“‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”Jésù Kristi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí ní 33 Sànmánì Kristẹni. *

Kò rọrùn fún àwọn kan láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí pé lójú tiwọn àdììtú ni Ọlọ́run jẹ́. Wọ́n gbà pé ó jìnnà sí àwa ẹ̀dá àti pé ìkà ni. Ohun tí àwọn míì sọ rèé:

  • “Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi, ó ń ṣe mí bíi pé kò lè gbọ́ àdúrà mi. Lójú tèmi, Ọlọ́run ò mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa rárá.”—Marco ọmọ ilẹ̀ Ítálì.

  • “Ó wù mí gan-an kí n sin Ọlọ́run, àmọ́ ó dà bíi pé ó jìnnà sí mi. Mo rò pé ìkà kan tó kàn ń fojú wa gbolẹ̀ lásán ni. Mi ò gbà pé ó láàánú rárá.”—Rosa ọmọ ilẹ̀ Guatemala.

  • “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo rò pé àṣìṣe wa nìkan ni Ọlọ́run máa ń wá, á sì máa ṣọ́ wa títí tá a máa fi ṣẹ̀ kó lè fìyà jẹ wá. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo Ọlọ́run bíi ẹni tó kàn ta kété sí wa. Lójú mi, ó jọ pé Ọlọ́run dà bí olórí ìjọba tó kàn ń ṣàkóso àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ rẹ̀, àmọ́ tí kò bìkítà rárá nípa wọn.”—Raymonde ọmọ ilẹ̀ Kánádà.

Kí ni èrò rẹ? Ṣé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni àwọn Kristẹni ti ń béèrè ìbéèrè yìí. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì kì í gbàdúrà sí Ọlọ́run Olódùmarè. Ìdí ni pé wọ́n kà á sí ẹni tó ń dẹ́rù bani tí kò ṣeé sún mọ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant tiẹ̀ sọ pé: “Báwo ni ẹlẹ́ṣẹ̀ lásánlàsàn ṣe lè gbójú gbóyà gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ń dẹ́rù bani tí ó sì jìnnà réré sí àwa èèyàn?”

Kí ló fà á tí àwọn kan fi ka Ọlọ́run sí “ẹni tó ń dẹ́rù bani tó sì jìnnà réré sí wa”? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Ọlọ́run? Tó o bá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, báwo ni ìyẹn ṣe lè mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?