Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  June 2013

 Sún Mọ́ Ọlọ́run

Jèhófà “Kì Í Ṣe Ojúsàájú”

Jèhófà “Kì Í Ṣe Ojúsàájú”

Ǹjẹ́ wọ́n ti hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sí ẹ rí? Àbí ṣe ni wọ́n fi ohun kan tí o fẹ́ dù ọ́ tàbí tí wọ́n fojú pa ọ́ rẹ́ torí àwọ̀ rẹ, ẹ̀yà tí o ti wá tàbí irú ipò tí o wà láwùjọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbà pé ìwọ nìkan kọ́ nirú rẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Inú rẹ máa dùn láti mọ̀ pé, bó ti wù kí irú àwọn ìwà báyìí pọ̀ tó, orí ilẹ̀ ayé nìkan ló mọ, kò sírú rẹ̀ lọ́run rárá. Àpọ́sítélì Pétérù fi ìdánilójú sọ pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.”—Ka Ìṣe 10:34, 35.

Ilé Kèfèrí kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù ni Pétérù ti sọ̀rọ̀ yẹn, èèyàn ò lè retí pé irú ibẹ̀ ni Pétérù a ti sọ ohun tó sọ yẹn. Júù ni Pétérù, ó gbé láyé nígbà tí àwọn Júù máa ń ka àwọn Kèfèrí sí aláìmọ́, tí wọn kì í sì í bá wọn da nǹkan kan pọ̀. Kí ni Pétérù lọ ṣe ní ilé Kọ̀nílíù? Jèhófà Ọlọ́run ló ní kó lọ síbẹ̀. Ọlọ́run sọ fún un nínú ìran pé: “Ìwọ dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” Pétérù kò mọ̀ pé Ọlọ́run ti fi ìran kan han Kọ̀nílíù lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, áńgẹ́lì kan sọ fún un pé kí ó pe Pétérù wá sí ilé rẹ̀. (Ìṣe 10:1-15) Nígbà tí Pétérù rí i pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kò ṣẹ̀yìn Jèhófà, ó sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀.

Pétérù sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ojúsàájú” lédè Yorùbá túmọ̀ sí “ẹni tó máa ń wo ojú.” (Bíbélì The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures) Nígbà tí ọkùnrin ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ń ṣàlàyé kókó yìí, ó ní: “Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí adájọ́ kan tó máa ń wo ojú dájọ́, tí kì í wo ti pé ẹnì kan jàre tàbí ó jẹ̀bi, ṣùgbọ́n orí ohun tó fẹ́ àti èyí tí kò fẹ́ nípa onítọ̀hún ló máa ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà.” Ọlọ́run kì í ṣe ojú rere sí ẹnì kan ju ẹlòmíì lọ nítorí ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tó ti wá, tàbí ipò tó wà láwùjọ tàbí àwọn àǹfààní míì tó ní.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó wà lọ́kàn wa ni Jèhófà ń wò. (1 Sámúẹ́lì 16:7; Òwe 21:2) Pétérù sọ pé: “Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:35) Tí a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, à á máa bọ̀wọ̀ fún un, à á bọlá fún un, à á fọkàn tán an, a ò sì ní ṣe ohunkóhun tó máa mú un bínú. Tí a bá fẹ́ máa ṣiṣẹ́ òdodo, a ó máa sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́. Jèhófà fẹ́ràn ẹni tó bá ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un látọkàn wá, tí èyí sì ń mú kí ẹni náà máa ṣe ohun tó tọ́.—Diutarónómì 10:12, 13.

Tí Jèhófà bá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ó ń rí, ìyẹn ni ìran èèyàn

Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ nípa Ọlọ́run máa fún ẹ níṣìírí gan-an tí wọ́n bá ti hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sí ẹ tàbí tí wọ́n ṣe ẹ̀tanú sí ẹ rí. Ṣe ni Jèhófà ń fa àwọn èèyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè wá sínú ìjọsìn tòótọ́. (Jòhánù 6:44; Ìṣe 17:26, 27) Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà àwọn tó ń sìn ín, ó sì máa ń dá wọn lóhùn láìka ẹ̀yà wọn tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ sí. (1 Àwọn Ọba 8:41-43) Ó dá wa lójú pé tí Jèhófà bá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ó ń rí, ìyẹn ni ìran èèyàn. Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ láti mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run tí kì í ṣe ojúsàájú yìí?

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún June

Jòhánù 17-21Ìṣe 1-10