Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí Jésù fi ń pa dà bọ̀?

Kí Jésù tó lọ sí ọ̀run ní ọdún 33 sànmánì Kristẹni, ó ṣèlérí pé òun ń pa dà bọ̀. Ó fi ara rẹ̀ wé ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá, ọkùnrin náà rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà tó jìn, ó sì pẹ́ gan-an níbẹ̀, àmọ́ nígbà tó pa dà, ó dé pẹ̀lú agbára láti ṣàkóso bí ọba. Torí náà, ìdí tí Jésù fi ń pa dà bọ̀ ni pé, ó fẹ́ mú ìjọba tó dára wá sórí ilẹ̀ ayé.—Ka Lúùkù 19:11, 12.

Jésù máa mú ìjọba tó dára wá sórí ilẹ̀ ayé

Ṣé gbogbo ojú ló máa rí Jésù nígbà tó bá pa dà wá? Rántí pé, nígbà tí Ọlọ́run jí Jésù dìde, Jésù di ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí. (1 Pétérù 3:18) Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. (Sáàmù 110:1) Nígbà tó yá, ó wọlé wá sọ́dọ̀ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, tó fún un ní agbára láti ṣàkóso aráyé. Torí náà, Jésù ò ní pa dà wá bí ẹ̀dá èèyàn mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa wá bí Ọba tí a kò lè fojú rí.—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Kí ni Jésù máa ṣe tó bá dé??

Tí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ tí a kò lè fojú rí bá dé, ó máa ṣèdájọ́ aráyé. Ó máa pa àwọn ẹni ibi run, á sì fún àwọn tó bá gbà á bí Ọba ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Mátíù 25:31-33, 46.

Ìṣàkóso Jésù máa sọ ayé di Párádísè. Jésù máa jí àwọn òkú dìde kí wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Lúùkù 23:42, 43.