Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

‘Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Tí A Kò Lè Rí Ṣe Kedere’

‘Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Tí A Kò Lè Rí Ṣe Kedere’

Ǹjẹ́ o gbà pé Ọlọ́run wà? Tí o bá gbà bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o lè tọ́ka sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló yí wa ká tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti alágbára, tó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Kí ni àwọn ẹ̀rí yìí? Báwo ló sì ṣe dá wa lójú tó? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù.

Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.” (Róòmù 1:20) Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere pé iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá hàn nínú àwọn ohun tí à ń rí. Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹ̀ wò.

Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí i pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run fara hàn kedere “láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú.” Kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí ń tọ́ka sí. Dípò bẹ́ẹ̀, ìran èèyàn ló ń tọ́ka sí. * Nítorí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, gbàrà tí Ọlọ́run ti dá èèyàn ni wọ́n ti rí i kedere fúnra wọn pé iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn.

Àwọn ẹ̀rí yìí wà níbi gbogbo. Kò sì ṣòro láti ‘rí wọn kedere’ nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Kódà, àwọn nǹkan tó tóbi títí dórí àwọn nǹkan kéékèèké tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kan wà àti pé ó ní àwọn ìwà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹ ò rí i pé àwọn ohun àgbàyanu tá à ń rí nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ bí ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó! Àwọn ìràwọ̀ tó kún ojú ọ̀run àti omi òkun tó ń ru gùdù pàápàá jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ alágbára. Yàtọ̀ síyẹn, oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn àti bí yíyọ oòrùn àti wíwọ̀ oòrùn ṣe lẹ́wà tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an.—Sáàmù 104:24; Aísáyà 40:26.

Báwo ni àwọn ẹ̀rí yìí ṣe hàn sí gbogbo èèyàn tó? Ó hàn gbangba débi pé àwọn tó sọ pé àwọn ò rí i, tí wọ́n sì torí bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn kò gbà pé Ọlọ́run wà “kò ní àwíjàre.” Ọ̀mọ̀wé kan ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ yìí pé: Ṣe ló dà bí awakọ̀ kan tó mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo àmì kan tó wà lójú pópó tó sọ pé kó yà sápá òsì. Ọlọ́pàá kan wá dá a dúró, ó sì sọ fún un pé ó máa san owó ìtanràn. Awakọ̀ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jiyàn pé òun kò rí àmì kankan lójú ọ̀nà. Àmọ́ ọlọ́pàá náà kò gbà torí pé àmì náà hàn kedere níbi tó wà, ojú ò sì dun awakọ̀ yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ojúṣe ẹnikẹ́ni tó bá ń wakọ̀ ni pé kó máa kíyè sí àwọn àmì tó bá rí lójú pópó, kó sì máa pa wọ́n mọ́. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn pẹ̀lú bí àwọn nǹkan tí Ọlọrun dá ṣe ń jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run wà. Àwọn àmì náà kò fara sin rárá. Torí pé ẹ̀dá onílàákàyè ni wá, a lè rí wọn kedere. A kò sì ní àwíjàre kankan láti gbójú fò wọ́n.

Iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá hàn nínú àwọn ohun tí à ń rí

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa látinú àwọn nǹkan tó dá. Àmọ́, Bíbélì tún sọ púpọ̀ fún wa nípa Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, inú Bíbélì ni a ti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì yìí: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé àti àwa èèyàn tó ń gbé inú rẹ̀? Tí o bá mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, ó máa jẹ́ kí o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ẹni tí ‘àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ṣe kedere’ nínú àwọn nǹkan tó yí wa ká nínú ayé.

Bíbélì Kíkà Tá a Dábàá Fún August

Róòmù 1-16

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì sọ pé “ayé” ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti pé wọ́n nílò olùgbàlà, ìyẹn fi hàn kedere pé ayé tí ibẹ̀ yẹn ń sọ kì í ṣe ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, àmọ́ ó ń tọ́ka sí àwọn èèyàn.—Jòhánù 1:29; 4:42; 12:47.