Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  January 2014

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni wọ́n ṣe ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn nínú tẹ́ńpìlì nígbà ayé Jésù?

Inú Àgbàlá Àwọn Obìnrin ni àwọn àpótí ti wọ́n máa ń fi ọrẹ sí wà nínú tẹ́ńpìlì. Ìwé kan tí wọ́n pè ní The Temple—Its Ministry and Services sọ pé: “Àwọn àpótí mẹ́tàlá wà tí wọ́n gbé sẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri níbi àwọn ìloro tí ó yí tẹ́ńpìlì ká, wọ́n tún máa ń pe àwọn àpótí yìí ní ‘kàkàkí,’ inú rẹ̀ ni wọ́n máa ń fi ọrẹ sí.”

Ìdí tí wọ́n fi ń pe àwọn àpótí yìí ní kàkàkí ni pé, ọrùn rẹ̀ rí tóóró, ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì fẹ̀. Wọ́n kọ irú ọrẹ tí àpótí kọ̀ọ̀kan wà fún sára rẹ̀, owó tí wọ́n bá sì kó nínú àwọn àpótí yẹn ti ní ohun pàtó ti wọ́n máa lò ó fún. Inú Àgbàlá Àwọn Obìnrin ni Jésù wà, nígbà tó kíyèsí bí opó aláìní kan, àtàwọn èèyàn míì ṣé ń fi ọrẹ sínú àpótí.—Lúùkù 21:1, 2.

Àpótí méjì àkọ́kọ́ ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún owó orí tẹ́ńpìlì, ìyẹn owó orí ti ọdún yẹn àti ti ọdún tó kọjá. Iye owó tó bá ohun tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ dọ́gba ni wọ́n máa ń sọ sínú àpótí kẹta sí ìkeje, ìyẹn owó oriri, ẹyẹlé, igi, tùràrí àti ti àwọn ohun èlò wúrà. Tí ẹni tó fẹ́ rúbọ bá mu ju iye owó ohun tó fẹ́ rà dání, ó máa sọ owó tó bá ṣẹ́ kù sínú ọ̀kan lára àwọn àpótí ọrẹ yòókù. Àpótí kẹjọ wà fún owó tó ṣẹ́ kù fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Àpótí kẹsàn án sí ìkejìlá sì wà fún owó tó ṣẹ́ kù fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, ti ẹyẹ tí wọ́n bá fi rúbọ, ọrẹ ẹbọ àwọn Násírì, àti ọrẹ ẹbọ fáwọn adẹ́tẹ̀. Àpótí kẹtàlá sì wà fún ọrẹ àtinúwá.

Ṣé òpìtàn tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye ni Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì?

Lúùkù ló kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù àti ìwé Ìṣe àwọn Àpọ́sítélì nínú Bíbélì. Lúùkù sọ pé òun “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye,” àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé kan ò gbà pé àkọsílẹ̀ rẹ̀ péye. (Lúùkù 1:3) Ṣé àkọsílẹ̀ tí Lúùkù ṣe péye lóòótọ́?

Àwọn ohun tí Lúùkù fà yọ nínú ìtàn tó sì kọ jóòótọ́ tó ṣe é jẹ́rìí sí. Bí àpẹẹrẹ, ó dárúkọ oyè tí àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa èyí ti àwọn aláṣẹ ìjọba Róòmù ní. Lára wọn ni àwọn agbófinró ìlú tó wà ní Fílípì, ó tún sọ nípa àwọn olùṣàkóso ìlú ńlá tàbí àwọn alákòóso agbègbè ní Tẹsalóníkà àti àwọn ọkùnrin tó ń mú ipò iwájú ní Éfésù. (Ìṣe 16:20, Kingdom Interlinear; 17:6; 19:31) Bákan náà, Lúùkù pe Hẹ́rọ́dù Áńtípà ní olùṣàkóso àgbègbè, ó sì tún pe Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ní alákòóso ìbílẹ̀ ti Kípírù.—Ìṣe 13:1, 7.

Bí Lúùkù ṣe lo àwọn orúkọ oyè lọ́nà tí ó tọ́, yẹ fún àfiyèsí torí pé, bí àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ tàwọn ará Róòmù ṣe ń yí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni oyè àwọn alákòóso rẹ̀ ń yí pa dà. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Bruce Metzger tó jẹ́ onímọ̀ nípa Bíbélì sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun tí Lúùkù tọ́ka sí nínú ìwé Ìṣe máa ń bá àwọn ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé àti àkókò tó ṣẹlẹ̀ mu. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ William Ramsay sọ pé: “Nínú gbogbo àwọn tó ń kọ ìtàn, ògbóǹkangí tó gba iwájú ni Lúùkù.”