Irú ẹ̀bùn wo ni wọ́n lè fún ẹ tó máa wú ẹ lórí, tí wàá sì mọyì rẹ̀ gan-an? Ó dájú pé ọ̀pọ̀ wa ló máa láyọ̀ tí ẹnì kan bá fún wa lẹ́bùn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ìyẹn á sì tẹ́ wa lọ́rùn ju ti ẹni tó kàn fún wa lẹ́bùn nítorí pé ó di dandan fún un tàbí torí pé kò rí ibi yẹ̀ ẹ́ sí. Àmọ́ tó bá di ọ̀rọ̀ ká fúnni lẹ́bùn, ó ṣe pàtàkì ká mọ ìdí tí a fi ń ṣe é. Ó yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa, torí ó ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Jẹ́ ká fara balẹ̀ wo ohun tí Ọlọ́run tipasẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 9:7.

Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ọ̀rọ̀ yẹn? Ìdí ni pé ó fẹ́ gba àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì níyànjú kí wọ́n lè ran àwọn Kristẹni bíi tiwọn tó wà ní ipò àìní ní Jùdíà lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ó fipá mú wọn pé kí wọ́n ṣèrànwọ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn tó fún wọn yìí.

“Gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ìdí tí Kristẹni tòótọ́ fi ń fúnni ní nǹkan ni pé ó ti pinnu tẹ́lẹ̀ “nínú ọkàn-àyà rẹ̀” láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákàn náà, ó tún ti fara balẹ̀ ronú nípa ohun tí àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ nílò. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “pinnu” nínú ẹsẹ yìí jẹ mọ́ “kéèyàn ti kọ́kọ́ fi ọkàn ro ohun tó fẹ́ ṣe.” Bákan náà, ńṣe ni Kristẹni kan á kọ́kọ́ ronú nípa nǹkan tí àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nílò, á sì wo ohun tó lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—1 Jòhánù 3:17.

“Kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe.” Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun méjì wà táwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá ń fúnni lẹ́bùn. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe é pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀, wọn kò sì gbọ́dọ̀ fipá ṣe é. Ní tààràtà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “ìlọ́tìkọ̀” túmọ̀ sí “kéèyàn ṣe nǹkan pẹ̀lú ìbànújẹ́ tàbí pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn.” Ìwé kan ṣàlàyé pé ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ máa ń banú jẹ́ torí gbogbo ohun tó ń rò ni pé òun ń pàdánù owó. Ní ti ẹni tó ń fúnni “lábẹ́ àfipáṣe,” ńṣe ni òun ń fúnni torí pé kò rí ibi yẹ̀ ẹ́ sí tàbí torí pé ó di dandan fún un. Èwo nínú wa ló máa fẹ́ gba nǹkan lọ́wọ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe?

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí Kristẹni kan bá pinnu láti fúnni ní nǹkan, ó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà tàbí pẹ̀lú ìdùnnú. Ó ṣe tán, tí èèyàn bá ń fúnni ní nǹkan látọkànwá, ayọ̀ ló máa ń yọrí sí. (Ìṣe 20:35) Ayọ̀ ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn látọkànwá máa ń pọ̀, kò ṣeé pa mọ́ra. Kódà, tí a bá sọ pé ẹnì kan ní “ọ̀yàyà,” yàtọ̀ sí pé ó hàn gbangba pé ó láyọ̀, ó tún fi hàn pé inú onítọ̀hùn dùn nínú lọ́hùn-ún láti fúnni. Tẹ́nì kan bá fi ọ̀yàyà fún wa lẹ́bùn, ó máa ń mú orí wa wú, ó sì máa ń mú inú Ọlọ́run dùn. Nínú ìtumọ̀ Bíbélì míì, ẹsẹ Bíbélì tá a gbé yẹ̀ wò yìí sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fẹ́ràn láti máa fúnni ní nǹkan.”—Bíbélì Contemporary English Version.

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fẹ́ràn láti máa fúnni ní nǹkan”

Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run tipasẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ ìlànà tó wúlò gan-an tó bá kan bó ṣe yẹ kí àwa Kristẹni máa fúnni ní nǹkan. Ì báà jẹ́ àkókò wa àti okun wa la lò tàbí nǹkan ìní wa la yọ̀ǹda nítorí àwọn ẹlòmíì, ẹ jẹ́ ká máa ṣeé látọkànwá. Tí a bá lawọ́ sí àwọn èèyàn, pàápàá jù lọ àwọn tó bá jẹ́ aláìní, ayọ̀ ló máa yọrí sí. Kò mọ síbẹ̀ o, irú ìwà bẹ́ẹ̀ á sọ wá di ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run torí pé ó “nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún September

1 àti 2 Kọ́ríńtì