Kí á lè mọ ìdí tí ìyà fi pọ̀ láyé àti ìdí tí ìsapá àwọn èèyàn láti fòpin sí i fi ń já sí pàbó, a ní láti kọ́kọ́ mọ àwọn ohun tó fa ìyà yìí gan-an. Àwọn ohun tó fa ìyà tó ń jẹ wá pọ̀, wọ́n sì lè má rọrùn láti lóye, àmọ́ a dúpẹ́ pé Bíbélì lè jẹ́ ká mọ̀ wọ́n. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun márùn-ún tó fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Ní báyìí, a fẹ́ kí o fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàlàyé ìdí tí ìyà fi ń jẹ aráyé.—2 Tímótì 3:16.

ÌJỌBA TÓ Ń FAYÉ NI ARÁÀLÚ LÁRA

Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.”—Òwe 29:2.

A ti gbọ́ ìtàn nípa oríṣiríṣi àwọn ìjọba apàṣẹwàá tí wọ́n ni àwọn aráàlú lára, èyí sì fa ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìyà bá àwọn èèyàn. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń ṣèjọba ló rí bẹ́ẹ̀. Àwọn míì máa ń fẹ́ kí nǹkan túbọ̀ dẹrùn fún àwọn aráàlú. Ṣùgbọ́n, kété tí wọ́n bá dórí oyè, ńṣe ni gbogbo kìràkìtà wọn máa ń dòfo torí àwọn tí kò fẹ́ kí ìjọba wọn dáa tàbí àwọn tó ń bá wọn du ipò. Nígbà míì sì rèé, àwọn kan máa ń lo ipò yẹn láti kówó jẹ, àwọn aráàlú ló sì máa ń forí fá a. Abájọ tí Henry Kissinger, tó jẹ́ Olùdarí Ètò Òde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nígbà kan rí fi sọ pé: “Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá dá lórí ìròyìn àwọn ìsapá tó ti forí ṣánpọ́n, àwọn ohun tá a fojú sọ́nà fún, àmọ́ tọ́wọ́ kò tẹ̀.”

Èyí bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ìyẹn ni pé àwa èèyàn aláìpé kò ní ọgbọ́n àti òye tó jinlẹ̀ tí a fi lè dá yanjú ọ̀rọ̀ ara wa. Bí ẹnì kan kò bá lè dá yanjú ìṣòro ara rẹ̀, báwo ló ṣe lè yanjú ìṣòro odindi orílẹ̀-èdè? Ṣé o ti wá rí ìdí tí àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso kò fi lágbára láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, ìjọba burúkú ló sábà máa ń fa ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn!

ỌṢẸ́ TÍ Ẹ̀SÌN ÈKÉ Ń ṢE

Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

Gbogbo àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ni wọ́n máa ń wàásù ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan. Àmọ́ wọ́n kùnà láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn bí wọ́n ṣe lè ní ìfẹ́ tó borí ẹ̀tanú. Dípò kí ẹ̀sìn kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, òun gan-an ló sábà máa ń rúná sí ìyapa, ẹ̀tanú àti ìjà tó wà láàárín àwọn èèyàn àti láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ìdí nìyẹn tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Hans Küng fi sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Christianity and the World Religions, pé: “Ẹ̀rí ti fi hàn pé àwọn rògbòdìyàn ìṣèlú tó burú jù lọ, tó sì mú ẹ̀mí lọ jù tó tíì wáyé ni èyí tí àwọn ẹ̀sìn dá sílẹ̀.”

 Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ni kò tiẹ̀ fi bò mọ́ pé àwọn fàyè gbà á kí àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa bá ara wọn lò pọ̀. Wọn ò sì rò pé ó burú tí àwọn tó ti ṣègbéyàwó bá ń bá ẹlòmíì ṣèṣekúṣe tàbí tí ọkùnrin àtọkùnrin tàbí obìnrin àtobìnrin bá fẹ́ ara wọn. Abájọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrùn fi ń jà ràn-ìn káàkiri, tí ọ̀pọ̀ ń lóyún àìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣẹ́ wọn dà nù. Èyí ti tú ọ̀pọ̀ ìdílé ká, ó sì ti fa ọ̀pọ̀ ìrora àti ọgbẹ́ ọkàn bá àwọn èèyàn.

Ẹ̀ṢẸ̀ ÀTI ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN

“Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14, 15.

Torí pé gbogbo wa ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, a máa ń ṣe àṣìṣe, ìdí nìyí tó fi gba ìsapá gidigidi ká tó lè yẹra fún “ṣíṣe àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́.” (Éfésù 2:3) Tí àyè bá yọ láti ṣe ohun tí kò tọ́ tí a ti ń rò lọ́kàn tẹ́lẹ̀, kì í sábà rọrùn láti kọ̀. Tí a bá lọ fàyè gba ohun tí kò dára tó ń wá sọ́kàn wa, àbájáde rẹ̀ máa ń burú jáì.

Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ P. D. Mehta sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn ló jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àwa fúnra wa àti bí àwa èèyàn ṣe ń wá fàájì lójú méjèèjì ló fà á. Bákan náà, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan, ojú kòkòrò àti bí àwa èèyàn ṣe ń lépa nǹkan ńlá tún dá kún ìyà tó ń jẹ aráyé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn táwọn aráàlú kà sí ẹni àyẹ́sí láwùjọ ti fi oríṣiríṣi nǹkan ba ayé ara wọn jẹ́, irú bí ọtí àmujù, oògùn olóró, tẹ́tẹ́, ìṣekúṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí sì ti kó ìyà jẹ ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti àwọn míì. Torí pé àwa èèyàn jẹ́ aláìpé, a gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ, ó ní: “Àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:22.

ỌṢẸ́ TÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ Ń ṢE

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” àti pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tó lágbára tá a mọ̀ sí ẹ̀mí èṣù wà tó ń ṣiṣẹ́ fún Sátánì.—2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:9.

Àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń ṣe bíi ti Sátánì, wọ́n ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n sì ń fipá darí wọn. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—Éfésù 6:12.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù fẹ́ràn kí wọ́n máa dá àwọn èèyàn lóró, ìyẹn gan-an kọ́ ló jẹ wọ́n lógún. Lájorí ohun tí wọ́n ń fẹ́ gan-an ni pé káwọn èèyàn má ṣe jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ. (Sáàmù 83:18) Díẹ̀ lára ohun táwọn ẹ̀mí èṣù ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ, kí wọ́n sì darí wọn ni àṣà kéèyàn máa wo ìràwọ̀, idán pípa, iṣẹ́ oṣó tàbí kéèyàn máa woṣẹ́. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi máa ń kìlọ̀ fún wa nípa irú àwọn ewu yìí, kó lè dáàbò bo wá tá a bá kọ ojú ìjà sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.—Jákọ́bù 4:7.

“ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN” LA WÀ YÌÍ

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.”

Bíbélì sọ ohun tó mú kí àkókò wa yìí le koko, ó ní: “Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Olórí ìdí tí ìyà fi pọ̀ láyé lónìí ni pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—2 Tímótì 3:1-4.

Ó dájú pé àwọn kókó tí a gbé yẹ̀ wò yìí ti ṣàlàyé lọ́nà tó ṣe kedere pé kò ṣeéṣe fún àwa èèyàn láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wù wá láti wá nǹkan ṣe sí i. Báwo la ṣe wá fẹ́ rí ọ̀nà àbáyọ? Àfi ká yíjú sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa, torí ó ti ṣèlérí pé òun máa “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú” tó fi mọ́ àwọn tó ń tì í lẹ́yìn. (1 Jòhánù 3:8) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jẹ ká mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe láti fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé.