Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  June 2013

 KỌ́ ỌMỌ RẸ

Kí La Rí Kọ́ Nínú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ọ̀daràn Kan?

Kí La Rí Kọ́ Nínú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ọ̀daràn Kan?

Ọ̀daràn tí a lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lò ń wò tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nínú àwòrán yìí. Inú ọ̀daràn yẹn kò dún torí gbogbo ìwà burúkú tó ti hù. Ó sọ fún Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i nínú àwòrán yìí, Jésù ń bá ọ̀daràn náà sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jésù ń sọ fún un? * Jésù ń ṣèlérí fun un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”

Báwo lo ṣe rò pé Párádísè yẹn ṣe máa rí?— Ká lè rí ìdáhùn tó tọ̀nà sí ìbéèrè yìí, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Párádísè tí Ọlọ́run fi ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ sí, ìyẹn Ádámù àti Éfà. Ibo ni Párádísè yẹn wà? Ṣé ọ̀run ni àbí orí ilẹ̀ ayé?

Tí o bá sọ pé orí ilẹ̀ ayé ló wà, o gbà á. Torí náà, tí a bá ń rò ó pé ọ̀daràn náà máa wà “ní Párádísè,” orí ilẹ̀ ayé níbí ló yẹ ká fọkàn sí pé ó máa wà nígbà tí ayé bá di Párádísè. Báwo ni Párádísè yẹn ṣe máa rí?— Jẹ́ ká wò ó ná.

Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì pè é ní “ọgbà kan ní Édẹ́nì.” Ǹjẹ́ o lè fojú yàwòrán bí ‘ọgbà Édẹ́nì’ ṣe rí nígbà yẹn?— Ó dájú pé, ibi tó rẹwà láti gbé, tó sì dára ju ibikíbi mìíràn tí èèyàn tíì rí rí ni!

Kí wá lèrò rẹ? Ṣé orí ilẹ̀ ayé níbí ni Jésù máa wà pẹ̀lú ọ̀daràn tó ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yẹn?— Rárá o, ọ̀run ni Jésù máa wà tí yóò máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lé ilẹ̀ ayé tó ti di Párádísè lórí. Nítorí náà, Jésù máa wà pẹ̀lú ọ̀daràn náà ní ti pé, ó máa jí i dìde, á sì rí i dájú pé ó rí àbójútó tó yẹ nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, kí nìdí tí Jésù fi máa jẹ́ kí ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ yìí gbé nínú Párádísè?— Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa èyí.

 Òótọ́ ni pé ọ̀daràn yìí ti hu àwọn ìwà tó burú jáì sẹ́yìn. Àmọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì náà wà tó ti gbé lórí ilẹ̀ ayé táwọn náà hùwà burúkú. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló hùwà burúkú torí pé wọn kò rí ẹni kọ́ wọn nípa Jèhófà, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe.

Tórí náà, irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, títí kan ọ̀daràn tí Jésù bá sọ̀rọ̀ lórí igi oró, ni yóò jíǹde sí ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n máa kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa ṣe. Ìgbà yẹn ni wọ́n á tó lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Ǹjẹ́ o mọ bí wọ́n ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?— Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ohun ayọ̀ gbáà ni yóò jẹ́ láti máa gbé títí láé nínú Párádísè pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì!

^ ìpínrọ̀ 3 Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.