Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ti ń gbé ní àlàáfíà tẹ́lẹ̀, fi ẹbí, ará àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì kọrí sójú ogun. Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè tó ń jó lala lọ́kàn wọn ló mú kí wọ́n lọ jagun náà. Ọ̀gbẹ́ni kan tó lọ jà fún orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lójú ogun náà lọ́dún 1914 sọ pé: “Inú mi ń dùn ṣìnkìn láti lọ, torí mo mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”

Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ rárá tí gbogbo àwọn arógunyọ̀ náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í sun ẹkún kíkorò torí kò sẹ́ni tó mọ̀ pé àwọn sójà náà máa bá ara wọn jà fún ọ̀pọ̀ ọdún ní ilẹ̀ Belgium àti ní orílẹ̀ èdè Faransé. Ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi pe ogun náà ní “Ogun Ńlá.” Ogun yìí la wá mọ̀ sí Ogun Àgbáyé Kìíní lónìí.

Ogun Àgbáyé Kìíní mi gbogbo ayé tìtì torí pé ẹ̀mí tó ṣòfò níbẹ̀ kò lóǹkà. Àwọn kan tiẹ̀ fojú bù ú pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá [10,000,000] èèyàn ni ogun náà pa, ó sì sọ nǹkan bíi mílíọ̀nù lọ́nà ogún [20,000,000] èèyàn di aláàbọ̀ ara. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yíwọ́ nígbà náà débi pé apá àwọn olóṣèlú Ilẹ̀ Yúróòpù kò ká rògbòdìyàn tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bá ara wọn fà. Kí wọn sì tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, wàhálà náà ti di ogun tó kárí ayé. Èyí tó tiẹ̀ burú jù ni pé, “Ogun Ńlá” náà ti ba ayé yìí jẹ́ kọjá ààlà. Ká sòótọ́, ogun yìí ló sọ ayé di bó ṣe rí lónìí, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ kò sì tíì kúrò lára aráyé títí di bá a ṣe ń sọ yìí.

 ÀWỌN ÀṢÌṢE TÍ KÒ JẸ́ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN FỌKÀN TÁN ÀWỌN OLÓRÍ

Àwọn àṣìṣe kan ló fa Ogun Àgbáyé Kìíní. Ìwé The Fall of the Dynasties—The Collapse of the Old Order 1905-1922 sọ nípa àwọn olórí nílẹ̀ Yúróòpù pé: “Wọ́n dà bí ẹni tó ń ṣèrànrán, tí kò sì mọ̀ nípa àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí wọn lásìkò tí gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́ lọ́dún 1914.” Ìyẹn ni pé, wọn ò fura pé àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe lè yọrí sí àjálù ńlá tó máa kan gbogbo ayé.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ẹnì kan pa ọmọ ọba ilẹ̀ Austria, èyí sì mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tó lágbára nílẹ̀ Yúróòpù kọjú ìjà sí ara wọn ní ọ̀sẹ̀ bí mélòó kan lẹ́yìn náà. Bí ogun tí wọn ò fẹ́ jà tẹ́lẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ olórí orílẹ̀-èdè Jámánì pé: “Kí ló fa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?” Ìbànújẹ́ ló fi dáhùn pé: “Áà! Kò sẹ́ni tó yé o.”

Àwọn olórí ìṣèlú tó ṣe ìpinnu tó yọrí sí ogun náà kò mọ̀ pé ìbẹ̀rẹ̀ ogun ni èèyàn ń mọ̀, kò sí ẹni tó mọ bí òpin rẹ̀ á ṣe rí. Ìgbà tí àwọn sójà dé ojú ogun tán ni wọ́n tó mọ̀ ohun tí wọ́n ki ọrùn bọ̀. Wọ́n wá rí i pé ogun ò rí bí wọ́n ṣe rò àti pé àwọn olórí ìṣèlú àtàwọn aṣáájú ìsìn ti já wọn kulẹ̀, wọ́n sì ti tan wọ́n jẹ, kódà, àwọn ọ̀gágun pàápàá ti dalẹ̀ wọn. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀?

Àwọn olórí ìṣèlú àti àwọn aṣáájú ìsìn ti já wọn kulẹ̀, wọ́n ti tàn wọ̀n jẹ, kódà, àwọn ọ̀gágun pàápàá ti dalẹ̀ wọn

Àwọn olórí ìṣèlú ṣèlérí pé ogun náà á jẹ́ kí ayé dáa àti pé, nǹkan á túbọ̀ dẹrùn fún àwọn aráàlú. Olórí Ìjọba ilẹ̀ Jámánì tiẹ̀ sọ pé: “À ń jà ká lè gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa, fún ogún tí àwọn baba ńlá wa fi sílẹ̀ àti fún ọjọ́ ọ̀la wa.” Woodrow Wilson, tó jẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sábà máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó gbòde kan nígbà yẹn láti fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀, ohun tó sọ ni pé ogun yẹn máa jẹ́ kí “ayé dẹrùn fún Ìjọba tiwa-n-tiwa.” Kódà, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn èèyàn máa ń sọ pé, ogun yẹn ni “yóò fòpin sí àwọn ogun yòókù.” Àmọ́, èrò wọn kò tọ̀nà.

Àwọn aṣáájú ìsìn fi ìtara kọ́wọ́ ti ogun yìí. Ìwé The Columbia History of the World sọ pé: “Àwọn aṣáájú ìsìn ló jẹ́ òléwájú nínú ogun náà. Torí náà, ogun yẹn délé dóko, bí ìkórìíra àti ẹ̀tanú ṣe gbòde kan nìyẹn.” Dípò kí àwọn aṣáájú ìsìn máa wá bí wọ́n á ṣe paná ìkórìíra tó gbilẹ̀, àwọn gan-an ló tún ń rúná sí i. Ìwé kan tí wọ́n pè ní A History of Christianity sọ pé: “Kò rọrùn fún àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti fi ìgbàgbọ́ Kristẹni ṣíwájú orílẹ̀-èdè wọn, wọn kò sì múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nàkọnà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn yan ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ, wọ́n sì sọ ìsìn Kristẹni àti ìfẹ́ orílẹ̀ èdè wọn di ọ̀kan-náà. Wọ́n gba àwọn sójà láti inú gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì níyànjú láti pa ara wọn lẹ́nì kínní kejì ní orúkọ Olùgbàlà wọn.”

Àwọn ọ̀gágun wọn pàápàá fi dá wọn lójú pé kò ní pẹ́ rárá tí wọ́n á fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá, àmọ́ ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Kí wọ́n tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, gbogbo nǹkan ti dà rú, ìjà yẹn sì le débi pé kò sẹ́ni tó borí nínú ogun àjàkú akáta náà. Òpìtàn kan ṣàpèjúwe ohun tí ojú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn sójà náà rí lójú ogun, ó pè é ní “ìwà ìkà tó rorò àti ìpakúpa tó tíì gbòòrò jù lọ tí ẹ̀dá èèyàn fara dà.” Bí ọwọ́ ìjà náà ṣe ń le sí i, ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí yíwọ́. Síbẹ̀, ńṣe ni àwọn ọ̀gágun tún rán àwọn ọmọ ogun pé kí wọ́n lọ kojú àwọn ọ̀tá tó ń fi ìbọn rọ̀jò ọta lè wọn lórí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń rápálá gba ara ògiri àti àwọn odi tí wọ́n fi wáyà ẹlẹ́gùn-ún wé yíká. Ká sòótọ́, ojú ogun náà le. Ìdí nìyẹn ti ọ̀pọ̀ àwọn sójà fi yarí, tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọ̀gá wọn.

Kí ni ogun àgbáyé kinní sọ ayé yìí dà? Ọ̀gbẹ́ni kan sọ pé: “Ogun yẹn ti sọ ìrònú àti ìwà àwọn èèyàn di ìdàkudà.” Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tó wà tẹ́lẹ̀ ni ogun náà sọ dì ìtàn tí a ò sì mọ̀ wọ́n mọ́ rárá. Ohun míì tún ni pé, ogun yẹn jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpakúpa tó bùáyà, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn ọdún tí wọ́n ti pa èèyàn jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé. Látìgbà náà ni rògbòdìyàn oríṣiríṣi, irú bíi ìfipá gba ìjọba, ìdaṣẹ́ sílẹ̀ tàbí ìwọ́de lónírúurú ti gbòde kan.

Kí ló fà á tí ogun yìí fi sọ ayé dìdàkudà? Àbí ṣé ogun náà kàn jẹ́ àjálù ńlá lásán ni? Kí ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí fi han nípa ọjọ́ ọ̀la?