Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  November 2013

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Àwọn wo ló ń lọ sí ọ̀run, kí sì nìdí?

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà pé ọ̀run ni àwọn ń lọ. Jésù sọ pé àwọn àpọ́sítélì òun tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yóò máa gbé ní ọ̀run. Kí Jésù tó kú, ó ṣèlérí fún wọn pé òun máa pèsè ibì kan sílẹ̀ fún wọn lọ́dọ̀ Bàbá òun ní ọ̀run.—Ka Jòhánù 14:2.

Kí nìdí tí àwọn kan fi máa jíǹde sí ọ̀run? Kí ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé wọ́n á jọba ní ọ̀run, wọ́n yóò sì ṣàkóso lé ayé lórí.—Ka Lúùkù 22:28-30; Ìṣípayá 5:10.

Ṣé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sí ọ̀run?

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa ń ṣàkóso. Níwọ̀n bí Jésù yóò ti jí àwọn kan sí ọ̀run kí wọ́n lè ṣàkóso lé ayé lórí, a lè gbà pé àwọn díẹ̀ ló máa yàn. (Lúùkù 12:32) Bíbélì sọ iye àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run.—Ka Ìṣípayá 14:1.

Jésù ti pèsè ibì kan sílẹ̀ ní ọ̀run fún díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀?

Àwọn tó ń lọ sí ọ̀run nìkan kọ́ ló máa gba èrè. Àwọn olóòótọ́ tí Jésù fẹ́ ṣàkóso lé lórí náà máa gba èrè. Wọ́n máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè. (Jòhánù 3:16) Ọlọ́run máa pa gbogbo èèyàn burúkú run. Àmọ́ àwọn èèyàn rere kan máa làájá, wọ́n á wà láàyè títí Párádísè á fi dé. Àwọn yòókù máa jíǹde sínú Párádísè.—Ka Sáàmù 37:29; Jòhánù 5:28, 29.