Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣé kéèyàn wà láàyè títí láé?

Kí la nílò ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ikú?

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù lò láyé. Àmọ́ nígbà tó yá, ó darúgbó, ó sì kú. Láti ìgbà yẹn, oríṣiríṣi nǹkan ni àwọn èèyàn ń ṣe kí wọ́n má bàa darúgbó. Síbẹ̀, kò sí ẹni tó tíì rí oògùn ikú ṣe. Kí nìdí? Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ ló dá. Ìdí nìyẹn tó fi darúgbó tó sì kú. Torí náà, àwa náà ń darúgbó torí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, ikú sì ni èyí yọrí sí fún wa.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 5:5; Róòmù 5:12.

Kí a tó lè máa wà láàyè títí láé, ẹni kan gbọ́dọ̀ san ìràpadà nítorí wa. (Jóòbù 33:24, 25) Ìràpadà ni iye tí èèyàn san láti dá ẹnì kan sílẹ̀ lómìnira. Nínú ọ̀ràn tiwa, a nílò òmìnira kúrò lọ́wọ́ ikú. (Ẹ́kísódù 21:29, 30) Jésù san ìràpadà yẹn nígbà tó kú fún wa.—Ka Jòhánù 3:16.

Kí ni èèyàn lè ṣe táá fi wà láàyè títí láé?

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa bọ́ lọ́wọ́ àìsàn àti ọjọ́ ogbó. Kódà, àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run bíi ti Ádámù, kò ní láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kìkì àwọn tí Ọlọ́run bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n nìkan ló máa wà láàyè títí láé.—Ka Aísáyà 33:24; 35:3-6.

Kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá, ohun kan wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe. A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká lè mọ Ọlọ́run. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí a lè ṣe kí ayé wa lè dára, ó tún kọ́ wa bí a ṣe lè rí ojú rere Ọlọ́run àti ohun tí a máa ṣe ká lè wà láàyè títí láé.—Ka Jòhánù 17:3; Ìṣe 3:19.