Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÈÈYÀN PA DÀ

“Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Kórìíra Mi”

“Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Kórìíra Mi”
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1978

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: CHILE

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍJÀGÍDÍJÀGAN NI MÍ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Santiago tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Chile ni mo gbé dàgbà. Àwọn ọmọọ̀ta pọ̀ ní àdúgbò mi, oògùn olóró àti ìwà ọ̀daràn ò sì jọ wọ́n lójú. Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà tí wọ́n pa bàbá mi. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pẹ̀lú ọkùnrin kan tó rorò, ó sábà máa ń na èmi àti màmá mi. Gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn ṣì ń bà mí nínú jẹ́ títí dòní.

Bí mo ṣe ń dàgbà, àwọn ìwà tí wọ́n ń hù ládùúgbò bẹ̀rẹ̀ sí í ràn mí, bí èmi náà ṣe di oníjàgídíjàgan nìyẹn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ orin rọ́ọ̀kì tó máa ń dún kíkankíkan, mo di ọ̀mùtí, mo sì ń lo oògùn olóró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bá àwọn tó ń ta oògùn olóró ja ìjà ìgboro, wọ́n pa mí tán díẹ̀ ló kù. Nígbà tó yá, àwọn ẹgbẹ́ jàǹdùkú míì rán alágbára kan tó jẹ́ ọmọọ̀ta pé kó wá pa mí, mo sá lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ àmọ́ ó dọ́gbẹ́ sí mi lára. Ìgbà kan tún wà tí àwọn tó ń ta oògùn olóró gbé ìbọn sí mi létí, wọ́n sì fẹ́ fokùn sí mi lọ́rùn kí wọ́n lè gbé mi kọ́.

Lọ́dún 1996, mo rí ọmọbìnrin kan tí mo nífẹ̀ẹ́, Carolina lorúkọ rẹ̀, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1998. Lẹ́yìn tí a bí ọmọ wa ọkùnrin, ńṣe ni ẹ̀rù ń bà mí pé bí mo ṣe máa ń bínú lódìlódì yìí, mo lè bẹ̀rẹ̀ sí lu ìyàwó àti ọmọ mi bí ọkọ màmá mi ṣe máa ń ṣe sí èmi àti ìyá mi nígbà yẹn. Torí náà, mo lọ sí àgọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ni láti jáwọ́ nínú àṣà búburú, kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́. Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìtọ́jú ti mo gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà já sí. Kí nǹkan kékeré máà tíì ṣẹlẹ̀ ni, màá ti fara ya, kò sí ẹni tó kápá mi. Nígbà tó yá, mo ronú ohun tí mo lè ṣe tí mi ò fi ní máa pa ìdílé mi lára mọ́, ni mo bá gbìyànjú láti pokùn so. Àmọ́ mi ò rí i ṣe.

Ó ti pẹ́ tí mo ti gbà pé kò sí Ọlọ́run, àmọ́ ní báyìí mo fẹ́ mọ Ọlọ́run. Torí náà, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ajíhìnrere fún ìgbà díẹ̀. Ní gbogbo àkókò yẹn, ìyàwó mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo kórìíra àwọn Ajẹ́rìí yẹn, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe ni mo máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn. Àmọ́ ó máa ń yà mí lẹ́nu pé wọn kì í fi ọ̀rọ̀ mi ṣèbínú, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ni wọ́n fi máa ń dá mi lóhùn.

Lọ́jọ́ kan, Carolina sọ pé kí n ka Sáàmù 83:18 nínú Bíbélì mi. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Ó yà mí lẹ́nu  gan-an torí pé nínú ẹ̀sìn mi wọ́n kọ́ mi nípa ọlọ́run kan, àmọ́ kì í ṣe Jèhófà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i, inú mi dùn nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run aláàánú àti pé ó máa ń dárí jini. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, Ẹ́kísódù 34:6, 7 sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.”

Síbẹ̀síbẹ̀, kò rọrùn fún mi láti fi ohun tí mò ń kọ́ ṣèwà hù. Mo ti ro ara mi pin pé mi ò ní lè kápá ìbínú mi láéláé. Ṣùgbọ́n, ìgbàkigbà tí mo bá tún ti bínú sódì, ìyàwó mi máa ń fún mi níṣìírí. Ó máa ń rán mi létí pé Jèhófà mọyì gbogbo bí mo ṣe ń sapá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè bọ́ nínú ìwà yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tó máa ń sọ máa ń gbé mi ró, kò jẹ́ kí n juwọ́ sílẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, Arákùnrin Alejandro tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ pé kí n ka Gálátíà 5:22, 23. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé èso ti ẹ̀mí ni “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Alejandro wá ṣàlàyé pé kì í ṣe agbára mi ni mo fi máa ní àwọn ìwà yìí, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló máa jẹ́ kí n lè ní i. Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ fún mi lọ́jọ́ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì yí èrò mi pa dà pátápátá!

Nígbà tó yá, mo lọ sí àpéjọ ńlá kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe. Bí nǹkan ṣe lọ létòletò, tí ibẹ̀ mọ́ tónítóní àti bí gbogbo wọn ṣe ń yọ̀ mọ́ ara wọn jẹ́ kó dá mi lójú pé mo ti rí ẹ̀sìn tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Mo ṣe ìrìbọmi lóṣù February ọdún 2001.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Ní báyìí, mi ò hùwà ipá mọ́ torí Jèhófà ti sọ mí di èèyàn àlááfíà. Ṣe ló dà bíi pé ó fà mí kúrò nínú ẹrẹ̀ tí mo rì sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kórìíra mi, àmọ́ kì í ṣe ẹ̀bi wọn. Mo dúpẹ́ pé èmi àti ìyàwó mi àtàwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì ń fi àlàáfíà sin Jèhófà.

Kàyéfì ni ọ̀rọ̀ mi jẹ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́, wọ́n ò mọ̀ pé mo lè yí pa dà báyìí. Èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èmi náà ti láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi dẹni tó ń sin Jèhófà. Ohun ayọ̀ ńlá gbáà ló jẹ́ láti rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé tiwọn náà pa dà!