Ẹnu máa ń ya àwọn tó bá rí mi, torí pé èèyàn ṣáńkó ni mí, mi ò wúwo ju kìlógíráàmù mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] lọ, inú kẹ̀kẹ́ arọ sì ni mo máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, bí mo tiẹ̀ jẹ́ aláìlera, okun inú ń gbé mi ró. Ẹ jẹ́ n sọ díẹ̀ nípa ìgbésí ayé mi fún yín, kí ẹ lè mọ ohun tó sọ mí di aláìlera àti bí okun inú ṣe ń gbé mi ró.

Èmi rèé lọ́mọ ọdún mẹ́rin

Inú ilé kékeré kan tó wà lápá gúúsù ilẹ̀ Faransé ni èmi àti àwọn òbí mi ń gbé. Bí mo bá rántí ìgbà kékeré mi, inú mi máa ń dùn gan-an. Bàbá mi ṣe jangirọ́fà kan fún mi, mo sì fẹ́ràn láti máa sáré kiri inú ọgbà. Lọ́dún 1966, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù dé ilé wa, wọ́n kọ́ bàbá mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́. Oṣù méje lẹ́yìn ìyẹn ni bàbá mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ rárá tí ìyá mi náà fi di ara wọn. Bí àwọn méjèèjì ṣe tọ́ mi dàgbà nínú ìdílé aláyọ̀ nìyẹn.

Àjò ò ṣáà lè dùn kí onílé má pa dà sílé, àwọn òbí mi pa dà sí orílẹ̀-èdè Sípéènì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ wọn. Kò pẹ́ tí a débẹ̀ ni àìsàn burúkú kan kọ lù mí. Ọwọ́ àti ọrùn ẹsẹ̀ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro mí kíkankíkan bíi pé ẹnì kan ń fi ọ̀bẹ gún mi níbẹ̀. Lẹ́yìn odindi ọdún méjì tá a ti ń pààrà ilé ìwòsàn, a rí dókítà kan tó mọ̀ nípa àìsàn aromọléegun. Àmọ́ nígbà tó ṣàyẹ̀wò mi, dókítà náà sọ pé “àìsàn náà kò ṣeé wò mọ́.” Bí ìyá mi ṣe bú sẹ́kún nìyẹn. Kò sí ohun tí etí mi ò gbọ́ tán lọ́jọ́ náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì nípa àìsàn náà. Wọ́n ní àìsàn “Autoimmune chronic illness,” ń ṣe mí, ìyẹn àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kí àwọn sẹ́ẹ̀lì gbógun ti ara wọn, wọ́n tún sọ pé mo ní “Juvenile polyarthritis,” * ìyẹn àìsàn oríkèé ara ríro tó lé kenkà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ nígbà náà, mo mọ̀ pé ìròyìn burúkú ni àwọn àrùn tí wọ́n dárúkọ yìí jẹ́ fún mi.

Dókítà náà wá sọ́ pé kí wọ́n gbé mi lọ sí ilé ìtọ́jú tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kọ́ fún àwọn ọmọdé tó ní àìsàn bíi tèmi. Gbàrà tí mo dé ilé náà, tí mo sì rí bí gbogbo ẹ̀ ṣe rí ni mo ti mọ̀ pé ibẹ̀ kò tuni lára. Wọ́n ti le mọ́ wa jù. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ti gé irun mi, wọ́n sì gbé aṣọ wúruwùru kan wọ̀ mí. Ọkàn mi gbọgbẹ́, omijé sì bọ́ lọ́jú mi. Ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í káàánú ara mi pé ìgbésí á nira fún mi níbí yìí.

BÍ JÈHÓFÀ ṢE RÀN MÍ LỌ́WỌ́

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí àwọn òbí mi ti kọ́ mi ni kò jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí ààtò ìsìn Kátólíìkì ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé tí mo wà. Ṣùgbọ́n, ìdí tí mi ò fí lọ́wọ́ sí àwọn ààtò ìsìn wọn kò yé àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Torí náà, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ṣáà má fi mí sílẹ̀, kò sì pẹ́  tí mo fi ri ọwọ́ ààbò rẹ̀ lára mi, ńṣe ló dà bí ìgbà tí baba kan tó nífẹ̀ẹ́ gbá ọmọ rẹ̀ mọ́ra lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.

Ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni wọ́n fún àwọn òbí mi láti bẹ̀ mí wò ní àwọn ọjọ́ Sátidé, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì máa ń mú wá fún mi jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, wọn kò gbà wá láyè láti dá ní ìwé ti ara wa, síbẹ̀, wọ́n jẹ́ kí n tọ́jú àwọn ìwé wọ̀nyí àti Bíbélì tí mo máa ń kà lójoojúmọ́. Mo tún máa ń sọ̀rọ̀ Bíbélì fún àwọn ọmọbìnrin tá a jọ wà níbẹ̀. Mo jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò ní sí àìsàn mọ́ nínú Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Ìṣípayá 21:3, 4) Lóòótọ́, bí mo ṣe máa ń dá wà lọ́pọ̀ ìgbà máa ń bà mí nínú jẹ́, síbẹ̀, mó máa ń láyọ̀ pé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Jèhófà túbọ̀ ń lágbára sí i.

Lẹ́yìn tí mo lo oṣù mẹ́fà gbáko nílé ìwòsàn, àwọn dókítà ní kí n máa lọ sílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe mí kò tíì sàn, inú mi dùn pé mo pa dà sílé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, gbogbo ara mi ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, mi ò sì lókun rárá nítorí pé àwọn oríkèé ara mi ti wọ́, ìrora tí àìsàn náà ń fà sì tún peléke sí i. Síbẹ̀, mo pinnu láti máa jọ́sìn baba mi ọ̀run dé ìwọ̀n àyè tí agbára mi bá lè gbe é dé, torí náà mo ṣe ìrìbọmi nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14]. Ká sòótọ́, ní ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń ṣe mí bíi pé Ọlọ́run ti já mi kulẹ̀. Tí mo bá sì ń gbàdúrà, ńṣe ni mo máa ń bíi pé: “Kí ni mo ṣe tí irú èyí fi tọ́ sí mi? Oò sì jọ̀ọ́ wò mí sàn. Àbí ṣé o kò ríi pé ìyà yìí tí pọ̀ jù ni?”

Ìgbà ọ̀dọ́ nira fún mi gan-an. Bí nǹkan ṣe ń lọ jẹ́ kí n gbà pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí màá ṣe bá kú nìyí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wù mí kí ara tèmi náà le bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ mi tí ara wọn dá ṣáṣá, àmọ́ àìsàn yìí ò jẹ́. Ìrònú wá sọ mí di onítìjú, mo sì ka ara mi sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n, àwọn èèyàn mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi dúró tì mí gbágbáágbá. Inú mi máa ń dùn tí mo bá rántí Arábìnrin Alicia. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ogún ọdún ló fi jù mí lọ, ọ̀rẹ́ mi àtàtà ni. Ó máa ń gbé ọkàn mi kúrò lórí àìlera mi, á sì rọ̀ mí láti pọkàn pọ̀ sórí bí mo ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Èyí ni kì í jẹ́ kí n máa ro àròkàn.

MO LO AYÉ MI LỌ́NÀ TÓ NÍ LÁÁRÍ

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], àìsàn tó ń ṣe mí le débi pé ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́. Kódà, àtilọ sí ilé ìjọsìn dogun fún mi, ńṣe ló máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Ṣùgbọ́n mi ò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, gbogbo “àkókò tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀” ni mo máa ń fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa. Ìwé Jóòbù àti Sáàmù tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí Sátánì sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn sì ni ààbò tó ṣe pàtàkì jù ní báyìí. Torí náà, ó lè máà jẹ́ gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run á gbà wá lọ́wọ́ ìpalára, àmọ́ Jèhófà máa ń fi ìrètí àti àwọn ìránnilétí tí a nílò tù wá nínú tá a bá wà nínú ìṣòro. Mo máa ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà, ìyẹn ló ń fún mi ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” àti “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:6, 7.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlélógún [22], tí mo sì rí ibi tí àìsàn mi le dé, mo gbà pé orí kẹ̀kẹ́ arọ ni màá ti lo ìyókù ìgbésí ayé mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé ojú aláìsàn ni àwọn èèyàn á máa fi wò mí. Àmọ́, kì í ṣe bí mo ṣe rò ló rí, torí pé ńṣe ni kẹ̀kẹ́ arọ náà jẹ́ kí n ní òmìnira láti ṣe ohun tí mo fẹ́, ó sì jẹ́ kí ohun tó dà bí òkè ìṣòro di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi kan tó ń jẹ́ Isabel tiẹ̀ dábàá pé kí èmi àti òun jọ máa wàásù fún ọgọ́ta [60] wákàtí lóṣooṣù.

Nígbà tó mú àbá yẹn wá, mo kọ́kọ́ wò ó pé, ṣé ó lóye ohun tó sọ ṣá? Àmọ́, àwọn èèyàn mi gbárùkù tì mí, èmi náà sì bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Níkẹyìn, Ọlọ́run fún mi ṣe. Iṣẹ́ ńlá ni mo ṣe lóṣù yẹn, àmọ́ kò pẹ́ tí gbogbo iṣẹ́ náà fi parí, tí gbogbo ohun tó ń já mi láyà, tó sì ń tì mí lójú fi di ìgbàgbé. Mo gbádùn oṣù yẹn gan-an débi pé lọ́dún 1996, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó ń lo àádọ́rùn-ún [90] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù. Ọ̀kan lára ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe nìyẹn, torí ó jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì tún fún mi lókun tí mo nílò. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ti fún mi láǹfààní láti sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn, tí àwọn náà sì wá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

JÈHÓFÀ GBÉ MI RÓ

Ní ìparí ọdún 2001, ìjàǹbá mọ́tò ṣẹlẹ̀ sí mi, bí ẹsẹ̀ mi méjèèjì ṣe tún kán nìyẹn. Inú ìroragógó ni mo wà lórí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n tẹ́ mi sí ní ilé ìwòsàn, síbẹ̀ mò ń fi ọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì ń sọ pé: “Jèhófà, jọ̀wọ́ má ṣe fi mí sílẹ̀!” Àkókò yẹn ni obìnrin tó wà lórí bẹ́ẹ̀dì lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi béèrè pé ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mo kàn mi orí pé bẹ́ẹ̀ ni torí pé àárẹ̀ tó mú mi kò jẹ́ kí n lè sọ̀rọ̀. Obìnrin náà sọ pé: “Mo mọ̀ yín dáadáa, mo sì máa ń ka àwọn ìwé yín déédéé.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn tù mí nínú gan-an. Bí mo tiẹ̀ ń kú lọ, mo ṣì láǹfààní láti wàásù nípa Jèhófà. Àbí ẹ ò ríi pé àǹfààní ńlá nìyẹn!

 Nígbà tí ara tù mí díẹ̀, mo pinnu láti tún wàásù fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i. Màmá mi ló máa ń yí mi kiri inú wọ́ọ̀dù lórí kẹ̀kẹ́ arọ kí n lè wàásù fún àwọn aláìsàn. Ìwọ̀nba díẹ̀ náà ni àwọn tá a lè bá sọ̀rọ̀. Tí a bá ti dé ọ̀dọ̀ wọn, àá béèrè bí ara wọn ṣe le sí, àá sì fún wọn ní ìwé ìròyìn wa. Kò rọrùn rárá, tí mo bá fi máa wàásù láti wọ́ọ̀dù kan sí òmíràn, á ti rẹ̀ mí gan-an, ṣùgbọ́n Jèhófà ń fún mi lókun tí mo nílò.

Èmi àti àwọn òbí mí rèé lọ́dún 2003

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìrora mi túbọ̀ ń peléke sí i, ikú bàbá mi sì tún dá kún ìbànújẹ́ mi. Síbẹ̀, mi ò bara jẹ́ jù, mo gbà pé nǹkan á ṣì dáa. Ọgbọ́n tí mo máa ń dá ni pé, mo máa ń lọ bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ mi ṣeré, èyí ni kì í jẹ́ kí ìdààmú ọkàn bò mí mọ́lẹ̀. Ní àwọn ìgbà tí mo bá sì dá wà, mo máa ń ka Bíbélì tàbí kí n kẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí ń máa wàásù fún àwọn èèyàn lórí fóònù.

Lọ́pọ̀ ìgbà màá kàn dijú, màá sì ṣe bíi pé mo ti wà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí

Mo tún máa ń gbìyànjú láti gbádùn ara mi. Mo máa ń lọ gbatẹ́gùn níta tàbí kí n lọ gbóòórùn àwọn òdòdó tó yí mi ká. Èyí lè dà bí àwọn nǹkan kéékèèké, àmọ́ ó máa ń jẹ́ kí n ronú lórí àwọn nǹkan tó yẹ kí n máa dúpẹ́ fún, kí n sì máa da ara mi lára yá. Lọ́jọ́ kan tí mo wà lóde ẹ̀rí, ṣàdédé ni ọ̀rẹ́ mi tá a jọ ṣiṣẹ́ dúró pé kí òun kọ nǹkan sínú ìwé. Àṣé, ó ti gbàgbé pé òun ti fi kẹ̀kẹ́ náà sílẹ̀. Bí kẹ̀kẹ́ náà ṣe ń da fíríì lọ geerege nìyẹn, títí mo fi lọ sẹrí mọ́ ọkọ̀ kan níbi tí wọ́n gbe é sí. Àyà wa kọ́kọ́ já, àmọ́ nígbà tó rí i pé mi ò fara pa, bí àwa méjèèjì ṣe bú sẹ́rìn nìyẹn.

Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó wù mí àmọ́ tí mi ò lè ṣe nísinsìnyí, mo máa ń pe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ní àwọn ohun tí màá ṣe lọ́jọ́ iwájú. Lọ́pọ̀ ìgbà, màá kàn dijú, màá sì ṣe bíi pé mo ti wà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pétérù 3:13) Màá máa wò ara mi bí ẹni tí ara ẹ̀ ti le, tó ń gbádùn ara ẹ̀, tó sì ń fò kiri. Mo máa ń fi ọ̀rọ̀ Dáfídì Ọba sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára.” (Sáàmù 27:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara mi ò gbé kánkán mọ́, síbẹ̀ Jèhófà ti sọ mí di alágbára. Mo sì ń bá a lọ láti máa rí okun láìka àìlera tó ń bá mi fínra sí.

^ ìpínrọ̀ 6 Juvenile polyarthritis jẹ́ àìsàn aromọléegun burúkú kan tó máa ń ṣe àwọn ọmọdé. Tí àìsàn yìí bá ti wọlé sí àgọ́ ara, ńṣe ni àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn nínú ara á bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn iṣan ara jẹ́. Èyí máa ń fa ìrora tó bùáyà, tí oríkèé ara á sì máa wú.