Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  November 2013

 SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“Olùsẹ̀san fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”

“Olùsẹ̀san fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”

Ǹjẹ́ Jèhófà mọyì bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń sapá láti ṣe ohun tó wù ú? Àwọn kan ò rò pé ó mọyì wọn. Kódà wọ́n gbà pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wa. Àmọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí wulẹ̀ ń jẹ́ kí èèyàn ní èrò tí kò tọ́ nípa Ọlọ́run ni. A dúpẹ́ pé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ òkodoro òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ó tún jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń sapá láti fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Hébérù 11:6.

Kí la lè ṣe láti wu Jèhófà? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa.” Kíyè sí pé, Pọ́ọ̀lù kò sọ pé ó nira láti wu Ọlọ́run láìsí ìgbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run. Ká sòótọ́, kòṣeémáàní ni ìgbàgbọ́ jẹ́ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.

Irú ìgbàgbọ́ wo ló yẹ ká ní tí a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Jèhófà? Ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi ohun méjì hàn. Àkọ́kọ́, a ‘gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà.’ Kò sí bí a ṣe lè ṣe ohun tó wu Ọlọ́run tí a kò bá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà. Ojúlówó ìgbàgbọ́ ju pé ká kàn gbà pé Ọlọ́run wà. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà pé Jèhófà wà. (Jákọ́bù 2:19) Ó yẹ kí ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé wa, ìyẹn ni pé, àwọn ohun tá bá ń ṣe lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé lóòótọ́ la gbà pé Ọlọ́run wà.—Jákọ́bù 2:20, 26.

Ìkejì, a “gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé” Ọlọ́run “ni olùsẹ̀san.” Ó máa ń dá ẹni tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ lójú pé gbogbo ìsapá òun láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run kò ní já sí asán. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Kò sí bá a ṣe lè ṣe ohun tó wu Jèhófà tí kò bá dá wa lójú pé ó lágbára láti san èrè fún wa àti pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 1:17; 1 Pétérù 5:7) Ẹni tó bá sọ pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wa tàbí pé abara-moore jẹ ni tàbí pé kò lawọ́, kò tíì mọ Ọlọ́run.

Àwọn wo ni Jèhófà máa san èrè fún? Pọ́ọ̀lù sọ pé yóò san èrè fún “àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “fi taratara wá a” kò túmọ̀ sí pé ká “jáde lọ wá nǹkan,” àmọ́, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ká sì “jọ́sìn rẹ̀.” Ìwé ìwádìí míì sọ pé ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí túmọ̀ sí ohun tá a fi gbogbo ara ṣe àti ohun tá a dìídì ṣe tọkàntọkàn. Ní ti gidi, Jèhófà máa ń san èrè fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn mú kí wọ́n máa fi ìfẹ́ àtọkànwá àti ìtara sìn ín.—Mátíù 22:37.

Kò sí bá a ṣe lè ṣe ohun tó wu Jèhófà tí kò bá dá wa lójú pé ó lágbára láti san èrè fún wa àti pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀

Báwo ni Jèhófà ṣe máa san èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Ó ṣe ìlérí àgbàyanu kan fún wọn pé lọ́jọ́ iwájú, wọ́n máa gbádùn ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Èyí fi hàn pé ó lawọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. (Ìṣípayá 21:3, 4) Kódà nísinsìnyí, Jèhófà ń bù kún àwọn tó ń fi taratara wá a. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn ládùn, kí ọkàn wọn sì balẹ̀.—Sáàmù 144:15; Mátíù 5:3.

Ní ti tòótọ́, Jèhófà mọyì wa ó sì mọrírì bí àwọn tó ń fi òótọ́ inú sin òun ṣe ń sapá gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ ohun tó o mọ̀ wẹ́rẹ́ nípa Ọlọ́run yìí mú kó wù ẹ́ láti sún mọ́ ọn? Tí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí o ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ tí Jèhófà máa ń mọyì tó sì máa ń bù kún.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún November

Títù 1-3; Fílémónì 1-25; Hébérù 1-13Jákọ́bù 1-5