn gan-an? Kókó ibẹ̀ ni pé, tí a bá fẹ́ yàgò fún ìṣekúṣe, àfi ká sá fún ìwòkuwò, a sì gbọ́dọ̀ pinnu pé a kò ní juwọ́ sílẹ̀ tí ìdẹwò bá dé.

Tí o bá ṣèèṣì rí àwòrán ìṣekúṣe, tètè gbójú kúrò

Ká sọ pé bó o ṣe ń kọjá lọ, o rí ajórin-mọ́rin kan táwọn kan ń pè ní wẹ́dà, tó ń fi iná jó irin pọ̀, iná rẹ̀ sì wọ̀ ẹ́ lójú bó ṣe ń bù yẹ̀rì, ṣé wàá túbọ̀ ranjú mọ́ ọn ni? Ńṣe ni wàá gbójú kúrò kí iná tó ń bù yẹ̀rì yẹn má bàa ba ojú rẹ jẹ́. Lọ́nà kan náà, tó o bá rí àwò rán oníhòòhò nínú ìwé, lórí kọ̀ǹpútà tàbí o rí ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí ní ìhòòhò, tètè yáa gbójú kúrò, kí o lè dáàbò bo ọkàn rẹ lọ́wọ́ ìwòkuwò tó ń sọ ọkàn ẹni dìbàjẹ́. Ọ̀gbẹ́ni Juan tó ti jingíri sínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe sọ pé: “Bí mo bá rí arẹwà obìnrin, àwòtúnwò ni mo máa ń wò ó, mi kì í gbójú kúrò bọ̀rọ̀. Torí náà, ńṣe ni mo máa ń sapá gan-an láti gbójú mi kúrò, màá sì sọ fún ara mi pé: ‘Gbàdúrà sí Jèhófà kíá! Tètè gbàdúrà kó tó pẹ́ jù!’ Gbàrà tí mo bá sì ti gbàdúrà ni èròkerò náà máa ń pòórá, ara á sì tù mí pẹ̀sẹ̀.”—Mátíù 6:9, 13; 1 Kọ́ríńtì 10:13.

Ìpinnu tí ọkùnrin olóòótọ́ náà, Jóòbù ṣe lè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ, ó ní: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Ìwọ náà lè ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.

Gbìyànjú èyí wò: Tí o bá ṣèèṣì rí àwòrán ìṣekúṣe fìrí, tètè gbójú kúrò. Fara wé òǹkọ̀wé Bíbélì kan tó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”—Sáàmù 119:37.

Ìkejì: Gbọ́kàn Kúrò Lórí Èròkerò

Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, nígbà míì, ìjàkadì la máa ń bá ara wa jà, ká lè borí èròkerò. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Báwo lo ṣe lè tètè gbé èròkerò kúrò lọ́kàn kó má bàa mu ẹ́ lómi débi tó fi máa ṣòro fún ẹ láti borí ìdẹwò?

Tí èrò ìṣekúṣe bá wá sí ẹ lọ́kàn, gbé e kúrò lọ́kàn, kí o sì gbàdúrà

Bí èròkerò bá wá sí ẹ lọ́kàn, rántí pé ìwọ fúnra rẹ ló máa pinnu ohun tí wàá ṣe. Bá èròkerò náà wọ̀yá ìjà. Sapá láti fà á tu kúrò nínú ọkàn rẹ, kó o sì pinnu pé o kò ní jẹ́ kí ọkàn rẹ máa ronú nípa ìṣekúṣe tí ń sọni di eléèérí. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Troy tí wíwo àwòrán ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di bárakú fún sọ pé: “Ńṣe ni mo máa ń jìjàkadì kí n lè fọ àwọn èrò ìṣekúṣe kúrò nínú ọpọlọ mi. Ká sòótọ́, kò rọrùn nítorí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èrò yẹn máa ń wá sí mi lọ́kàn. Àmọ́ mo sapá gan-an láti fi àwọn èrò tó dára rọ́pò èròkerò tó máa ń gbà mí lọ́kàn, èyí sì ti jẹ́ kí n lè ṣàkóso àwọn èrò mi dáadáa.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Elsa, ti òun náà sapá láti borí èròkerò tó ń súnni ṣe ìṣekúṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, sọ pé: “Mó máa ń jẹ́ kí ọwọ́ mi dí, ó ṣe tán ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni èṣù ń rán níṣẹ́. Mo tún máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, ìyẹn ló jẹ́ kí n lè mú èròkerò tó máa ń wá sí mi lọ́kàn kúrò.”

 Gbìyànjú èyí wò: Tí èrò ìṣekúṣe bá gbà ẹ́ lọ́kàn, tètè gbé e kúrò lọ́kàn, kí o sì gbàdúrà. Jà fitafita láti fọ èrò náà kúrò nínú ọpọlọ rẹ. Àwọn èrò tí o yẹ kí o máa gbé sọ́kàn gbọ́dọ̀ jẹ́ “ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn.”—Fílípì 4:8.

Ẹ̀kẹta: Má Ṣe Rin Ìrìnkurìn

Tó o bá ń ro èròkerò, tí ẹni kan sì fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, tí àǹfààní wá ṣí sílẹ̀ fún ẹ láti ṣe é, wàhálà dé nìyẹn o. (Òwe 7:6-23) Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní kó sínú páńpẹ́ yìí?

“Ìgbà tí àwọn tó kù bá wà nílé nìkan ni mo máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì”

Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Torí náà, ó yẹ kí o ṣọ́ra gidigidi. Jẹ́ ẹni tó ní ìfura, tó sì ń ronú jinlẹ̀. Ronú lórí àwọn ipò tó lè kó ẹ sí wàhálà, kó o sì yẹra fún wọn. (Òwe 7:25) Ọgbọ́n tí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Filipe dá sí ìṣòro rẹ̀ náà nìyẹn. Kó lè jáwọ́ nínú àwòrán ìṣekúṣe tó ń wò, ó ní: “Bí mo bá fẹ́ lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo máa ń gbé kọ̀ǹpútà síbi tí àwọn yòókù nínú ilé ti lè rí ohun tí mò ń ṣe, mo sì tún fi ètò orí kọ̀ǹpútà kan sórí rẹ̀ tí kì í jẹ́ kí àwòrán oníhòòhò wọlé. Mo tún pinnu pé ìgbà tí àwọn tó kù bá wà nílé nìkan ni màá máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.” Ọ̀gbẹ́ni Troy tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan tún sọ pé: “Mo yẹra fún wíwo àwọn fíìmù tó máa ń gbé àwòrán ìṣekúṣe jáde, mi ò sì jókòó ti àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ rírùn nípa ìbálòpọ̀. Mí ò fẹ́ kí wọ́n kó mi sí wàhálà.”

Gbìyànjú èyí wò: Fara balẹ̀ yẹ ara rẹ wò dáadáa kó o sì mọ ibi tó o kù sí, ronú nípa ohun tí wàá ṣe tí ìdẹwò bá dé kó o sì yẹra fún àwọn nǹkan tó o mọ̀ pé ó lè dẹ ẹ́ wò.—Mátíù 6:13.

Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ!

Ká sọ pé gbogbo ipá rẹ lo sà, síbẹ̀ ìdẹwò yẹn bá ẹ lábo, o sì ṣe àṣìṣe láìmọ̀, kí ni wàá ṣe? Má sọ̀rètí nù, má sì jẹ́ kó sú ẹ. Bíbélì sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” (Òwe 24:16) Tí a bá ṣubú, Baba wa ọ̀run fún wa níṣìírí pé, “ká dìde.” Àmọ́, ṣe wàá fẹ́ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, má ṣe jẹ́ kí àdúrà sú ẹ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóòrèkóòrè, kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára sí i. Ìpinnu tó o ṣe pé o kò ní juwọ́ sílẹ̀ á túbọ̀ dúró digbí tó o bá ń wá sí ìpàdé. Fọkàn balẹ̀, kó o sì gbára lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé: “Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Aísáyà 41:10.

Ọ̀gbẹ́ni Cody, tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Ó nira fún mi gan-an láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe, àìmọye ìgbà ni mo tún pa dà sídìí rẹ̀. Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, mo borí ìṣòro náà.” Ọ̀gbẹ́ni Dylan, náà sọ pé: “Mo láǹfààní láti ṣe ìṣekúṣe ká ní mo fẹ́ ṣe é ni. Mi ò bá ti bá obìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sùn tipẹ́tipẹ́, àmọ́ mo kọ̀ jálẹ̀, mo sì sọ fún un pé ‘Rárá!’ Mi ò ṣe. Èyí jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, mo sì láyọ̀. Ní pàtàkì, mo mọ̀ pé, ohun tí mo ṣe mú inú Jèhófà dùn.”

Tí ìdẹwò bá dé, tó o bá dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀ lórí ohun tó o gbà gbọ́, ó dájú pé àrídunnú ọmọ ni wàá jẹ́ fún Jèhófà!—Òwe 27:11.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

\

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Bawo La Ṣe Ń Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìlànà Bíbélì?

Jésù ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà Bíbélì méjì tó ṣe pàtàkì jù.