Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  March 2014

Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe dé Orílẹ̀ èdè Sípéènì

Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe dé Orílẹ̀ èdè Sípéènì

“Nígbàkigbà tí mo bá wà ní ọ̀nà mi lọ sí Sípéènì, mo ní ìrètí . . . láti rí yín fẹ̀rẹ̀, kí ẹ sì sìn mí díẹ̀ lọ́nà ibẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá ti kọ́kọ́ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ yín dé ìwọ̀n kan.”—Róòmù 15:24.

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù ní ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. Bóyá Pọ́ọ̀lù wá rin ìrìn àjò yẹn lọ sí Sípéènì tàbí kò lọ, Bíbélì ò sọ. Síbẹ̀, akitiyan tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn Kristẹni míì tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ṣe mú kí ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì Ọrọ̀ Ọlọ́run dé orílẹ̀-èdè Sípéènì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì lẹ́yìn ikú Jésù.

Díẹ̀díẹ̀ ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹ̀sìn Kristẹni, kò sì pẹ́ tó fi gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó wá ṣe kedere pé, àwọn èèyàn náà nílò Bíbélì ní èdè Látìn, torí pé Róòmù ló ń ṣàkóso àgbègbè Sípéènì fún ọ̀pọ̀ ọdún títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kejì, èdè Látìn ni wọ́n sì ń sọ jákèjádò ilẹ̀ ọba Róòmù.

BÍBÉLÌ NÍ ÈDÈ LÁTÌN

Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni ní orílẹ̀-èdè Sípéènì tú àwọn ìwé Bíbélì kan sí èdè Látìn, àkópọ̀ àwọn ìwé yìí la mọ̀ sí Vetus Latina Hispana. Àìmọye ọdún ni wọ́n fi pín Bíbélì yìí kiri ní orílẹ̀-èdè Sípéènì kí Jerome tó parí ìtumọ̀ Bíbélì Vulgate, tó kọ ní èdè Látìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ọdún karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù.

Kò pẹ́ tí ìtumọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ilẹ̀ Palẹ́sìnì fi dé orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ìdí ni pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Lucinius rán àwọn akọ̀wé mẹ́fà sí Jerome ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà tó gbọ́ pé ó fẹ́ tú Bíbélì sí èdè Látìn. Ó ní kí wọ́n ṣe àdàkọ Bíbélì náà, kí wọ́n sì mú ẹ̀dà rẹ̀ wá fún òun ní gbàrà tí Jerome bá ti parí ìtumọ̀ rẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ùn ọdún tó tẹ̀ lé e, ìtumọ̀ Vulgate bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́pò ìtumọ̀ Vetus Latina Hispana. Àwọn Bíbélì tó wà ní èdè Látìn yìí ló jẹ́ kí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Sípéènì lè ka Bíbélì kí wọ́n sì lóye rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ilẹ̀ ọba Róòmù kógbá sílé, ó di dandan kí wọ́n tú Bíbélì sí èdè tuntun tí àwọn èèyàn ń sọ.

BÍBÉLÌ TÍ WỌ́N KỌ SÓRÍ SÍLÉÈTÌ

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún, àwọn ẹ̀yà visigoth àtàwọn ẹ̀yà míì láti ilẹ̀ Jámánì tó ń sọ èdè Gothic ṣẹ́gun ilẹ̀ Sípéènì. Bó ṣe di pé èdè Gothic gbilẹ̀ ní gbogbo agbègbè náà nìyẹn. Ẹ̀ka ẹ̀sìn Kristẹni kan tí wọ́n ń pè ní Arianism, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn Arius, ni àwọn ẹ̀yà yìí ń ṣe, ẹ̀sìn wọn sì ta ko ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan. Wọ́n mú Bíbélì tiwọn lédè Gothic wá, ìyẹn Ulfilas’ Gothic Bible. Bíbélì yìí ni wọ́n ń kà ní ilẹ̀ Sípéènì títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà. Àsìkò yìí ni Reccared ọba àwọn ẹ̀yà Visigoth di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ó sì sọ pé òun kì í ṣe ọmọlẹ́yìn Arius mọ́. Ó wá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ìwé Arius jọ, kí wọ́n sì dáná sun gbogbo rẹ̀ títí kan Bíbélì Ulfilas. Bí gbogbo Bíbélì tí wọ́n kọ ní èdè Gothic ṣe pòórá ní orílẹ̀-èdè Sípéènì nìyẹn.

Síléètì tí wọ́n kọ ẹsẹ Bíbélì sí lédè Látìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà

Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣì ń tàn kálẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì ní gbogbo àkókò yìí. Yàtọ̀ sí èdè Gothic, wọ́n ṣì ń sọ èdè Látìn jákèjádò àgbègbè Sípéènì. Èdè Látìn yìí ló bí àwọn èdè míì tí wọ́n ń pè ní Romance tí wọ́n ń sọ ní agbègbè Iberia. * Àwọn àkọsílẹ̀ kan tí ọjọ́ wọ́n ti pẹ́ tó wà ní èdè Látìn ni wọ́n máa ń pè ní Visigothic slates, ìyẹn àwọn síléètì Visigoth torí pé, orí àwọn síléètì kéékèèké ni wọ́n kọ wọ́n sí. Nǹkan  bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà sí ìkeje [501-700] ni wọ́n kọ wọ́n, lára wọn ni a ti rí ìwé Sáàmù àti àwọn ìwé Ìhìn Rere. Síléètì kan tiẹ̀ wà tí wọ́n kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù kẹrìndínlógún [16] sí.

Bí wọ́n ṣe rí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lórí àwọn síléètì tí owó rẹ̀ kò wọ́n yìí fi hàn pé àwọn èèyàn tí kò rí jájẹ pàápàá máa ń ka Bíbélì, wọ́n sì máa ń dà á kọ nígbà yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn olùkọ́ máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó wà lórí àwọn síléètì yìí kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Owó síléètì kò wọ́n rárá tá a bá fi wé iye tí wọ́n ń ta àwọn ìwé awọ tí àwọn ilé ìsìn àtijọ́ ń lò láti tẹ àwọn Bíbélì aláwọ̀ mèremère.

Apá kan lára Bíbélì aláràbarà tó ní àwòrán mèremère, èyí tó wà ní León. Lóòótọ́, Bíbélì yìí wọ́n, ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀kan lára irú àwọn Bíbélì aláwọ̀ mèremère yìí wà nínú ilé ìjọsìn San Isidoro ní León, lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ọdún 960 ni wọ́n kọ ọ́, ó sì ní ojú ìwé tí ó tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n [1028], ó gùn tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́tàdínláàádọ́ta [47], ó fẹ̀ tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34], ó sì wúwo tó kìlógíráàmù méjìdínlógún [18]. Òmíràn tí wọ́n kọ ní nǹkan bí ọdún 1020 ni Bíbélì Ripoll tó wà ní ibi ìkówèésí àwọn Póòpù ní ìlú Vatican. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Bíbélì aláràbarà tó ní àwọn àwòrán mèremère. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ẹni tó dárà sí i ṣe, torí pé ó lè lo odindi ọjọ́ kan láti kọ álífábẹ́ẹ̀tì àkọ́kọ́ nìkan, tàbí kó lo ọ̀sẹ̀ kan gbáko nídìí àkọlé ìwé náà lásán. Lóòótọ́, Bíbélì yìí níye lórí, ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

BÍBÉLÌ NÍ ÈDÈ LÁRÚBÁWÁ

Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ, èdè Lárúbáwá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì nítorí pé àwọn Mùsùlùmí ṣẹ́gun apá kan ní ilẹ̀ náà. Ní àwọn àgbègbè tí àwọn Mùsùlùmí ti ń ṣe ìjọba, èdè Lárúbáwá ni wọ́n ń sọ, èyí sì mú kí àwọn èèyàn pa èdè Látìn tì, torí náà, wọ́n nílò Bíbélì lédè Lárúbáwá.

Láti ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún sí ìkẹjọ, Bíbélì tó wà ní èdè Látìn àti Lárúbáwá ti ran àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Sípéènì lọ́wọ́ láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n kọ lédè Lárúbáwá, pàápàá àwọn ìwé Ìhìn Rere, ló tàn ká orílẹ̀-èdè Sípéènì nígbà yẹn. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ, Ọ̀gbẹ́ni John tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Seville, tú Bíbélì lódindi sí èdè Lárúbáwá. Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú  pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀dà yìí ló ti sọ nù. Ọ̀kan lára ìtumọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere ní èdè Lárúbáwá tí wọ́n kọ láàárín ọgọ́rùn ọdún kẹwàá ni wọ́n tọ́jú sínú ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan ní León, ní orílẹ̀-èdè Sípéènì.

Àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n tú sí èdè Lárúbáwá ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá

BÍBÉLÌ NÍ ÈDÈ SÍPÁNÍÌṢÌ

Ní nǹkan bí ọdún 476 AD sí 1500 AD ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè Castile tí a mọ̀ sí èdè Sípáníìṣì ní àgbègbè Iberia. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ní èdè tuntun yìí ṣe nínú títan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀. * Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tú sí èdè Sípáníìṣì fara hàn nínú ìwé kan tó ń jẹ́ La Fazienda de Ultra Mar (àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lókè òkun) tí wọ́n tẹ̀ jáde ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn 1201. Ìwé yìí sọ nípa ìrìn àjò kan tó lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ọ̀rọ̀ inú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì, àtàwọn ìwé míì nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti àwọn lẹ́tà inú Bíbélì.

Ọba Alfonso kẹwàá ṣagbátẹrù bí wọ́n ṣe tú Bíbélì sí èdè Sípáníìṣì

Inú àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì kò dùn sí ìtumọ̀ Bíbélì yìí. Ní ọdún 1234, ìgbìmọ̀ ìjọ Kátólíìkì ní Tarragona pàṣẹ pé kí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì dáná sun gbogbo Bíbélì tí kì í ṣe èdè Látìn ni wọ́n fi kọ wọ́n. Àmọ́, àṣẹ tí wọ́n pa yìí kò dá iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì dúró. Ọba Alfonso kẹwàá tó jọba láti ọdún 1252 sí ọdún 1284, sapá gan-an kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sí èdè Sípáníìṣì, kódà, àwọn èèyàn gbà pé ni olùdásílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọ èdè Sípáníìṣì lónìí. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó gbòde kan nígbà yẹn lédè Sípáníìṣì ni èyí tí wọ́n kọ kí ọba Alfonso kẹwàá tó gorí ìtẹ́, àti èyí tí wọ́n kọ lórúkọ ọba Alfonso fúnra rẹ̀ lẹ́yìn tó jọba.

(Lápá òsì) Bíbélì tí wọ́n kọ ṣáájú kí Alfonso tó gorí ìtẹ́ ní ọgọ́rùn ọdún kẹtàlá, (lápá ọ̀tún) Bíbélì Alfonso

Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì méjèèjì yìí ló jẹ́ kí èdè Sípáníìṣì dùn-ún kọ sílẹ̀ tó sì jẹ́ kó fìdí múlẹ̀ dáadáa. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Thomas Montgomery sọ nípa Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ kí ọba Alfonso kẹwàá tó jọba pé: “Àwọn atúmọ̀ Bíbélì yìí síṣẹ́ kára, wọ́n rí i dájú pé Bíbélì náà péye, wọ́n sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó bu ẹwà kún èdè yìí . . . Èdè tí wọ́n lò rọrùn láti lóye, pàápàá fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Látìn dáadáa.”

Àmọ́, kàkà kí wọ́n tú Bíbélì yìí láti inú èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, Bíbélì Vulgate tó wà lédè Látìn ni wọ́n lò láti fí ṣe ìtumọ̀ Bíbélì Sípáníìṣì yìí. Torí náà, láti nǹkan bí ọdún 1301 wá, àwọn ọ̀mọ̀wé Júù bẹ̀rẹ̀ sí í tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní tààràtà látinú èdè Hébérù. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè Sípéènì làwọn Júù pọ̀ sí jù ní ilẹ̀ Yúróòpù, bákàn náà, àwọn atúmọ̀ èdè tó jẹ́ Júù láǹfààní láti rí àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó péye tó wà lédè Hébérù fún ìtumọ̀ tí wọ́n ṣe. *

Ọ̀kan pàtàkì lára Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ni Alba Bible tí wọ́n ní ọdún 1401 sí ọdún 1500. Ọkùnrin olówó kan tó gbajúmọ̀ tó ń jẹ́ Luis de Guzmán sọ fún Moisés Arragel tó jẹ́ Rábì pé kó tú Bíbélì sí èdè castizo ìyẹn èdè Sípáníìṣì pọ́ńbélé. Ó sọ ìdí méjì tó fi ní kí ó ṣe ìtumọ̀ tuntun yìí. Ó ní: “Àwọn Bíbélì tó wà ní àwọn èdè ìbílẹ̀ kò péye rárá,” àti pé, “àwọn èèyàn bíi tèmi báyìí nílò àwọn àfikún àlàyé ká tó lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó tó wà nínú rẹ̀.” Ohun tó sọ yìí fi hàn pé àwọn èèyàn ìgbà yẹn nífẹ̀ẹ́ láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì lóye rẹ̀. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn Bíbélì tó wà ní èdè ìbílẹ̀ pọ̀ jaburata ní orílẹ̀-èdè Sípéènì láwọn ọdún yẹn.

 Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn atúmọ̀ èdè yìí àtàwọn adàwékọ, tí wọ́n jẹ́ kó rọrùn fún àwọn tó mọ̀wé ní orílẹ̀ èdè Sípéènì láti ka Bíbélì lọ́nà tó já geere. Ìdí nìyẹn tí òpìtàn Juan Orts González fi sọ pé: “Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Sípéènì mọ Bíbélì dáadáa ju àwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ ṣáájú ìgbà ayé Luther.”

“Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Sípéènì mọ Bíbélì dáadáa ju àwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ, ṣáájú ìgbà ayé Luther.”—Òpìtàn náà, Juan Orts González

Àmọ́, bí ọdún 1500 ṣe ń sún mọ́lé, ilé ẹjọ́ Kátólíìkì tó máa ń fìyà jẹ àwọn ọ̀tá pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ túmọ̀ tàbí kó ní Bíbélì kankan ní èdè ìbílẹ̀ èyíkéyìí. Bí wọ́n ṣe fòfin de Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọdún ní orílẹ̀-èdè Sípéènì nìyẹn. Ọgọ́rùn mẹ́ta ọdún sì kọjá kí wọ́n tó yí àṣẹ yẹn pa dà. Ní àwọn ọdún tí nǹkan ò rọgbọ yìí, àwọn atúmọ̀ èdè kan tó nígboyà máa ń tẹ Bíbélì ní èdè Sípáníìṣì ní ìlú míì, wọ́n á wá fọgbọ́n kó wọn wọlé sí orílẹ̀-èdè Sípéènì. *

Ìtàn nípa bí Bíbélì ṣe dé orílẹ̀-èdè Sípéènì yìí fi hàn pé àwọn ọ̀tá ti sapá gan-an láti bo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́lẹ̀. Àmọ́, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ìsapá wọn já sí torí pé, wọn ò ríbi bo Ọ̀rọ̀ Olódùmarè mọ́lẹ̀.—Sáàmù 83:1; 94:20.

Iṣẹ́ takuntakun ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣe láti mú kí Bíbélì wà, kó sì tàn kálẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì àtijọ́. Àwọn atúmọ̀ èdè yìí ṣe bẹbẹ láti tú Bíbélì sí èdè Látìn, Gothic, Lárúbáwá àti Sípáníìṣì, ẹṣin iwájú tiwọn làwọ́n atúmọ̀ èdè òde òní ń wò sáré. Ìdí nìyẹn tó fi ṣeé ṣe fún ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Sípáníìṣì lónìí láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn dáadáa.

^ ìpínrọ̀ 10 Lára wọn ni èdè ìbílẹ̀ Castile, Catalan, Galician àti èdè Potogí.

^ ìpínrọ̀ 17 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogójì mílíọ̀nù (540 million) àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Sípáníìṣì lónìí.

^ ìpínrọ̀ 20 Wo àpilẹ̀kọ náà “Orúkọ Ọlọ́run àti Ìsapá Alfonso de Zamora Láti Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Péye,” nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2011.

^ ìpínrọ̀ 23 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìjà Tí Casiodoro de Reina Jà fún Bibeli Èdè Spanish,” nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 1996.