Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ó ‘Ń Mú Inú Wa Dùn’

Ó ‘Ń Mú Inú Wa Dùn’

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lógún? Àbí kò tiẹ̀ sí èyí tó kàn án nínú gbogbo ìṣòro tó ń dé bá àwa èèyàn láyé ni? Bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn tù wá nínú, ó sì múnú wa dùn. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún, àti pé ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa. Lójoojúmọ́ ni Ọlọ́run ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn jàǹfààní oore rẹ̀, kódà títí kan àwọn tí kò moore Ọlọ́run. Wo ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ.—Ka Ìṣe 14:16, 17.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ ní ìlú Lísírà sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, [Ọlọ́run] jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. Síbẹ̀ kò ṣàìfi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fún yín ní ońjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” (Ìròhìn Ayọ̀) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí gbé wá sọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀?

Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ á ti tètè yé àwọn ará Lísírà. Ìdí ni pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn ń ṣe, ilẹ̀ wọn lọ́ràá, àgbègbè ibẹ̀ sì lómi dáadáa. Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé Ọlọ́run ló ń rọ òjò, òun ló sì ń mú kí èso jáde lásìkò tó yẹ. Nítorí náà, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá kó irè oko rẹpẹtẹ, tàbí tí wọ́n jẹ oúnjẹ aládùn ni wọ́n á máa rántí pé àwọn ń jàǹfààní oore Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ìlú Lísírà kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ mélòó kan tó ṣe pàtàkì nípa Jèhófà Ọlọ́run.

Jèhófà fún wa lómìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́. Kíyè sí i pé Jèhófà fún àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti “máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.” Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí pé “kí wọ́n ṣe bí ó bá ṣe tẹ́ wọn lọ́rùn” tàbí “kí wọ́n ṣe ohun tó bá ṣáà ti tọ́ lójú wọn.” Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni pé kó wá sin òun. Ṣe ló fún wa lómìnira láti fúnra wa yan bí a ṣe máa gbé ìgbésí ayé wa.—Diutarónómì 30:19.

Jèhófà fẹ́ ká mọ òun. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé, “kò ṣàìfi àmì ara rẹ̀ hàn.” Ìwé tí a tọ́ka sí lẹ́ẹ̀kan sọ pé ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí pé “ó ti fi irú Ọlọ́run tí òun jẹ́ han àwọn èèyàn kedere.” Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ló ní ‘àwọn ànímọ́ tí a kò lè rí,’ irú bí ọgbọ́n, agbára, ìfẹ́ àti inú rere. (Róòmù 1:20) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa ara rẹ̀ nínú Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Ǹjẹ́ èyí kò fi hàn lóòótọ́ pé ó fẹ́ ká mọ òun?

Lójoojúmọ́ ni Ọlọ́run ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn jàǹfààní oore rẹ̀, kódà títí kan àwọn tí kò moore Ọlọ́run

Jèhófà fẹ́ kí inú wa máa dùn. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà máa ń fún wa ‘ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú wa dùn.’ Kódà, ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí kò moore Jèhófà pàápàá lè máa jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn, kí inú rẹ̀ sì dùn. Àmọ́, Ọlọ́run fẹ́ ká ní ojúlówó ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí. Èyí sì máa tẹ̀ wá lọ́wọ́ tí a bá mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ gan-an, tí a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.—Sáàmù 144:15; Mátíù 5:3.

Ojoojúmọ́ ni gbogbo wa ń jàǹfààní oore Ọlọ́run. A rọ̀ ọ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí o ṣe lè fi hàn pé o moore Ọlọ́run tó ń fún wa ‘ní oúnjẹ, tó tún ń mú inú wa dùn.’

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún July

Ìṣe 11-28