Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  December 2013

‘Láti Inú Àwọn Òkè Ńlá Ni Ìwọ Yóò Ti Máa Wa Bàbà’

‘Láti Inú Àwọn Òkè Ńlá Ni Ìwọ Yóò Ti Máa Wa Bàbà’

Àwọn awalẹ̀pìtàn kan ń ṣèwádìí ní aginjù Jùdíà, wọ́n ń fara balẹ̀ tú gbogbo ihò àpáta àti àwọn ọ̀nà tóóró tó wà níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n ń rò ó pé ǹjẹ́ àwọn lè rí àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó ṣeyebíye tàbí àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ irú bí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú tí àwọn ń wá? Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi òkè kan tó ga fíofío, tí wọ́n sì tú inú ihò àpáta tó wà níbẹ̀, ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí àwọn ohun ìṣúra tó ṣeyebíye, èyí tí wọ́n pè ní ìṣúra iyebíye ti Nahal Mishmar.

OṢÙ March ọdún 1961 ni wọ́n rí àwọn ìṣúra tó ṣeyebíye yẹn, tí wọ́n wé sínú ẹní kan tí wọ́n fi esùsú ṣe, tí wọ́n sì fi há ibì kan tó lanu lára àpáta. Oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n bá nínú rẹ̀ tó irínwó [400], bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀. Lára àwọn ohun tí wọ́n rí ni àwọn ọ̀pá ọba, oríṣiríṣi adé, àwọn irinṣẹ́, ọ̀pá táwọn ìjòyè máa ń mú dání àtàwọn ohun ìjà mìíràn. Àwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí yìí gbàfiyèsí àwọn tó ń ka Bíbélì, torí àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 4:22 tọ́ka sí Tubali-kéènì, pé ó jẹ́ “olùrọ gbogbo onírúurú irinṣẹ́ bàbà àti irin.”

Ọ̀pọ̀ ìbéèrè làwọn èèyàn ti béèrè nípa ibi tí àwọn ohun ìṣúra tó ṣíṣeyebíye yìí ti wá. Àwọn ohun tí wọn rí yìí fi hàn pé láyé àtijọ́, wọ́n máa ń wa bàbà láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan, wọ́n máa ń yọ́ ọ, wọ́n á sì fi rọ onírúurú nǹkan.

ÀWỌN IBI TÍ WỌ́N TI Ń WA BÀBÀ NÍ ILẸ̀ ÌLÉRÍ

Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ fún wọn pé: “Láti inú àwọn òkè ńlá [ilẹ̀ náà] ni ìwọ yóò ti máa wa bàbà.” (Diutarónómì 8:7-9) Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti Jọ́dánì, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ibi mélòó kan tí wọ́n ti máa ń wa bàbà àti ibi tí wọ́n ti máa ń yọ́ ọ nígbà àtijọ́. Àwọn ibi tí wọ́n rí ni Feinan, Tímínà àti Khirbat en-Nahas. Kí ni àwọn ibi tí wọ́n rí yìí jẹ́ ká mọ̀?

Ní Tímínà àti Feinan, wọ́n rí àwọn kòtò kéékèèké tó wà káàkiri ibi tí wọ́n ti wa bàbà fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún. Kódà, àwọn àlejò tó bá lọ síbẹ̀ lónìí ṣì máa rí àwọn àfọ́kù òkúta bàbà nílẹ̀ káàkiri. Àwọn awakùsà láyé àtijọ́ máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára gan-an, wọ́n máa ń fi irinṣẹ́ tí wọ́n fi òkúta ṣe gbẹ́ àpáta kí wọ́n tó kan àwọn ojú ibi tí bàbà wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti wa àwọn bàbà tó wà lókè tán ráúráú, wọ́n á fi àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi irin ṣe gbẹ́ àpáta náà wọnú, ibẹ̀ á wá ní ojú ihò tó fẹ̀ àti àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀. Nínú Bíbélì, ìwé Jóòbù ṣàpèjúwe irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí. (Jóòbù 28:2-11) Iṣẹ́ tó gba agbára ni iṣẹ́ yìí, kódà láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta sí ìkarùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, àwọn aláṣẹ Róòmù máa ń rán àwọn ọ̀daràn paraku àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì lọ ṣiṣẹ́ ní ibi tí wọ́n ti máa ń wa bàbà ní Feinan.

Ní Khirbat en-Nahas (tó túmọ̀ sí “Ìdàrọ́ Bàbà”), wọ́n rí òkìtì ìdàrọ́ bàbà, èyí fi hàn pé bàbà tí wọ́n máa ń yọ́ níbẹ̀ pọ̀ gan-an. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé wọ́n máa ń kó ẹta (ìyẹn òkúta tí wọ́n máa yọ irin lára rẹ̀) wá sí ibẹ̀ láti ibi tó sún mọ́ tòsì tí wọ́n ti  ń wa kùsà, bíi Feinan àti Tímínà. Tí wọ́n bá fẹ́ yọ́ bàbà kúrò nínú ẹta, wọ́n máa fi àwọn ọ̀pá àti ẹwìrì fẹ́ iná tí wọ́n dá, kí ẹyín iná náà lè gbóná gan-an. Wọ́n á wá koná mọ́ ẹta yìí dáadáa fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá, á sì gbóná gan-an títí tí bàbà ara rẹ̀ á fi yọ́ kúrò. Nǹkan bí ẹta kìlógíráàmù márùn-ún ni wọ́n máa lò kí wọ́n tó rí kìlógíráàmù kan bàbà, tí wọ́n lè fi rọ oríṣiríṣi nǹkan.

OHUN TÍ WỌ́N Ń LO BÀBÀ FÚN NÍ ÍSÍRẸ́LÌ ÀTIJỌ́

Lórí Òkè Sínáì, Jèhófà dìídì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni pé irin iyebíye tí wọ́n ń wà jáde nínú ilẹ̀ ni kí wọ́n fi kọ́ àgọ́ ìjọsìn. Nígbà tó yá, irú ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́kísódù, orí 27) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mọ bí wọ́n ṣe ń fi irin rọ onírúurú nǹkan kí wọ́n tó lọ sí Íjíbítì, ó sì lè jẹ́ pé ibẹ̀ ni wọ́n ti kọ́ ọ. Nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà. Wọ́n tún ṣe àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn, lára àwọn ohun èlò yìí ni bàsíà ńlá, ìkòkò, páànù, ṣọ́bìrì àti àmúga.—Ẹ́kísódù 32:4.

Nígbà ìrìn-àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù, wọ́n dé agbègbè kan tí bàbà pọ̀ níbẹ̀ dáadáa, bóyá ní Púnónì (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Feinan lónìí), àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé pé mánà tí àwọn ń jẹ ti sú àwọn àti pé omi ò tó. Jèhófà fìyà jẹ wọ́n nítorí ohun tí wọ́n ṣe yìí, ó mú kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán, ọ̀pọ̀ sì kú. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, Mósè bẹ̀bẹ̀ nítorí wọn, Jèhófà wá pàṣẹ fún un pé kó fi bàbà ṣe ère ejò kan, kó sì gbé e kọ́ sórí òpó. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ pé bí ejò bá ti bu ènìyàn kan ṣán, tí ó sì tẹjú mọ́ ejò bàbà náà, nígbà náà, òun a máa wà láàyè nìṣó.”—Númérì 21:4-10; 33:43.

BÀBÀ TÍ SÓLÓMỌ́NÌ ỌBA FI KỌ́ TẸ́ŃPÌLÌ

Apá tó pọ̀ jù nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n fi bàbà ṣe

Sólómọ́nì Ọba lo bàbà tó pọ̀ gàn-an láti fi ṣe tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn bàbà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ kó bọ̀ nígbà tó ṣẹ́gun àwọn ará Síríà ni Sólómọ́nì lò. (1 Kíróníkà 18:6-8) “Òkun dídà,” (ìyẹn bàsíà ràgàjì kan) tí àwọn àlùfáà fi máa ń wẹ̀ lè gba nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún àti ààbọ̀ [17,500] gálọ́ọ̀nù omi. Ó sì lè wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] àpò sìmẹ́ǹtì. (1 Àwọn Ọba 7:23-26, 44-46) Àwọn ọwọ̀n tàbí òpó ràgàjì méjì tí wọ́n fi bàbà ṣe ló wà lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé tẹ́ńpìlì. Wọ́n ga tó mítà mẹ́jọ (8m), àwọn ọpọ́n tó wà lórí ọwọ̀n náà sì ga tó nǹkan bí mítà méjì àtààbọ̀ (2.2m). Ọwọ̀n náà ní ihò láàárín, ó nípọn tó sẹ̀ǹtímítà méje àtààbọ̀ (7.5cm), fífẹ̀ rẹ̀ si dín díẹ̀ ní mítà méjì (1.7m). (1 Àwọn Ọba 7:15, 16; 2 Kíróníkà 4:17) Ó máa yà wá lẹ́nu gan-an tá a bá mọ adúrú bàbà tí wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn.

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń lo bàbà gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n fi bàbà ṣe irú bí àwọn ohun ìjà, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀, àwọn ohun èlò ìkọrin àti ilẹ̀kùn. (1 Sámúẹ́lì 17:5, 6; 2 Àwọn Ọba 25:7; 1 Kíróníkà 15:19; Sáàmù 107:16) Jésù tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa owó “bàbà” nínú àpò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà mẹ́nu kan “Alẹkisáńdà alágbẹ̀dẹ bàbà.”—Mátíù 10:9; 2 Tímótì 4:14.

Àwọn awalẹ̀pìtàn àti àwọn òpìtàn ṣì nílò ìsọfúnni sí i nípa ìtàn àti orísun àwọn èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe táwọn èèyàn ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Tó fi mọ́ ohun ìṣúra iyebíye ti Nahal Mishmar tí wọ́n ṣàwárí yìí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún jẹ́ “ilẹ̀ tí ó dára, . . . láti inú àwọn òkè ńlá rẹ̀ [sì] ni [wọn] yóò ti máa wa bàbà.”—Diutarónómì 8:7-9.