Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Míkà sọ nípa Mèsáyà náà ní ìmúṣẹ. Ìgbà yẹn ni wọ́n bí Jésù sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 29 Sànmánì Kristẹni, apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa Mèsáyà ní ìmúṣẹ. Ìgbà yẹn ni Jésù ṣe ìrìbọmi tí Ọlọ́run sì fi ẹ̀mí mímọ yàn án. Àkókò tí Ọlọ́run sọ pé irú-ọmọ náà máa dé ló dé, ìyẹn Mèsáyà tí àwọn èèyàn ti ń retí látọdúnmọdún!

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó ń “polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ni Jésù ṣe rí. Onínúure àti èèyàn jẹ́jẹ́ ni. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn sì jẹ ẹ́ lógún. Àwọn ohun tó fi kọ́ni fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó tún wo “gbogbo onírúurú àìlera” sàn, èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀. (Mátíù 4:23) Tọmọdé tàgbà ló ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Jésù, àwọn náà sì gbà bíi ti ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sọ pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà”!—Jòhánù 1:41.

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé kó tó di pé òun gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn èèyàn pátápátá, ogun, ìsẹ̀lẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ìṣòro míì máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ó wá rọ gbogbo èèyàn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 13:37.

Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, ó máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, àmọ́ nígbẹ̀yìn, àwọn ọ̀tá rẹ̀ pa á. Ikú Jésù yìí ló pèsè ẹbọ pípé tó kúnjú ìwọ̀n láti ra ohun tí Ádámù àti Éfà ti gbé sọ nù pa dà, ìyẹn ìyè ayérayé nínú Párádísè.

Bí Jésù ṣe kú àti bí Ọlọ́run ṣe jí i dìde lọ́jọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ní ìmúṣẹ. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han èyí tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó gbé iṣẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọ́n máa polongo ìhìn rere nípa òun àti Ìjọba òun fún “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 28:19) Ǹjẹ́ wọ́n ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ yẹn kúnnákúnná?

A gbé e ka Mátíù, Máàkù, Lúùkù, Jòhánù, 1 Kọ́ríńtì.