Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìṣura Kan Tó Fara Sin Láti Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ọdún

Ìṣura Kan Tó Fara Sin Láti Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ọdún

Ohun tí ọ̀mọ̀wé yìí rí yà á lẹ́nu. Ṣe ló ń fara balẹ̀ yẹ ìwé àtijọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí wò ní àwòtúnwò. Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ọ́ àti gírámà tí wọ́n fi kọ ọ́ jẹ́ kó dá a lójú pé ẹ̀dà tó tíì pẹ́ jù lọ nínú ìtumọ̀ Bíbélì lédè Geogian ni òun mú dání yìí.

OṢÙ December, ọdún 1922 ti ń parí lọ nígbà tí wọ́n rí ohun tí a lè pè ní ìṣúra yìí. Nígbà yẹn, ọ̀mọ̀wé Ivané Javakhishvili, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Georgia ló ń ṣe ìwádìí lórí bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn lẹ́tà èdè Georgian. Ẹnu ìwádìí yìí ló wà nígbà tó rí ẹ̀dà kan ìwé ìsìn àwọn Júù tí wọ́n ń pè ní Támọ́dì Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe ń yẹ̀ ẹ́ wò, ó kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ èdè Georgian kọ̀ọ̀kan tí wọn ò pa rẹ́ tán lábẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó wà nínú ìwé ọ̀hún. *

Apá kan ìwé Jeremáyà nínú Bíbélì ni àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lábẹ́ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé Támọ́dì yìí, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ni wọ́n ti kọ ìwé yìí. Kí wọ́n tó rí ẹ̀dà yìí, ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ tó tíì pẹ́ jù lọ tí àwọn èèyàn mọ̀ ní èdè Georgian ni èyí tó ti wà láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí apá kọ̀ọ̀kan lára àwọn ìwé míì nínú Bíbélì tó ti wà láti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù àti àwọn tó tiẹ̀ ti wà ṣáájú àkókò yìí. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n ṣàwárí apá kan lára Bíbélì tí wọ́n kọ lẹ́nu ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbà ayé Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀!

Ta ló túmọ̀ àwọn ẹ̀dà yìí? Ṣé iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kan ni, àbí àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n fi tọkàntara ṣiṣẹ́? Títí di báyìí, kò tíì sí ẹ̀rí kankan nínú ìtàn tó lè jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe jẹ́ gan-an. Ẹni yòówù tíì báà túmọ̀ wọn, ohun tó dájú ni pé wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì lódindi tàbí apá kan rẹ̀ sí èdè Georgian láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wà lọ́wọ́ àwọn ará ilẹ̀ Georgia ní èdè ìbílẹ̀ wọn láti ìgbà yẹn.

Ìtàn kan tó fi bí àwọn ará ilẹ̀ Georgia ṣe mọ Ìwé Mímọ́ tó hàn, wà nínú ìwé kan tó ń jẹ́ The Martyrdom of St. Shushanik the Queen, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ni wọ́n kọ ìwé yìí. Nígbà tí ẹni tó kọ ìwé yìí ń sọ ìtàn nípa ayaba kan tó ń jẹ́ Shushanik, ó fa àwọn ọ̀rọ̀ kan yọ látinú ìwé Sáàmù, àwọn ìwé Ìhìn Rere àti àwọn ìwé míì nínú Bíbélì. Ó tún sọ pé, nígbà tí ọkọ ayaba Shushanik, ìyẹn Varsken, tó jẹ́ gómìnà àgbègbè Kartli ní ilẹ̀ Georgia fẹ́ fa ojú àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Páṣíà mọ́ra, ó kúrò nínú “ẹ̀sìn Kristẹni,” ó sì lọ wọnú ẹ̀sìn Zoroaster ti àwọn ará Páṣíà. Ó tún  fi dandan lé e pé ìyàwó òun gbọ́dọ̀ fi ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀. Àmọ́, ìwé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé, ìyàwó rẹ̀ kò fi ẹ̀sìn rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tó kà nínú Ìwé Mímọ́ sì tù ú nínú gan-an kó tó di pé wọ́n pa á.

Ẹ̀rí fi hàn pé bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè Georgian, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀dà rẹ̀ jáde kò dáwọ́ dúró rárá láti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù. Bí àwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n fi ọwọ́ kọ lédè Georgian ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ jẹ́ ká rí iṣẹ́ ribiribi tí àwọn atúmọ̀ èdè àti àwọn tó ṣe àdàkọ Bíbélì ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo apá méjì nínú ìtàn alárinrin yìí, ìyẹn bí wọ́n ṣe túmọ̀ Bíbélì àti bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde.

ÌTÚMỌ̀ BÍBÉLÌ TÚBỌ̀ GBILẸ̀

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan sẹ́yìn nílẹ̀ Georgia, ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó ń jẹ́ Giorgi Mtatsmindeli sọ pé: “Èmi Giorgi, tí mo jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ṣe iṣẹ́ àṣekára, mo sì sapá gan-an kí n lè túmọ̀ ìwé Sáàmù láti èdè Gíríìkì sí èdè Georgian.” Kí nìdí tí wọ́n tún fi ń túmọ̀ Bíbélì lásìkò yìí nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì ti wà lédè Georgian láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn?

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan sẹ́yìn, àwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n dà kọ lédè Georgian kò fi bẹ́ẹ̀ sí lọ́wọ́ àwọn èèyàn mọ́. Àwọn ìwé Bíbélì kan tiẹ̀ ti sọ nù lódindi. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe ń sọ èdè náà nísinsìnyí ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, torí náà àwọn èèyàn kì í tètè lóye ọ̀rọ̀ inú àwọn ẹ̀dà àtijọ́ yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó gbìyànjú láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Georgian pọ̀ díẹ̀, ìtumọ̀ tí Giorgi ṣe ló gba iwájú. Ìdí ni pé, ó fi àwọn Bíbélì tó ti wà lédè Georgian wé àwọn ẹ̀dà tí wọ́n fi ọwọ́ kọ lédè Gíríìkì, ó sì túmọ̀ àwọn apá tó ti sọ nù nínú Bíbélì lédè Georgian, títí kan àwọn odindi ìwé míì nínú Bíbélì. Ohun tó máa ń ṣe ni pé, lójúmọmọ, ó máa ń bójú tó iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Ṣùgbọ́n tó bá di ọwọ́ alẹ́, ó máa ń túmọ̀ Bíbélì.

Ojúgbà Giorgi kan tó ń jẹ́ Ephrem Mtsire, dáwọ́ lé iṣẹ́ tí Giorgi ti ń ṣe bọ̀, ó sì ń bá a nìṣó. Ó gbé àwọn ìlànà tó wúlò kan kalẹ̀ fún àwọn atúmọ̀ èdè. Lára àwọn ìlànà yìí ni pé tó bá ṣeé ṣé, kí àwọn atúmọ̀ èdè máa ṣe ìtumọ̀ wọn látinú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ iṣẹ́ tí wọ́n bá ń tú. Bákan náà, kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n kọ ọ́ bí àwọn tó ni èdè ṣe máa sọ ọ́ gan-an. Nínú àwọn Bíbélì tí wọ́n tú, òun ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti atọ́ka kún Bíbélì lédè Georgian. Kódà Ephrem túmọ̀ àwọn ìwé inú Bíbélì kan lákọ̀tun. Ìpìlẹ̀ tó dára ni Giorgi àti Ephrem fi lélẹ̀ fún àwọn tó wá ń ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ lẹ́yìn wọn.

Láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni àwọn èèyàn ṣe jáde ní ilẹ̀ Georgia. Wọ́n dá àwọn ilé ìwé sílẹ̀ ní ìlú Gelati àti ìlú Ikalto. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé tó gboyè jáde ní àwọn ilé ìwé tó wà ní ìlú Gelati tàbí ìlú Ikalto, ló ṣe ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń pè ní Gelati Bible tó wà ní ibi tí wọ́n ń kó àwọn ìwé àfọwọ́kọ sí ní orílẹ̀-èdè Georgia.

 Ipa wo ni iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì yìí ti ní lórí àwọn èèyàn ilẹ̀ Georgia? Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] ọdún sẹ́yìn, akéwì ọmọ ilẹ̀ Georgia, Shota Rustaveli kọ ìwé Vepkhis-tqaosani (Knight in the Panther Skin). Ìwé yìí gbajúmọ̀ gan-an láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún débi pe Bíbélì kejì lédè Geogian ni wọ́n ń pè é. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé òde òní kan tó ń jẹ́ K. Kekelidze ṣàyẹ̀wò ìwé yìí, ó fura pé ó ṣeé ṣe kí akéwì yìí fa àwọn ọ̀rọ̀ kan yọ látinú Bíbélì ní tààràtà, àmọ́ tí kò bá tiẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, “díẹ̀ lára àwọn ohun tó kọ fi hàn pé inú àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ló ti fa ewì rẹ̀ yọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbùmọ́ pọ̀ nínú ewì yìí, léraléra ló tẹnu mọ́ bí èèyàn ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, kó jẹ́ ọ̀làwọ́, kó bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin, kó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì. Láti ìrandíran àwọn ará ilẹ̀ Georgia sì ni àwọn ẹ̀kọ́ yìí àti àwọn míì tó wà nínú Bíbélì ti ní ipa lórí bí wọ́n ṣe máa ń ronú, kódà títí dòní wọ́n ṣì gbà pé ó yẹ kéèyàn máa fi wọ́n ṣèwà hù.

ÀWỌN LỌ́BALỌ́BA KỌ́WỌ́ TI IṢẸ́ ÌTẸ̀WÉ BÍBÉLÌ

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún sẹ́yìn, ìdílé àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Georgia fẹ́ kí wọ́n tẹ Bíbélì jáde. Nítorí èyí, Ọba Vakhtang kẹfà kọ́ ilé ìtẹ̀wé kan sí olú ìlú wọn ní Tbilisi. Àmọ́, wọn ò tíì kọ Bíbélì tán débi tí wọ́n máa tẹ̀ ẹ́ jáde nígbà yẹn. Ṣe ló dà bí ẹni pé Bíbélì lédè Georgian tún ti fara sin. Apá kan lára àwọn ẹ̀dà tí wọ́n fọwọ́ kọ nìkan ló ṣì wà, èdè tí wọ́n sì fi kọ wọ́n kò bóde mu mọ́. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sulkhan Saba Orbeliani tó jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú ìmọ̀ èdè ni wọ́n gbé iṣẹ́ àtúnkọ àti àtúnṣe Bíbélì náà fún.

Tọkàntọkàn ni Orbeliani fi ṣe iṣẹ́ yìí. Nítorí pé ó gbọ́ oríṣiríṣi èdè títí kan Gíríìkì àti Látìn, ó ṣeé ṣe fún un láti wo onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ yàtọ̀ sí ti èdè Georgian. Àmọ́ ṣá o, bí kò ṣe fi igbá kan bọ ìkan nínú nídìí iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un kò tẹ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lọ́rùn. Torí náà, àwọn àlùfáà fẹ̀sùn kàn án pé ó ti dalẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì dọ́gbọ́n lọ sọ fún ọba pé kó pàṣẹ pé kí Orbeliani dáwọ́ iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì náà dúró. Ìròyìn kan nílẹ̀ Georgia sọ pé, níbi àpérò kan tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe, wọ́n fipá mú kí Orbeliani dáná sun Bíbélì tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣíṣẹ́ lé lórí.

Ó jọni lójú pé ẹ̀dà kan ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n ń pè ní Mtskheta (tàbí Mcxeta) ṣì wà títí dòní, àwọn èèyàn tún máa ń pè é ní Saba’s Bible. Àwọn àlàyé tí Orbeliani fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ sì wà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò dá àwọn kan lójú pé Bíbélì yìí ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì dáná sun nígbà yẹn. Àfikún àlàyé inú rẹ̀ nìkan ló dá àwọn èèyàn lójú pé Orbeliani kọ.

Kódà lójú gbogbo àtakò wọ̀nyí, ó ṣì wà lọ́kàn àwọn kan lára ìdílé àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Georgia láti tẹ Bíbélì jáde. Láàárín ọdún 1705 sí 1711, wọ́n tẹ àwọn apá kan nínú Bíbélì jáde. Ọpẹ́lọpẹ́ Bakari àti Vakhushti tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba nílẹ̀ Georgia, ìsapá wọn ló mú kí wọ́n lè tẹ Bíbélì jáde lódindi lédè Georgian ní ọdún 1743. Bí Bíbélì ṣe wá di ohun tó délé dóko nìyẹn o!

^ ìpínrọ̀ 3 Láyé àtijọ́, ohun èlò ìkọ̀wé ṣọ̀wọ́n, wọ́n sì gbówó lórí. Torí náà, ọ̀pọ̀ ló máa ń pa ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá kọ sínú ìwé àfọwọ́kọ rẹ́ kí wọ́n lè tún rí ìwé náà lò láti kọ nǹkan míì. Orúkọ tí wọ́n ń pe irú àwọn ìwé àfọwọ́kọ yìí ní èdè Gíríìkì túmọ̀ sí kéèyàn nu nǹkan kúrò.