Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ July 2013 | Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Gbára Lé Ẹ̀sìn?

Kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbára lé ẹ̀sìn torí bí ẹ̀sìn wọn ṣe ti já wọn kulẹ̀ nígbà kan. Mọ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀sìn kan tí kò ní já ọ kulẹ̀.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí O Yẹ Ẹ̀sìn Rẹ Wò Dáadáa?

Bí àárín ìwọ àti Ọlọ́run ṣe máa rí àti ìgbàlà rẹ wà lọ́wọ́ ẹ̀sìn tí ò ń ṣe.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Owó?

Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn tó wà ládùúgbò rẹ máa ń béèrè owó ní tààràtà, àbí ṣe ni wọ́n ń fi oríṣiríṣi ọgbọ́n gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn? Ǹjẹ́ èyí bá Bíbélì mu?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ogun?

Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn. Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn lónìí ń pa àṣẹ yẹn mọ́?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ìwà Rere?

Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìwà rere ọ̀pọ̀ aṣáájú ẹ̀sìn ni kò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Ṣé ìwà tí à ń hù jẹ Ọlọ́run lógún?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Ẹ̀sìn Kankan Tiẹ̀ Wà Téèyàn Lè Gbára Lé?

Tí ẹ̀sìn kan bá ti já ẹ kulẹ̀ rí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbára lé ẹ̀sìn kankan. Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

Ìṣòro tó máa ń wáyé nínú ìgbéyàwó téèyàn tún ṣe lè máà sí nínú ìgbéyàwó àkọ́kọ́. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè ṣàṣeyọrí?

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ó ‘Ń Mú Inú Wa Dùn’

Lójoojúmọ́ ni Ọlọ́run ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn jàǹfààní oore rẹ̀, kódà títí kan àwọn tí kò moore Ọlọ́run.

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà”

Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe jẹ́ kí ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn rí ohun tó lè yí ayé yìí pa dà pátápátá?

ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN

Ǹjẹ́ Ìyà Tó Ń Jẹ Wá Tiẹ̀ Kan Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé kò sí Ọlọ́run torí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Wo bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ bí ìyà tó ń jẹ wá ṣe rí lára Ọlọ́run.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Oríṣiríṣi nǹkan ni àwọn èèyàn ń ṣe kí wọ́n má bàa kú, síbẹ̀ kò sí ẹni tó tíì rí oògùn ikú ṣe. Kí ló fà á?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Èèyàn Tó Ti Lẹ́sìn Tiwọn?

Kí ló ń mú ká máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó ti lẹ́sìn tiwọn?