Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ November 2013 | Àwọn Irọ́ Tí Kò Jẹ́ Káwọn èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

Àwọn irọ́ tí ìsìn tí ń pa mọ́ Ọlọ́run láti ọdúnmọ́dún kò jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì mú kó jìnnà sí wọn. Báwo la ṣe mò pé Ọlọ́run kò jìnnà sí wa, kì í sì ṣe ìkà?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Nìdí Táwọn Kan Ò Fi Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bí i pé o jìnnà sí Ọlọ́run? Ṣé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Kà nípa ìdí tí àwọn Kristẹni kan fi rò bẹ́ẹ̀.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Wọ́n Parọ́ Pé Ọlọ́run Kò Lórúkọ

Ǹjẹ́ a lè mọ orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa lò ó? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Wọ́n Parọ́ Pé Àdììtú Ni Ọlọ́run

Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́ ohun ìdènà tí kò lè jẹ́ ká mọ Ọlọ́run tàbí ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ o lè nífẹ̀ẹ́ ẹni tí kò ṣe é mọ̀ tàbí ẹni tó ṣòro lóye?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Wọ́n parọ́ pé Ìkà ni Ọlọ́run

Ọ̀pọ̀ ló gbà pé Ọlọ́run máa ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ títí ayérayé. Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń hùwà burúkú? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an nígbà tí a bá kú?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Òtítọ́ Lè Dá Ẹ Sílẹ̀ Lómìnira

Ìlànà wo ni Jésù fi lélẹ̀ tí a lè fi ṣàyẹ̀wò bóyá àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn ń kọ́ni jẹ́ òtítọ́?

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn

Ọmọ rẹ fẹ́ fi irú eni tí ó jẹ́ hàn, ńṣe ni kó o jẹ́ kí ara rẹ̀ yá gágá kó lè sọ tinú rẹ̀ jáde fàlàlà. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́?

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“Olùsẹ̀san fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”

Irú ìgbàgbọ́ wo ló yẹ ká ní tí a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Jèhófà? Báwo ni ó ṣe ń san èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fi ìgbàgbọ́ sìn ín?

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”

Báwo ni ìtàn Ráhábù ṣe fi dá wa lójú pé kò sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà? Kí la rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sí ọ̀run? Wádìí ohun tí Bíbélì sọ.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Pé Ẹ̀sìn Àwọn Lẹ̀sìn Tòótọ́?

Ǹjẹ́ Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló ń ṣamọ̀nà sí ìgbàlà?