• ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1922

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: SÍPÉÈNÌ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: KATIKÍÌSÌ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìpínlẹ̀ Bilbao tó wà lápá àríwá ilẹ̀ Sípéènì ni wọ́n bí mi sí, mẹ̀kúnnù sì ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní àdúgbò yẹn. Èmi ni ọmọ kejì nínú àwa mẹ́rin tí àwọn òbí mi bí. Kátólíìkì paraku ni wá nínú ìdílé wa. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń lọ sí ibi ààtò gbígba ara Olúwa, ìyẹn Máàsì. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23], mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́, ìyẹn sì ni iṣẹ́ tí mo yàn láàyò jùlọ, ogójì [40] ọdún ni mo sì fi ṣe iṣẹ́ yìí. Nínú gbogbo iṣẹ́ tí mò ń kọ́ àwọn ọmọ níléèwé, ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì ni inú mi máa ń dùn láti kọ́ wọ́n. Torí pé mo tún jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ ìsìn, ìyẹn katikíìsì, mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ láti kọ́ àwọn ọmọbìnrin bi wọn ṣe máa jẹ ara Olúwa fún ìgbà àkọ́kọ́.

Ọdún méjìlá lẹ́yìn ìgbéyàwó mi, ọkọ mi kú, èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nìkan ló wá kù. Bí mo ṣe di opó lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] nìyẹn. Mo rò pé màá rí ìtùnú nínú ìsìn Kátólíìkì tí mo gbájú mọ́, àmọ́ ńṣe ni ọ̀pọ̀ nǹkan túbọ̀ ń rú mi lójú. Mo máa ń bi ara mi pé: ‘Ṣebí Kristi ti rà wá padà, kí ló wá dé tí àwa èèyàn fí ń kú? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni gbogbo èèyàn rere ń lọ sọ́run, kí nìdí tá a ṣì fi ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé?’ Èyí tó tiẹ̀ máa ń ṣe mí ní kàyéfì jù ni pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run máa ń dá wa lẹ́jọ́ nígbà tá a bá kú, kí nìdí tá a tún fi máa kúrò ní ọ̀run, pọ́gátórì tàbí ọ̀run àpáàdì fún ìdájọ́ ìkẹyìn?’

Èyí ló mú kí n lọ bá àwọn àlùfáà, mo wá bi wọ́n ní àwọn ìbéèrè yìí, ọ̀kan nínú wọn sọ fún mi pé: “Èmi ò mọ̀ o. Lọ béèrè lọ́wọ́ bíṣọ́ọ̀bù. Kí ló dé tí àwọn ìbéèrè yìí fi ṣe pàtàkì sí ẹ tó yìí? Ṣe bí o gba Ọlọ́run gbọ́, àbí? Ìyẹn náà tí tó, èwo ni àbùrọ̀ máa wá fì-ín-ìn ìdí kókò!” Síbẹ̀, ó ṣì wù mí kí n mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí. Nígbà tó yá, mo máa ń lọ gbọ́ ìwàásù àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit, àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì-Gba-Jésù àti tàwọn Onímọ̀-Awo. Síbẹ̀, mi ò rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè mi.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Mo ti lé ní ọgọ́ta ọdún nígbà tí ọmọ ọdún méje kan ní ilé ẹ̀kọ́ mi sọ pé kí n wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ohun tí mo rí àti ohun tí mo gbọ́ níbẹ̀ dùn mọ́ mi gan-an. Àmọ́, torí pé ọwọ́ mi sábà máa ń dí, mi ò láǹfààní láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíròrò mọ́ nígbà yẹn. Ọdún méjì lẹ́yìn náà ni tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Juan àti Maite wàásù dé ilé mi. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti wá ni mo máa ń da ìbéèrè bò wọ́n, wọ́n sì máa ń dáhùn gbogbo rẹ̀. Oṣù mẹ́ta  gbáko la fi ṣe èyí, nígbà tó yá ìjíròrò wa di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo gbádùn àwọn ìjíròrò wa débi pé ara mi máa ń wà lọ́nà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo máa ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ mi fínnífínní, kódà, oríṣi ìtumọ̀ Bíbélì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ń lò, kí ń lè rí i dájú pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ mi. Kò pẹ́ tó fi yé mi pé ẹ̀sìn ti kó mi ṣìnà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ńṣe ni ìrònú bá mi nígbà ti mo rí ìyàtọ̀ ńlá tó wà láàárín ohun tí mo gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ àti ohun tí mò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ látinú Bíbélì. Mo rí i pé mo ní láti yí àwọn ohun tó mo gbà gbọ́ tẹ́ lẹ̀ pa dà, bí ìgbà tí èèyàn hú igi tó ti fìdí múlẹ̀ ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò.

Mo mọ̀ pé mo ti ri ìṣúra kan

Nígbà tó yá, ọkọ kejì tí mo fẹ́ tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, ó sì kú. Àsìkò yẹn náà ni mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, tí mo sì kúrò ní Bilbao fún ìgbà díẹ̀. Juan and Maite tó ń kọ́ mí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà kúrò lágbègbè yìí. Bí mo ṣe dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi dúró nìyẹn. Ṣùgbọ́n, nínú ọkàn mi lọ́hùn ún, mo mọ̀ pé mo ti ri ìṣúra kan. Mi ò sì lè gbàgbé láé.

Lẹ́yìn ogún ọdún, Juan àti Maite padà sí ìlú Bilbao wọ́n sì ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi. Nígbà yẹn, mo tí di ẹni ọgọ́rin ọdún ó lé méjì [82]. Inú mi dùn gan-an pé ojú túnra rí! Mo wá rí i pé Jèhófà kò tíì gbàgbé mi, ni mo bá tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ mi pa dà. Lọ́tẹ̀ yìí, Juan àti Maite fara balẹ̀ pẹ̀lú mi gan an, nítorí àwọn ìbéèrè kan náà tí mo ti bi wọ́n ni mo tún máa ń bi wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà. Mo fẹ́ gbọ́ àwọn àlàyé Bíbélì léraléra kí n lè fa àwọn ìgbàgbọ́ èké tó ti jinlẹ̀ lọ́kàn mi tu. Mo sì tún fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa kí n lè ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fáwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ mi.

Ọjọ́ tí mo láyọ̀ jùlọ ní ìgbésí-ayé mi ni ọjọ́ tí mo ṣe ìrìbọmi lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87]. Àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti ṣe ìrìbọmi. Alàgbà kan ló sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì tá a dìídì sọ nítorí àwa tá a fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Bí mo ṣe ń gbọ́ àsọyé yẹn, omijé ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú mi. Gbogbo ọkàn ni mo fi ń bá àsọyé yẹn lọ, àfi bí i pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń bá mi sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àìmọye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wa bá mi yọ̀ lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ni mi ò mọ̀ rí.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Láti kékeré ni mo ti mọ̀ pé Jésù “ni ọ̀nà.” (Jòhánù 14:6) Àmọ́, bí mo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí jẹ́ kí n mọ ẹni tí Jésù ṣamọ̀nà wa sọ́dọ̀ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà. Ní báyìí, mo lè gbàdúrà sí Ọlọ́run bíi Baba mi ọ̀wọ́n àti Ọ̀rẹ́ mi. Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà * tí mo kà ló jẹ́ kí n yí ìgbésí ayé mi padà. Òru ọjọ́ kan péré ni mo fi ka ìwé yẹn láti páálí dé páálí. Ó wọ̀ mi lọ́kàn gan-an nígbà ti mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe láàánú tó!

Tí mo bá rántí gbogbo ohun tí ojú mi rí nítorí mò ń wá ẹ̀kọ́ òtítọ́ kiri, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ló sábà máa ń wá sí mi lọ́kàn, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” (Mátíù 7:7) Ní báyìí tí mo ti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ń jẹ mi lọ́kàn, ńṣe ni inú mi máa ń dùn láti sọ àwọn ohun tí mo ti kọ́ fún àwọn èèyàn.

Kódà, nísinsìnyí tí mo ti di ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tí mo ní láti kọ́ nípa Jèhófà. Inú mi máa ń dùn láti lọ sí ilé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo máa ń kọ́ ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbẹ̀, mó sì tún máa ń wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Nígbà tí Ọlọ́run bá sọ gbogbo ayé di Párádísè, iṣẹ́ olùkọ́ ló ṣì wù mí kí n ṣe. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ní pàtàkì, mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àwọn èèyàn mi tó ti kú máa tún pà dà wà láàyè, tí màá sì láǹfààní láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 24:15) Inú mi á mà dùn o, láti ṣàlàyé fún wọn nípa ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún mi ní ọjọ́ ogbó mi!

^ ìpínrọ̀ 15 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.