Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  December 2013

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Iṣẹ́ Jèhófà Ni Mo Fi Ìgbésí Ayé Mi Ṣe

Iṣẹ́ Jèhófà Ni Mo Fi Ìgbésí Ayé Mi Ṣe

Oṣù January, ọdún 1937 ni mo jáde ilé ẹ̀kọ́ girama, mo sì wọ Yunifásítì ti Iowa tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síbi tí à ń gbé ní àárín ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà. Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an torí pé mo ń lọ sí iléèwé, mo sì tún ń ṣiṣẹ́ kí ń lè sanwó iléèwé mi. Látìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti wù mí kí n mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ilé gíga àti àwọn afárá alásokọ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1942, mo ti wà ní ìpele karùn ún ní Yunifásítì, oṣù díẹ̀ ló sì kù kí n gba oyè àkọ́kọ́ jáde gẹ́gẹ́ bi ẹnjiníà tó ń yàwòrán ilé. Àmọ́, oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kó wọnú Ogun Àgbáyé Kejì. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú àwọn méjì tá a jọ ń gbé sọ fún mi pé kí n lọ bá ẹni tó máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń gbé ìsàlẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ilé wa sọ̀rọ̀. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń jẹ́ John O. (Johnny) Brehmer. Bó ṣe fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè tí mo bi í yà mí lẹ́nu gan-an. Èyí ló wú mi lórí tí mo fi gbà kó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lọ wàásù nígbàkigbà tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀.

Nígbà yẹn, Otto, ìyẹn Bàbá Johnny ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun sì ni ọ̀gá pátápátá ní Báńkì ti ìlú Walnut tó wà ní Iowa, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́, bàbá Johnny fi ipò ńlá yìí sílẹ̀ kó lè máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àpẹẹrẹ àtàtà tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi lélẹ̀ wú mi lórí gan-an, kò sì pẹ́ tí èmi náà fi ṣe ìpinnu pàtàkì kan.

MO PINNU OHUN TÍ MO FẸ́ ṢE

Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ àgbà ní Yunifásítì sọ fún mi pé máàkì mi ti ń lọ sílẹ̀ jù, àti pé tí mi ò bá múra sí ẹ̀kọ́ mi, mi ò ní lè gboyè jáde pẹ̀lú àwọn máàkì tó dáa tí mo ti gbà tẹ́lẹ̀. Lọ́jọ́ náà lọ́hùn-ún, tọkàntọkàn ni mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ wa ní ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ẹ̀ka ti mo wà sọ pé òun fẹ́ rí mi. Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún mi pé iléeṣẹ́ kan ń wá ẹnjiníà tó jáfáfá, òun sì ti gbẹnu sọ fún mi pé màá lè ṣe iṣẹ́ náà. Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ mo jẹ́ kó mọ̀ pé iṣẹ́ Jèhófà ni mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe. Mo ṣèrìbọmi ní June 17, ọdún 1942, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi yàn mí láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, ìyẹn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù.

Lọ́dún 1942 yẹn, ìjọba sọ pé kí n wá wọṣẹ́ ológun. Nígbà tí mo dé iwájú ìgbìmọ̀ tó ń múni wọṣẹ́ ológun, mó ṣàlàyé pé mi ò ní lè jagun nítorí ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì. Mo tún fi àwọn ìwé ẹ̀rí tí mo gbà níléèwé hàn wọ́n, èyí tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó kọ́ mi níṣẹ́ fi jẹ́rìí nípa ìwà rere mi àti òye iṣẹ́ tí mo ni gẹ́gẹ́ bí ọ̀jáfáfá nínú iṣẹ́ yíyàwòrán ilé. Síbẹ̀, wọ́n ní kí n san owó ìtanràn tó lé ní mílíọ̀nù kan àtààbọ̀ owó náírà, wọ́n sì tún jù mí sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún ní Leavenworth, tó wà ní Kansas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

BÍ NǸKAN ṢE RÍ FÚN MI LẸ́WỌ̀N

Ó lé ní ọgbọ̀n-lé-rúgba [230] àwa ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Leavenworth

Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní Leavenworth lé ní ọgbọ̀n-lé-rúgba [230], iṣẹ́ àgbẹ̀ sì ni wọ́n ń kó àwọn èèyàn ṣe lẹ́wọ̀n yìí. Gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà  ẹ̀wọ̀n ń ṣọ́ wa, àwọn kan nínú wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni wá àti pé àwọn ohun tá a ti kọ́ nínú Bíbélì ló mú ká pinnu láti má ṣe wọṣẹ́ ogun, èyí sì jẹ́ ká rí ojú rere wọn.

Àwọn kan lára ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn fàyè gbà wá láti máa ṣe ìjọsìn wa, wọ́n sì tún máa ń bá wa gba àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé sọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kódà, ọ̀gá wọ́dà ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Consolation (tá a wá mọ̀ sí Jí! lónìí).

LẸ́YÌN TÍ MO JÁDE LẸ́WỌ̀N, MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ

Ní February 16, ọdún 1946, ìyẹn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́ta nínú márùn ún tí wọ́n dá fún mi. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tó máa ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà yẹn, agbègbè Leavenworth ní Kansas ni wọ́n rán mi lọ láti wàásù. Àyà mi là gààrà bí mo ṣe gbọ́ pé ibẹ̀ ni màá ti máa wàásù torí pé wọ́n kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an níbẹ̀. Kò rọrùn fún mi rárá láti rí iṣẹ́ níbẹ̀, àtigbọ́ bùkátà dogun, agbára káká sì ni mo fi rí ibi tí mo gbé.

Mo rántí ọjọ́ kan tí mò ń wàásù láti ilé-dé-ilé, mo pàdé ẹ̀ṣọ́ kan tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà tẹ́lẹ̀, ó jágbe mọ́ mi, ó ní: “Àfira, kó ìranù ẹ kúrò níbí!” Nígbà tí mo rí kóńdó gbàǹgbà tó ń gbé bọ̀, orí mi fò lọ, mo ya tètè bẹ́sẹ̀ mi sọ̀rọ̀. Níbòmíì tí mo tún wàásù dé, obìnrin tí mo bá sọ̀rọ̀ sọ pé: “Dúró dè mí mò ń bọ̀,” ló bá wọlé lọ. Bí mo ṣe ń dúró dè é, ṣàdédé ni mo rí tẹ́nì kan ṣí fèrèsé àjà tó wà lókè, àfi wàà-rà-wà tó da omi abọ́ ìdọ̀tí tó fọ̀ sí mi lára, ńṣe ni gbogbo aṣọ mi tùtù látòkè dẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ ìwàásù mi lọ́pọ̀lọpọ̀. Torí mo gbọ́ pé àwọn kan tí mo fún ní ìwé nígbà yẹn ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí.

Lọ́dún 1943 wọ́n dá ilé ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì sílẹ̀ nílùú New York, èmi náà sì ní àǹfààní láti lọ síbẹ̀. Mo wà lára àwọn tó lọ sí kíláàsì kẹwàá ní February 8, ọdún 1948. Ilé ẹ̀kọ́ yẹn là ń pé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lónìí. Lẹ́yìn tí mo ṣe tán níléèwé yẹn, wọ́n yàn mí láti lọ máa wàásù ní ilẹ̀ Gold Coast, tá a wá mọ̀ sí Gánà lónìí.

Nígbà tí mo dé ilẹ̀ Gold Coast, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn òyìnbó ni wọ́n yàn mí láti máa wàásù fún. Àmọ́ lópin ọ̀sẹ̀, mo máa ń lọ sí ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yẹn ká lè jọ wàásù láti ilé-dé-ilé. Mo tún máa ń lọ sí àwọn àdádó níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò pọ̀ sí, kí n lè kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa wàásù. Mo máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ tó wà ní Ivory Coast, tá a wá mọ̀ sí Côte d’Ivoire lónìí, kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí n sì fún wọn ní ìṣírí.

Nígbà tí mò ń wàásù ní àgbègbè yẹn, mo kọ́ láti máa ṣe bí àwọn ọmọ Áfíríkà. Bí àpẹẹrẹ, mo gbé inú ahéré tí wọ́n fi amọ̀ kọ́, mo fọwọ́ jẹun, mo sì kọ́ bí mo ṣe lè lóṣòó láti ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ síta bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ní aginjù. (Diutarónómì 23: 12-14) Gbogbo nǹkan yìí ló wú àwọn ará ìlú yìí lórí, ọ̀rọ̀ dáadáa ni wọ́n sì ń sọ nípa èmi àti àwọn yòókù tí a jẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀. Kódà àwọn ìyàwó àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà kan, àwọn alátakò fínná mọ́ wa, wọ́n tiẹ̀ tún lọ gbàṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ àdúgbò kí wọ́n lè wọ́gi lé ìwé àṣẹ ìwọ̀lú wa. Àmọ́ àwọn ìyàwó àwọn aláṣẹ yìí ló ràn wá lọ́wọ́, wọ́n lọ bá àwọn ọkọ wọn sọ̀rọ̀, bí wọ́n ṣe yí àṣẹ náà pa dà nìyẹn!

Ọ̀pọ̀ àwa tí a wá ṣe míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà ni àìsàn ibà mú. Akọ ibà fojú mi rí màbo, ara gbígbóná àti òtútù náà ò gbẹ́yìn. Nígbà míì, ńṣe ni mo máa ń di àgbọ̀n mi mú kó má bàa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí òtútù. Síbẹ̀ mo láyọ̀, ọkàn mi sì balẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe.

Láàárín ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ tí mo lò nílẹ̀ Áfíríkà, èmi àti ọmọbìnrin kan tí mo pàdé ní Amẹ́ríkà, ìyẹn Eva Hallquist máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ síra wa. Mo gbọ́ pé òun náà wà lára kíláàsì kọkàndínlógún tó fẹ́ gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní July 19, 1953, níbi àpéjọ àgbáyé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa wáyé ní Pápá Ìṣeré ti Yankee ní ìlú New York. Kíá ni mo ṣètò pé kí adarí ọkọ̀ ojú omi kan gbà mí láyè láti ṣiṣẹ́ fún un kó lè fi ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ gbé mi dé Amẹ́ríkà.

Ìrìn àjò yẹn tó ọjọ́ méjìlélógún [22], nǹkan o sì rọrùn lórí omi, àmọ́ mo ṣáà sapá kí n lè rí Eva ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn. Orí òkè ilé rírẹwà kan tó wà lókè téńté tó kọjú sí etíkun ńlá kan ní New York, ni mo ti sọ fún Eva pé kó fẹ́ mi. Nígbà tó yá, Eva wá bá mi ní ilẹ̀ Gold Coast, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù nìṣó níbẹ̀.

MO BÓJÚ TÓ OJÚṢE MI NÍNÚ ÌDÍLÉ

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí èmi àti Eva ti wà nílẹ̀ Áfíríkà, màmá mi kọ lẹ́tà ránṣẹ́ pé àrùn jẹjẹrẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa bàbá mi. Ní kíá, èmi àti Eva gba àyè láti padà sí Amẹ́ríkà ká lè lọ tọ́jú bàbá. Láìka gbogbo akitiyan wa sí, ìlera bàbá ò yí pa dà, kò sí pẹ́ tí wọ́n fi gbẹ́mìí mì.

Nígbà tó yá, a pa dà sí ilẹ̀ Gánà. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà la tún gbọ́ pé ara ìyá mi kò le mọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ wa kan gba èmi àti Eva níyànjú pé ká padà lọ sílé ká lọ bójú tó màmá mi. Ìpinnu yìí ló le jù fún wa láti ṣe, kò rọrùn fún wa rárá pé ká pa dà sílé. Torí a ti lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, èmi àti Eva sì ti gbé pọ̀ fún ọdún mọ́kànlá [11] nígbà náà. Àmọ́, àwa méjèèjì pa dà sí Amẹ́ríkà.

Èmi rèé níbi tí mo ti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olóyè nílẹ̀ Gánà

Ní gbogbo ọdún tí a fi bójú tó màmá mi, èmi àti ìyàwó mi máa ń gba ìtọ́jú náà ṣe fún ara wa. Ní January 17, ọdún 1976, màmá mi kú ní ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86]. Ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé. Wọ́n sọ pé Eva náà ti ní àrùn jẹjẹrẹ. A jà fitafita pé ká lè wo àrùn náà, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wa já sí. Eva kú ní June 4, ọdún 1985 ní ẹni àádọ́rin [70] ọdún.

Ọ̀PỌ̀ ÌTẸ̀SÍWÁJÚ TÚN BÁ IṢẸ́ ALÁYỌ̀ TÍ MÒ Ń ṢE

Lọ́dún 1988, wọ́n ní kí n wá síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì Gánà tí wọ́n mú gbòòrò sí i. Mánigbàgbé lọjọ́ náà! Nígbà tí mó dé sílẹ̀ Gánà ni nǹkan bí ogójì [40] ọdún sẹ́yìn, ìwọ̀nba ọgọ́rùn-ún èèyàn ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọ̀dún 1988, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34,000] lọ, kódà ní báyìí, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàdọ́fà [114,000]!

Ọdún méjì lẹ́yìn tí mo ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ Gánà, mo gbé ọ̀rẹ́ Eva, ìyẹn Betty Miller níyàwó, ní August 6, ọdún 1990. Látìgbà yẹn ni àwa méjèèjì ti ń fi ayé wa ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run nìṣó. À ń fojú sọ́nà fún àjíǹde tó máa wáyé nínú Párádísè nígbà tí a ó tún rí àwọn òbí wa àgbà, màmá àti bàbá mi àti Eva.—Ìṣe 24:15.

Omijé ayọ̀ máa ń dà lójú mi tí mo bá ti rántí àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta tí Ọlọ́run ti lò mí fún, láti nǹkan bí àádọ́rin [70] ọdún sẹ́yìn. Mo sábà máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fi ayé mi ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí, síbẹ̀, Jèhófà Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ṣì ń fún mi lókun kí n lè máa fi ayé mi sìn ín nìṣó.