• ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: LATVIA

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÒ Ń FI ALÙPÙPÙ DÍJE LỌ́NÀ TÓ LÉWU

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Riga tó jẹ́ olú ìlú Latvia ni wọ́n bí mi sí. Màmá mi nìkan ló tọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kátólíìkì ni màmá mi, síbẹ̀ ọjọ́ ọdún nìkan la máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Láti kékeré ni mo ti gbà gbọ́ pé ẹnì kan wà tó lágbára ju ẹ̀dá lọ, àmọ́, oríṣiríṣi nǹkan ló gbà mí lọ́kàn nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́.

Bí mo ṣe ń dàgbà, màmá mi ríi pé mo fẹ́ràn kí n máa tú nǹkan palẹ̀, kí n sì tò wọ́n pa dà. Ìdí nìyí tí màmá mi kì í fẹ́ fi èmi nìkan sílẹ̀ nílé, torí pé kí wọ́n tó dé, màá ti tú gbogbo nǹkan tó wà nílé palẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ni màmá mi bá ra ohun ìṣeré kan fún mi tó ṣe é tò pọ̀, tó sì ṣe é tú palẹ̀. Mó fẹ́ràn kí n máa to ohun ìṣeré yẹn pọ̀ kó lè dà bí mọ́tò tàbí irú ọkọ̀ míì. Yàtọ̀ sí pé mo nífẹ̀ẹ́ láti máa tú nǹkan palẹ̀, mo tún fẹ́ràn láti máa gun alùpùpù kiri. Ìdí nìyẹn tí màmá mi fi forúkọ mi sílẹ̀ ní Zelta Mopēds, ìyẹn ibi ìdíje kan tí wọ́n ti máa ń fi alùpùpù sáré àsápajúdé. Alùpùpù kékeré ni mo fi bẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, mó bẹ̀rẹ̀ sí í gun alùpùpù ńlá.

Nǹkan tètè yé mi gan an, kò sì pẹ́ tí mo di gbajúmọ̀ nínú eré tó léwu yẹn. Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo gba ipò kìíní nínú ìdíje àwọn tó ń fi alùpùpù sáré ní ìlú Latvia. Mo sì tún gba ipò kìíní nínú ìdíje ti Baltic States ní ẹ̀ẹ̀mejì.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Lákòókò tí òkìkí mi bẹ̀rẹ̀ sí í kàn nínu iṣẹ́ tí mo fẹ́ràn yìí, ọmọbìnrin kan tí mò ń fẹ́ sọ́nà tó ń jẹ́ Evija, tí mo pa dà fi ṣe aya, pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣáájú ìgbà yẹn, ó rí ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣàlàyé Bíbélì, tí ó ní fọ́ọ̀mù tí èèyàn fi ń kọ̀wé béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù náà, o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó wà níbẹ̀. Kò pẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, mo fara mọ́ bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀, èmi ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ìsìn nígbà yẹn.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn sọ pé kí èmi náà jókòó kí n sì máa fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun kan tí mo gbọ́ tó dùn mọ́ mi, tó  sì wọ̀ mí lọ́kàn jù, ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi ohun tó wà nínú Sáàmù 37:10, 11 hàn mí, tó sọ pé: “Nítorí pé àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, Ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; Dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ìlérí yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.

Díẹ̀díẹ̀ ló túbọ̀ ń wù mí láti mọ Bíbélì sí i. Mo wá rí i pé onírúurú irọ́ ni ìsìn fi ń kọ́ni. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ láti inú Bíbélì wú mi lórí gan-an, wọ́n tuni lára, wọn ò sì lọ́jú pọ̀.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ jẹ́ ki ń mọ bí ẹ̀mí ṣe ṣeyebíye tó lójú Jèhófà, àti bó ṣe kà á sí pàtàkì tó. (Sáàmù 36:9) Ohun tí mo kọ́ yìí mú kí n ronú nípa bí mo ṣe ń fi alùpùpù díje, mi ò sì fẹ́ fi ẹ̀mí ara mi wewu mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fẹ́ fi ayé mi ṣe ohun tó máa mú inú Ọlọ́run dùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí mo ṣe máa ń fi alùpùpù dárà àti bí àwọn èèyàn ṣe ń kan sáárá sí mi ti sọ mí di gbajúmọ̀, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ kò jẹ́ kí àwọn nǹkan yẹn jọ mí lójú mọ́.

Mó ti wá mọ̀ pé mo ní ojúṣe kan tó yẹ kí n ṣe fún Olùfúnni ní ìyè

Ní ọdún 1996, mo lọ sí ìpàdé àgbáyé kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní ìlú Tallinn, ní orílẹ̀ èdè Estonia. Ibẹ̀ kò jìnnà sí pápá ìṣeré tí mo tí fi alùpùpù dá bírà láìmọye ìgbà sẹ́yìn. Ní àpéjọ yẹn, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n wá láti onírúurú orílẹ̀ èdè, tí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan àti àlàáfíà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ yẹn, obìnrin kan sọ pọ́ọ̀sì rẹ̀ nù, mo ti rò pé kò lè rí i mọ́ láé, àmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé arábìnrin kan rí pọ́ọ̀sì náà, ó sì dá a pa dà láìsí ohunkóhun tó sọnù nínú rẹ̀! Ìgbà yẹn ló wá yé mi pé, lóòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò. Èmi àti Evija tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, nígbà tó di ọdún 1997, à ṣe ìrìbọmi, a sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n ti kú nítorí ìwà ẹhànnà àti eré egéle tí wọ́n fi gbogbo ìgbésí ayé wọn ṣe níbi tí wọ́n ti ń fi alùpùpù sáré ìdíje. Bóyá èmi gan ì bá ti kú, àmọ́, mo dúpẹ́ pé mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí mo ti wá mọ̀ pé mo ní ojúṣe kan tó yẹ kí n ṣe fún Jèhófà, tó jẹ́ Olùfúnni ní ìyè.

Ọdún mẹ́rin ni èmi àti Evija fi ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tó ń lo àkókò tó pọ̀ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Riga. Ní báyìí, inú wa ń dùn bí a ṣe ń tọ́ Alise ọmọbìnrin wa, tí a sì ń kọ́ ọ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Mo tún láǹfààní láti máa fi ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtumọ̀ èdè, mo máa ń bá wọn tún mọ́tò àtàwọn nǹkan míì tó bá bàjẹ́ níbẹ̀ ṣe. Inú mi máa ń dùn gan-an pé ohun tí mo fẹ́ràn láti máa ṣe ní kékeré ni mo tún wá ń ṣe nígbà tí mo dàgbà. Àbí ẹ̀ rí nǹkan, mo ṣì máa ń tú nǹkan palẹ̀, tí màá sì tún tò ó pọ̀ pa dà!

Mo mọyì àǹfààní tí mo ní láti máa wàásù nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé mi, àwọn nǹkan tí mo kọ́ láti inú Bíbélì ló sì ran mí lọ́wọ́. Ní tòótọ́, ìlérí Párádísè ló yí ìgbésí ayé mi pa dà!