• ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1941

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ỌSIRÉLÍÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO Ń MU SÌGÁ ÀTI ỌTÍ NÍ ÀMUJÙ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Warialda ni mo gbé dàgbà ní ìpínlẹ̀ New South Wales. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn ará ìlú yìí ń ṣe, wọ́n máa ń gbin àwọn oúnjẹ oníhóró àti àwọn nǹkan ọ̀gbìn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì, wọ́n tún máa ń sin àgùntàn àti màlúù. Ìlú náà tòrò, ìwà ọ̀daràn ò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀.

Ọmọ mẹ́wàá ni àwọn òbí mi bí, èmi sì ni àkọ́bí. Torí náà, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kí n lè ran àwọn òbí mi lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé wa. Torí pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, iṣẹ́ oko ni mo ń ṣe. Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sin ẹran, kódà mo máa ń sin àwọn ẹṣin kí wọ́n lè mọ ojú àwọn èèyàn, kí wọ́n sì lè wúlò fún wọn.

Bí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ti ṣe mí láǹfààní náà ló tún ṣàkóbá fún mi. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo gbádùn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, mo sì fẹ́ràn àyíká ibẹ̀. Tí mo bá jókòó tí mò ń yáná lọ́wọ́ alẹ́, mo máa ń wo òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó kún ojú ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni atẹ́gùn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ á máa fẹ́ yẹ́ẹ́, tí òórùn àwọn ewéko tútù tó yí mi ká sì máa gbalẹ̀ kan. Mo rántí pé ó máa ń wá sí mi lọ́kàn nígbà yẹn pé Ẹnì kan ní láti wà tó dá gbogbo nǹkan àgbàyanu yìí. Àmọ́ ṣá, àwọn àṣà burúkú tó lè kó báni kan wà tí mo kọ́ nígbà tí mo wà níbi tí a ti ń sin ẹran. Mo sábà máa ń gbọ́ tí àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń ṣépè, wọ́n sì máa ń mu sìgá gan-an. Torí náà, kò pẹ́ tó fi mọ́ mi lára láti máa ṣépè, ojoojúmọ́ ni mo sì ń mu sìgá.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo kó lọ sí ìlú Sydney. Mo gbìyànjú kí n wọ iṣẹ́ ológun níbẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò gbà mí torí pé mi ò kàwé. Nígbà tó yá, mo rí iṣẹ́, àmọ́ mi ò lò ju ọdún kan lọ ní Sydney. Àárín àkókò yẹn ni mo kọ́kọ́ pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ní kí n wá sí ìpàdé wọn, mo sì lọ. Ọjọ́ yẹn gan-an ni mo ti kíyè sí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni wọ́n fi ń kọ́ni.

Láìpẹ́ sígbà yẹn ni mo kúrò ní ìgboro. Ìlú kan tó ń jẹ́ Goondiwindi ni mo wá fàbọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ Queensland. Mo rí iṣẹ́ síbẹ̀,  mo sì gbéyàwó. Àmọ́, èyí tí mo fi bọ̀rọ̀ jẹ́ ni bí mo ṣe wá bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí.

Èmi àti ìyàwó mi bí ọmọ méjì. Lẹ́yìn tí a bí àwọn ọmọ wa ọkùnrin méjèèjì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gidigidi nípa ibi tí mo ń bọ́rọ̀ ayé mi lọ. Mo wá ń rántí àwọn nǹkan tí mo gbọ́ ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí tí mo lọ nígbà tí mo wà ní Sydney, mo sì pinnu pé màá wá nǹkan kan ṣe nípa ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ níbẹ̀.

Mo rí ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan tó ti pẹ́, àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Ọsirélíà sì wà nínú rẹ̀. Ni mo bá kọ lẹ́tà sí wọn pé mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n sì rán Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọkùnrin sí mi, ó jẹ́ oníwà tútù, ó sì kó èèyàn mọ́ra. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nínú ayé mi. Ẹsẹ Bíbélì kan tó dìídì wọ̀ mí lọ́kàn ni 2 Kọ́ríńtì 7:1. Ó gbà wá níyànjú pé ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.”

Mo pinnu pé mi ò ní mu sìgá mọ́, mi ò sì ní mu ọtí lámujù mọ́. Kò rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà yìí torí ohun tí mo máa ń ṣe lójoojúmọ́ ayé mi nìyẹn. Ṣùgbọ́n mo ti pinnu pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni màá máa fi ayé mi ṣe. Ohun kan tó ràn mí lọ́wọ́ jù lọ ni bí mo ṣe fi ìlànà inú Róòmù 12:2 sílò. Ó sọ pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.” Mo wá rí i pé kí n tó lè yí àwọn àṣà mi pa dà, mo ní láti yí èrò mi pa dà, kí n sì mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn àṣà mi, pé ó jẹ́ àṣà tó burú jáì. Ó mú kí n lè jáwọ́ nínú ọtí àmujù, mi ò sì mu sìgá mọ́.

“Mo wá rí i pé kí n tó lè yí àwọn àṣà mi pa dà, mo ní láti yí èrò mi pa dà”

Èyí tó wá le jù fún mi láti fi sílẹ̀ ni èpè tí mo máa ń ṣẹ́. Mo mọ ìtọ́ni Bíbélì tó wà nínú Éfésù 4:29, ó sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.” Síbẹ̀ náà, ojú ẹsẹ̀ kọ́ ni mo jáwọ́ nínú ṣíṣépè. Ohun tó wà nínú Aísáyà 40:26 ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo ronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀. Ẹsẹ yẹn sọ nípa ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.” Mo wá ronú pé tí Ọlọ́run bá lágbára láti dá gbogbo àwọn nǹkan tí mo fẹ́ràn láti máa wò tó wà ní àgbáyé, ó dájú pé ó lè mú kí n lè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ, kí n sì ṣe ohun tó fẹ́. Mo gbàdúrà gan-an, mo sì sa gbogbo ipá mi kí n lè máa ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Torí pé ibi tí wọ́n ti ń sin ẹran ni mo ti ń ṣiṣẹ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti máa bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ torí ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló wà ní àgbègbè ibẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tí mo ti kọ́ ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ kí n kọ́ bí mo ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ó tún ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè máa sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn.—Mátíù 6:9, 10; 24:14.

Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí tí mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àǹfààní ńlá ni mo ka èyí sí torí ó jẹ́ kí n máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ran àwọn tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́. Àmọ́ ìbùkún tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún mi pé èmi àti ìyàwó mi àtàtà àtàwọn ọmọ mi ọ̀wọ́n la jọ ń sin Jèhófà.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ó jẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé. (Aísáyà 54:13) Tọkàntọkàn ni mo fi gbà pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú Òwe 10:22 tó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀.” Èmi àti ìdílé mi ń fojú sọ́nà láti kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ sí i lọ́dọ̀ Jèhófà, ká sì máa sìn ín títí láé.