Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ìwà Rere?

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ìwà Rere?

Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Sylvia, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tá a jọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ló sọ pé onísìn làwọn, síbẹ̀ wọ́n jí ìwé wò nígbà ìdánwò, wọ́n sì lo oògùn olóró. Ẹ̀sìn ò ní kí wọ́n má ṣe bó ṣe wù wọ́n.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lionel sọ pé: “Tí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ kò bá fẹ́ wá sí ibi iṣẹ́ nígbà míì, wọ́n á parọ́ pé ara àwọn ò yá, bẹ́ẹ̀ nǹkan kan ò ṣe wọ́n. Wọ́n ní ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àmọ́ kò ṣe nǹkan kan láyé wọn, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn ò kọjá orí ahọ́n lásán.”

Ẹ̀sìn ò kọ́ àwọn èèyàn bó ṣe yẹ kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ìwà rere. Lóde òní, ọ̀pọ̀ ló “ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run” ṣùgbọ́n tí wọ́n “já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:5) Àwọn aṣáájú ìsìn ò fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. Àwọn àlùfáà pàápàá kò kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn ní ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà rere. Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi gbà pé ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé àwọn ò kan Ọlọ́run.

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

Bíbélì jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run àti pé ìwà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń hù jẹ ẹ́ lógún gan-an. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ‘wọn mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́.’ (Sáàmù 78:40) Àmọ́ o, “ìdùnnú púpọ̀ . . . wà ní ọ̀run” nígbà tẹ́nì kan bá fi tọkàntọkàn yí ìwà rẹ̀ pa dà. (Lúùkù 15:7) Tí ẹnì kan bá mọyì àwọn ìwà dáadáa tí Baba wa ọ̀run ní, ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Èyí ló sì máa sún ẹni náà láti nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọrun nífẹ̀ẹ́, kó sì kórìíra ohun tí Ọlọ́run kórìíra.—Ámósì 5:15.

ṢÉ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

Ìwé ìròyìn Deseret News ti Salt Lake City, ní ìpínlẹ̀ Utah, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “máa ń mú kí àwọn ìdílé ṣera wọn lọ́kan. Wọ́n sì tún máa ń mú kí àwọn èèyàn di aráàlú tó wúlò tó sì jẹ́ olóòótọ́.” Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé: “Ìlànà ìwà rere tó ta yọ ni àwọn ọmọ ìjọ wọn máa ń tẹ̀ lé. Wọ́n gbà pé sìgá mímu, ọtí àmujù, oògùn olóró, tẹ́tẹ́ títa, ìṣekúṣe àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ máa ń ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.”

Ǹjẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà rere?

Báwo ni bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́? Sylvia tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera sábà máa ń kówó jẹ. Bí àwọn yòókù ti ń ṣe ni èmi náà ì bá máa ṣe. Àmọ́ bí mo ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà * kò dùn sí irú ìwà yìí ti jẹ́ kí n máa ṣe ohun tí ó tọ́. Mò ń láyọ̀, ọkàn mi sì balẹ̀.” Ó dá Sylvia lójú pé ìlànà tí ẹ̀sìn òun fi kọ́ òun ló jẹ́ kí ìgbésí ayé òun dára.

^ ìpínrọ̀ 9 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.