Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí gbogbo èèyàn nílé lóko mọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó rọrùn láti lóye. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó ti gbé láyé rí, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó wáyé láàárín wọn àti irú àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tó bọ́gbọ́n mu, kò sì lọ́jú pọ̀. Èyí mú kó rọrùn fún gbogbo èèyàn láti lóye rẹ̀. Wọ́n tú Bíbélì sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́ tó àwọn èèyàn kárí ayé. Kò sígbà tí àwọn ìlànà Bíbélì ò wúlò.

Pabanbarì rẹ̀ ni pé, Bíbélì kì í ṣe ìwé tó kàn sọ nípa Ọlọ́run, àmọ́ ó tún jẹ́ ìwé tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Bíbélì sọ orúkọ Ọlọ́run, irú ẹni tó jẹ́, àti ìdí tó fi dá àwa èèyàn sáyé. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run àmọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ fi Sátánì hàn ní ẹni ibi, á sì paná gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ tó ti hù. Tí a kò bá fiyè méjì ka Bíbélì, á jẹ́ ká lè ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí tó dájú.

Àwọn ìsọfúnni tó wà Bíbélì ò láfiwé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa àwọn kókó pàtàkì bíi:

  • Ibi tí a ti ṣè wá àti ìdí tí ìyà fi ń jẹ́ ọmọ aráyé

  • Ètò ti Ọlọ́run ṣe láti dá aráyé nídè

  • Ohun tí Jésù ṣe fún wa

  • Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí àti àwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú

Jọ̀wọ́ fara balẹ̀ wo àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e kí o lè mọ ohun tó wà nínú Bíbélì.